ÌDÁRÍJÌNÀpẹrẹ
ÀWỌN ÀǸFÀÀNÍ ÌDÁRÍJÌN
Ìdáríjìn máa ń sọ ayé wa di titun kí á ba lè fẹ́ Ọlọ́run jìnlẹ̀, kí á sì nífẹ̀ẹ́ àwọn mìíràn ní tòótọ́ tayọ ipa ènìyàn tí a jẹ́. Díẹ̀ nínú àǹfààní ìdáríjìn ni:
• Àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run: Romu 5:1
• Ṣíṣètò ìbáṣepọ̀ tó dára: (Òwe 17:9)
• Máa ń mú ìwòsàn wá: Ìdáríjìn máa ń tun í sílẹ̀ lọ́wọ́ ìrora, ẹ̀dùn-ọkàn, ìkórira, àníyàn àti ìwà kíkorò, èyí tó ní agbára láti nípa lórí ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn, èyí tí ó tún lè nípa burúku lórí ìlera wa. Gẹ́gẹ́ bí ìkànnì Johnhopkinsmedicine.org ṣe sọ,’’ìwádìí ti fi hàn pé ìṣe ìdáríjìn lè ní èrè ńlá lórí ìlera rẹ, èyí tí ó máa ń mú àdínkù bá ewu ìkọlù ọkàn; dídára àwọn ìpele ọ̀rá ara àti oorun; àti pé ó máa ń dí ìrora, ẹ̀jẹ̀ ríru, àti àwọn ìpele àníyàn, ìrẹ̀wẹ̀sì-ọkàn àti wàhálà kù.’’ Àìní-ìdáríjìn ní ipa lórí burúkú pàápàá jùlọ lórí ẹni tí a ṣẹ̀ tí ó yàn láti dì í sínú.
Nígbà tí a bá dárí jin ni, à ń ṣe àfihàn ẹ̀dá Ọlọ́run.
Àwọn àǹfààní ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ kò lóǹkà. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ yan wíwá àti fífún ni ní ìdáríjìn láàyò. Nígbàkúùgbà tí a bá nílò láti ṣe bẹ́ẹ̀, bèèrè fún ìdáríjìn, yálà láti ọwọ́ Ọlọ́run, ọ̀rẹ́ kan, akẹgbẹ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí o bá ṣẹ̀. Bákan náà, lawọ́ sí dídáríjin àwọn tó wà ní àyíká rẹ. èyí ṣe pàtàkì fún ìlera ìgbésí-ayé ìgbàgbọ́/ẹ̀mí rẹ.
Ó tún ṣe pàtàkì láti ní ọkàn tó dára èyí tó máa ń fààyè gba àìpé àti àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn, láì maa ka àwọn àìṣedéédéé wọn ní gbogbo ìgbà. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe máa ń dárí jìn wá pátápátá, tí kìí dúró-retí láti fìyà rẹ̀ jẹ wa nígbà tí a bá tún ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà gbọ́dọ̀ nawọ́ ìdáríjìn aláìnídìí sí àwọn ènìyàn mìíràn.
Ìdáríjìn jẹ́ kókó-ọ̀rọ̀ tó dára gbáà; ṣùgbọ́n ìṣe rẹ̀ lè nira gidi. Yálà ó jẹ́ bíbèèrè fún ìdáríjìn tàbí nínawọ́ ìdáríjìn sí àwọn ẹlòmíràn, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbọn ìbára-ẹni-ṣepọ̀ tó le jùlọ, ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì sí ìgbésí-ayé Kristẹni.
A gbọ́dọ̀ dù lójoojúmọ́ láti gbọ́ràn sí ìlànà yìí láti dáríjinni, láti ní ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, àti láti ní àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn. Ọlọ́run fún gbogbo ènìyàn, àti pé èyí tó rẹwà níbẹ̀ ni pé kò tilẹ̀ rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́! Ọ̀daràn tí ó burú jù tí ó fi sùúrù wá sọ́dọ̀ rẹ̀ yóò rí ìdáríjìn gbà, yóò sì di mímọ́ gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Bí a ṣe ń gba ìdáríjìn, Ẹ̀mí Mímọ̀ ń fi agbára fún wa láti fún ni ní ìdáríjìn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìdáríjìn jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìgbésíayé Kristẹni fún ìbáṣepọ̀ àlààfíà àti èyí tó gbèrú pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn. Kì í ṣe pé Jésù tún ìdáríjìn ṣàlàyé nípa ìgbéayé àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún pèsè oore-ọ̀fẹ́ tí a nílò láti gba ìdáríjìn àti láti dárí jin ni nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀. Gbogbo ọmọ Ọlọ́run ni a ti fún ní agbára láti gbọ́ràn sí àṣẹ Ọlọ́run nípa dídáríjin ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe dárí jin àwọn tìkalára wọn.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/