Ìgbéyàwó Gẹ́gẹ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Pète Rẹ̀Àpẹrẹ
Sísín Kristi Jẹ
Ohun kíkà ti òní jẹ́ ìtàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yọrí sí ìpàdé àkọ́kọ́ Adamu àti ìyàwó rẹ̀, Eefa. Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ abẹ àkọ́kọ́ irú ẹ̀ lára Adamu. Ó bá ìmọ̀lára Adamu nípasẹ̀ fífi oorun kùn ún wọra, ó ṣí igbá àyà rẹ̀, ó yọ ẹfọ́nhà kan, ó sì dá obìnrin. Adamu kò tilẹ̀ kó ipa ìmọ̀ọ́mọ̀ kó nínú ìgbésẹ̀ náà; Ọlọ́run pèsè akẹgbẹ́ tí ó tọ́ tí ó sì bá a mú rẹ́gí fún un. Nígbà tí Adamu jí láti ara ipò-àìmọ̀kan afarapẹ́-ikú yìí, ó fèsì pẹ̀lú ewì: ó dunnú láti bá ìyàwó rẹ̀ pàdé, Egungun nínú Egungun rẹ̀ àti ẹran-ara nínú ẹran ara rẹ̀!
Ọ̀nà tí a gbà dá Eefa ṣe pàtàkì. Adamu sọ apá kan nù nínú ara rẹ̀, àdánù náà sì mú ìyàwó jáde. Àdánù rẹ̀ yìí yọrí sí arẹwà ẹ̀bùn tí ó mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún un. Ìṣẹ̀lẹ̀ inú ọgbà Edẹni yìí ṣàpẹrẹ bí Jesu ṣe gba ìyàwó rẹ̀, tí í ṣe ìjọ. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sí ẹ̀gbẹ́ Adamu láti yọ ẹfọ́nhà rẹ̀, a ṣí ẹ̀gbẹ́ Jesu nígbà tí a fi kọ́ orí àgbélèbú. Jesu kò pàdánù ẹfọ́nhà kan, ó pàdánù ayé rẹ̀ láti jèrè wa.
Adamu àti Jesu ṣe àfihàn ìrúbọ-ara-ẹni tí ó sodo sínú ìbáṣepọ̀ ìgbéyàwó. Èyí jẹ́ ìpènijà fún àwọn ọkùnrin pàápàá, àwọn tó ti gbéyàwó àti àwọn tó fẹ́ láti gbéyàwó. Máṣe réti láti gba ẹ̀bùn ìyanu ti ìgbéyàwó lọ́fẹ̀ẹ́. Wà á ní láti ṣe ìrúbọ apá pàtàkì ara rẹ láti jèrè ìgbéyàwó tímọ́tímọ́, alálòpẹ́ àti oníṣọ̀kan. Àti pé ìrúbọ ara-ẹni kì í ṣe ohun àṣetán lẹ́ẹ̀kanṣoṣo nígbà tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó; í nílò láti jẹ́ gbogbo ìgbà nínú ìgbéyàyó aláyọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọkọ, gẹ́gẹ́ bí olórí, agbọ́dọ̀ yára lára fi ayé wa lélẹ̀ fún àwọn ìyàwó wa.
Ní púpọ̀ ẹkùn Afíríkà, wọ́n sọ fún àwọn okùnrin pé àwọn ni olórí ilé wọn. ó dájú nínú Bíbélì pé ọkọ ni olórí ìdílé rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé kí ọkùnrin jókòó kí ó sì máa retí kí wọ́n sìn ín lọ́sàn-án àti lóru. Láti jẹ́ orí túmọ̀ sí pé ìwọ ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó ń léwájú nínú àwọn ohun tó níra – nípa ti ìṣúná, ìbágbépọ̀-àwùjọ, ìmọ̀sílára, ìbárìn, tàbí nípa ti ìlàkalẹ̀ ẹbí
Bákan náà, àyọkà òní jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé ọkùnrin yóò fi ìyá àti bàbá rẹ̀ sílẹ̀ láti lè darapọ̀ mọ́ ìyàwó rẹ̀, kì í sì ṣe ní ìdàkejì rẹ̀. Bí èyí kì í bá ṣe ìrètí gbogbogbòò nínú àṣà tàbí ní àwùjọ rẹ, o lè nílò láti pa àwọn ààlà kan sílẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ, kí o sì múra sílẹ̀ láti ní àwọn ìbánisọ̀rọ̀ tó le kan.
Ìgbéyàwó jẹ́ ìdàpọ̀ tí ó de ọkùnrin àti obìnrin nínú ìfarajìn títí láé sí ara ẹni bí wọ́n ṣe ń sín ìlànà ọkùnrin ńlá nnì jẹ - Jesu Kristi - ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ìyàwó rẹ̀ tí ó sì so wá papọ̀ mọ́ ara rẹ̀ títí láé. Kò ní fi wá sílẹ̀ láéláé. Àwa náà – àti pàápàá àwọn ọkùnrin tó ti gbéyàwó – yẹ kí ó ní àwòṣe yìí gẹ́gẹ́ bí àfojúsùn ńláláti lè jẹ́ ìbùkún ẹlẹ́wà tí Ọlọ́run ti fún wa gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Yálà ó ti ṣègbéyàwó tàbí o fẹ́ ṣe ìgbéyàwó, ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-mkta yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ètò rere Ọlọ́run fún ìfarajìn títí-ayé fún ọkọ àti aya. Kọ́ bí a ti ń ṣe àfihàn ìfẹ́ Jesu fún ìyàwó Rẹ̀, ìjọ, nípa ṣíṣe àwàjinlẹ̀ àwọn kókó bí i ìbádọ́rẹ̀ẹ́, ìbímọ, ìjẹ́rìí, ìjẹ́-mímọ́, àti ìgbádùn.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Kip' Chelashaw fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://christchurchke.org/