Ìgbéyàwó Gẹ́gẹ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Pète Rẹ̀Àpẹrẹ

Ìgbéyàwó Gẹ́gẹ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Pète Rẹ̀

Ọjọ́ 1 nínú 3

Ìṣẹ̀dá Ìgbéyàwó

Ọlọ́run pète ìgbéyàwó fún ìmúṣẹ àti ìgbèrú ènìyàn, àti pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéyàwó ń dínkù ní gbogbo àwọn ẹkùn àgbáyé, ó sì jẹ́ ara ètò rere Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Rẹ̀. Àwọn kàn fẹ́rẹ̀ gbàgbọ́ pé ìgbéyàwó jẹ́ ohun àtijọ́, nígbà tí àwọn kan tin ní àníjù èrò ìfẹ́ tí ó máa ń yọrí sí rúdurùdu. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pilẹ̀ pète ìgbéyàwó láti jẹ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ títí láé pẹ̀lú ìfẹ́, ìfarajìn papọ̀, sísín ìfẹ́ àìtàṣé tí Jesu ní fún ìyáwó Rẹ̀, ìjọ. Nítorí náà, ìgbéyàwó jẹ́ ohun tí ó yẹ ká fẹ́.

Ìgbéyàwó àkọ́kọ́ wáyé níbẹ̀rẹ̀ ayé, nínú Ọgbà Edẹni, láàrin Adamu àti Eefa. A dá Adamu láti ara èrùpẹ̀, kí Eefa sì tó dé, Ọlọ́run pàṣẹ fún Adamu láti ṣiṣẹ́ ní ayé kí ó sì dáàbò bò ó. Eefa, lẹ́yìn, ni a dá tààrà láti ara Adamu. (A lè sọ pé Adamu ni ‘àwòṣe pàtàkì’ – àwòṣe tí ó ṣe kókó jù – nígbà tí Eefa jẹ́ ẹ̀dà àkọ́fihàn!) ó ṣe pàtàkì láti kíyèsí pé ọkùnrin jẹ́ òṣìṣẹ́ tàbí olùpèsè àti pé ó tún jẹ́ aláàbò - ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú tí ó sì ń wá ire àwọn tí ó yí i ká. Kí ènìyàn tó subú sínú ẹ̀ṣẹ̀, Ọlọ́run fún wan í iṣẹ́ láti ṣe, ó sì pè é ní iṣẹ́ rere.

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti fi Adamu lọ́lẹ̀ láti pèsè àti láti dáàbòbò, Ó sọ nípa ìtara rẹ̀ fún ìdáwà Adamu. Èyí nìkan ni ohun tí kò dára nínú ayé tí ó pé tí kò tíì lẹ́ṣẹ̀. Èyí dájúdájú tọ́ka sí pàtàkì ìgbéyàwó. A nílò ara wa.

Ó tún fanimọ́ra pé Adamu kò tọ Ọlọ́run lọ láti bèèrè fún ẹlẹgbẹ́. Ọlọ́run ló ṣe ìdámọ̀ àìní Adamu tí ó msì pèsè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Adamu ní ọgbà tó rẹwà tó sì lọ́ràá àti ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àwọn ẹyẹ àti ẹranko, ohun kan kò sí. Ọrọ̀ àti ohun-ìní kò tó. Adamu nílò olùrànwọ́, ẹlẹgbẹ́/ọ̀rẹ́, irọ̀ ẹni tí ó lè bá sọ̀rọ̀ àti dàpọ̀. A lè rí ìyànjú fà jádé nínú èyí. Ọlọ́run mọ̀ wá, ó sì mọ ohun tí a nílò ju bí a ṣe mọ̀ ọ́n fúnra wa lọ, ó sì ju ẹni tí ó tó láti pèsè lọ.

Bí o kò bá tíì ṣe ìgbéyàwó tí o sì fẹ́ láti ṣe é, gbàdúrà lójoojúma pé Ọlọ́run yóò fi ọ́ hàn ìyàwó/ọkọ rẹ. fi àsìkò sílẹ̀ láti dúpẹ́ pé ìgbéyàwó kì í ṣe ohun tí ènìyàn dá sílẹ̀. Ó jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbèrú ní àwùjọ àti láti mọ ìbákẹ́gbẹ́ tó jinlẹ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn. Ìgbéyàwó jẹ́ àgbékalẹ̀ pípẹ́ - ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí ó ti ṣá. A ti ṣẹ̀dá wa pẹ̀lú àìní ìsopọ̀ àti ìdàpọ̀ pẹ̀lú ẹnìkàn tí ó dọ́gba tó sì yàtọ̀ síbẹ̀. Ó jẹ́ èrò rere Ọlọ́run láti bùkún wa pẹ̀lú ẹwà ìfarajìn títí láé.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Ìgbéyàwó Gẹ́gẹ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Pète Rẹ̀

Yálà ó ti ṣègbéyàwó tàbí o fẹ́ ṣe ìgbéyàwó, ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-mkta yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí ètò rere Ọlọ́run fún ìfarajìn títí-ayé fún ọkọ àti aya. Kọ́ bí a ti ń ṣe àfihàn ìfẹ́ Jesu fún ìyàwó Rẹ̀, ìjọ, nípa ṣíṣe àwàjinlẹ̀ àwọn kókó bí i ìbádọ́rẹ̀ẹ́, ìbímọ, ìjẹ́rìí, ìjẹ́-mímọ́, àti ìgbádùn.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Kip' Chelashaw fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://christchurchke.org/