ÌDÁRÍJÌNÀpẹrẹ

ÌDÁRÍJÌN

Ọjọ́ 2 nínú 3

KÍN NI ÌDÍ TÍ MO FI NÍLÁTI DÁRÍJINNI?

Jésù pa òwe kan nípa ọmọ-ọ̀dọ̀ kan kí ó jẹ olúwa rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ gbèsèṣùgbọ́n tí kò lè san padà. Olúwa rẹ̀ pa àṣẹ pé kí wọ́n dè é kí wọ́n sì jù ú sínú túbú títí di ìgbà tí yóò lè san án padà. Ṣùgbọ́n ọmọ-ọ̀dọ̀ náà ké fún àánú, olúwa rẹ̀ sí káàánú rẹ̀; ó dárí jìn ín, ó sì fagi lé gbogbo gbèsè rẹ̀.

Ọmọ-ọ̀dọ̀ náà dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ó sì kúrò. Lọ́gán tí ó jáde, ó rí akẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní gbèsè díẹ̀ ṣùgbọ́n tí òun náà kò lè san án padà. Dípò kí ó dárí jìn ín gẹ́gẹ́ bí òún náà ṣe rí gbà, ó di ọmọ-ọ̀dọ̀ akẹgbẹ́ rẹ̀ mú, ó sì tì í mọ́lé títí di ìgbà tí yóó lè san gbèsè rẹ̀ padà, èyí tí kò dùn mọ́ àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ yòókù nínú.

Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ yòókù tí inú bí sí ìwà ìkà rẹ̀ yìí jábọ̀ ọ̀rọ̀ náà fún olúwa wọn, ẹni tí ó ní ìjákulẹ̀ nínú ọmọ-ọ̀dọ̀ náà nítorí pé kò fi ohun tí ó ti rí gbà fún ni. Èyí mú kí ó rántí gbogbo gbèsè rẹ̀ tí ó sì ní kí wọ́n ti òun pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ mọ́lé títí di ìgbà tí ó bá san gbogbo gbèsè tí ó jẹ. Àkàwé yìí jẹ́ ẹ̀kọ́ lórí pàtàkì ìdáríjìn.

Nígbà tí ẹnìkan bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ kan jìn ni, Ọlọ́run rí wọn gẹ́gẹ́ bí ìkà àti pé Ó sọ pé òun yóò ré ìdáríjìn tí wan ti gbà kúrò. Gbígba àìlẹ́mìí ìdáríjìn láàyè máa ń yọrí sí ìkórira, ìbínú, ó sì lè yọrí sí àìsàn. Ó máa ń gé ẹ̀mí ìbáṣepọ̀ kúrú ó sì máa ń yọrí sí dúkùú lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹnìkan tilẹ̀ sọ nígbà kan pé àìlèdáríjinni dàbí mímú májèlé, nígbà tí à ń retí ẹlòmíràn láti kú. Ó máa ń pa ẹni tí a ṣẹ̀ ju ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ.

Kíkọ̀ láti dárí jin ni jẹ́ ìmọ̀ọ́mọ̀ yan àìgbọràn sí Ọlọ́run. Èyí lè gé ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú rẹ̀ kúrú ní ayé yìi, ó sì ní agbára láti yà wá nípa pẹ̀lú rẹ̀ títí ayé àìnípẹ̀kun.

Apá kan àdúrà Olúwa sọ pé, ‘’…dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá bí a ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jin àwọn tó ṣẹ̀ wá…’’ Èyí túmọ̀ sí pé ìkúnjú-òṣùwọ̀n láti rí ìdáríjìn èṣẹ̀ gbà lọ́wọ́ Ọlọ́runwà lọ́wọ́ ìpinnu wa láti dárí jin àwọn mìíràn. Á jẹ́ ohun tí kò pé láti gba ìdáríjìn lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí á wá kọ̀ láti dárí jin àwọn ẹlòmíràn. Ọlọ́run retí pé ó yẹ kí á fún ni ní ohun tí a ti rí gbà.

Bíbélì sọ pé, ‘’Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ jin àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín lọ́run náà kì yóò dárí jìn yín.’’

Nítorí náà, kín nìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ dárí jin ni? Nítorí pé Ọlọ́run pàṣẹ rẹ̀. Yíyàn láti gbàgbé ìrora àti ẹ̀dùn ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí á sì nawọ́ ìdáríjìn sí ni kì í ṣe àìlera tàbí agọ̀, dípọ̀ bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ yíyàn láti bu ọlá fún Ọlọ́run àti láti gbọ́ràn sí àwọn ìlànà rẹ̀. Fún tiwa náà ni, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì tó láti ràn wá lọ́wọ́ láti la ìgbésẹ̀ náà já.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

ÌDÁRÍJÌN

Ìdáríjìn jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìgbésíayé Kristẹni fún ìbáṣepọ̀ àlààfíà àti èyí tó gbèrú pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn. Kì í ṣe pé Jésù tún ìdáríjìn ṣàlàyé nípa ìgbéayé àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún pèsè oore-ọ̀fẹ́ tí a nílò láti gba ìdáríjìn àti láti dárí jin ni nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀. Gbogbo ọmọ Ọlọ́run ni a ti fún ní agbára láti gbọ́ràn sí àṣẹ Ọlọ́run nípa dídáríjin ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe dárí jin àwọn tìkalára wọn.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/