ÌDÁRÍJÌNÀpẹrẹ

ÌDÁRÍJÌN

Ọjọ́ 1 nínú 3

KÍN NI ÌDÁRÍJÌN?

Wòye ọ̀daràn kan tó dá ọ̀ràn ńlá sí òfin ìjọba, tí ikú sì tọ́ sí; ṣùgbọ́n kí wọ́n tó dá ẹjọ́ ikú fún un, àánú ṣe adájọ́, ó sì pinnu láti forí jìn ín dípò kí ó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀. Ọ̀daràn náà gba òmìnira -wọ́n sì dá a sílẹ̀ láìjẹ̀bi ọ̀ràn kankan; èyí tí í ṣe àǹfààní kejì láyé.

Ìdáríjìn, tí í náwọ́ àánú àti oore-ọ̀fẹ́ sí ni, jẹ́ olóròó àti oníbùú.

Ìdáríjìn olóròó ni èyí tí a gbà nípasẹ̀ ikú Kristi, èyí tí ó pẹ̀tù sí ìbínú Ọlọ́run tí ó fi jẹ́ pé dípò kí á gba èrè ẹ̀ṣẹ̀ Efesu 1:7 di òtítọ́ fún wa.

‘’Nínú ẹni tí àwá ní ìràpadà wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀;’’

Ìrúfẹ̀ ọ̀nà ìdáríjìn yìí kò ṣe é rí gbà lẹ́yìn Kristi. Òun ni ó fi wá sí ipò tó yẹ pẹ̀lú Ọlọ́run tó sì ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìgboyà wọn ibi mímọ́ jùlọ torí pé a ti dáríjìn wa. Gbígbà ìdáríjìn yìí ṣe pàtàkì sí dídi Kristẹni. Ìdáríjìn yìí ni ohun tó ń yí ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku padà sí ẹni mímọ́ tí ó wá ní gbé ìgbé ayé rẹ̀ lójoojúmọ́ láti wu Ọlọ́run. Ọ̀fẹ́ ni; o kò lè ṣiṣẹ́ fún tàbí kí ó tọ́ sí ọ. Jésù ni ìrúbọ tí ó ràn wá lọwọ́ láti gba Ìdáríjìn yìí. Kò sí bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣe le burú tó, kò lè ka Ọlọ́run láyà. Lọ́gán tí o bá ti tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú ìrònúpìwàdà tòótọ́, wà á gba ìdáríjìn.

Ìdáríjìn oníbùú nídàkejì ẹ̀wẹ̀ jẹ́ ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún wa láti fún àwọn ẹlòmíràn nínú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ènìyàn lójoojúmọ́. Pétérù, nínú ìwòye rẹ̀ lórí bí ènìyàn ṣe lè nawọ́ àánú àti oore-ọ̀fẹ́ sí ẹlẹ́ṣẹ̀, bi Jésù léèrè iye ìgbà tí ó yẹ kí òun dáríjin ẹni tó bá ṣe òun nínú Ìwé Matiu 18:21. Ìdáhùn Jésù ṣe àfihàn bí ó ṣe yẹ kí á lawọ́ tó pẹ̀lú dídárí jinni. “…Títí di ìgbà àádọ́rin méje.” Jésù pè wá sí ìgbésí-ayé ìṣoore àti ìkáàánú sí àwọn ẹlòmíràn.

Lílè dárí jinni wà lọ́wọ́ òye rẹ nípa ìwúwo ìdáríjìn tí o ti rí gbà. Yíyàn láti jọ̀wọ́ àwọn èrò ìkórira àti ìfẹ́ láti gbẹ̀san lára ẹni tí ó ti ṣẹ̀ ọ́ jẹ́ ìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run láti dárí jin ni. Èyí kò túmọ̀ sí pé o kò ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣùgbọ́n ìdáríjinnni túmọ̀ sí ìrántí rẹ̀ kò mú ẹ̀dùn ọkàn wá mọ́, kò sì tún sí èrò láti gbẹ̀san. Ní báyìí, gbogbo ohun tí ò ń gbà lérò sí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ni ìkáàánú àti ìṣoore, èyí tí ó ń gún o ní kẹ́sẹ́ láti bá wọn ṣe pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́, yálà wọ́n túúbá tàbí wọn kò túúbá.

Èyí lè dàbí ohun tí kò ṣe é ṣe, ṣùgbọ́n pẹ̀lú Ọlọ́run, Ìdáríjìn sọ pé, ‘’Mo ṣe é ṣe’’. Rọ̀ mọ́ ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ láti jọ̀wọ́ ẹnikẹ́ni tí o ti dè nígbèkùn àìnídáríjìn nítorí pé àwọn ẹni tí a ti dáríjìn yẹ kí ó dáríjin àwọn ẹlòmìíràn nítorí ìdáríjìn ta gbòǹgbò sínú ikú ìrúbọ Jésù láti fún wan í ìdáríjìn.

Ǹjẹ́ a ti dárí jìn ọ́? Taa ni o nílò láti dárí jìn lónìí? Bèèrè oore-ọ̀fẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

ÌDÁRÍJÌN

Ìdáríjìn jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìgbésíayé Kristẹni fún ìbáṣepọ̀ àlààfíà àti èyí tó gbèrú pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn. Kì í ṣe pé Jésù tún ìdáríjìn ṣàlàyé nípa ìgbéayé àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún pèsè oore-ọ̀fẹ́ tí a nílò láti gba ìdáríjìn àti láti dárí jin ni nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ̀. Gbogbo ọmọ Ọlọ́run ni a ti fún ní agbára láti gbọ́ràn sí àṣẹ Ọlọ́run nípa dídáríjin ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe dárí jin àwọn tìkalára wọn.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/