Àwọn Ìkùnà Wa Gẹ́gẹ́ bí KristẹniÀpẹrẹ
Dáríjìn
Lulu kọ̀wé rẹ̀ pé, kí Kristi tó ki Peteru nílọ̀ pé yóò ṣẹ́ Òun lẹ́ẹ̀mẹta, Kristi sọ fún Peteru: ‘Simoni, Simoni, Satani ti dù láti gbá ọ dànù bí èpò. Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, pé kí ìgbàgbọ́ rẹ máṣe kùnà. Nígbà tí o bá sì ti yípadà, gbé àwọn ará rẹ ró.’ Peteru wá tẹ̀síwájú’, gẹ́gẹ́ bí a tí rí i, láti ṣẹ́ Kristi. Ìyànjú Peteru kùnà, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ Peteru, kì í ṣe bí ti Judasi, kò kùnà.
Ní ó ku díẹ̀ kí Ìhìnrere Johanu parí, Kristi tó jíǹde yọ dé láti ibikíbi lẹ́bàá odò Galili. Ó sì jẹ́ kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja pẹ̀lú ìyanu, ó sì bá wọn jẹ oúnjẹ àárọ̀ ní bèbè odò.
Lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti jẹun tán, bí wọ́n sì ti ń rìn kúrò létí bèbè odò náà, Kristi bèèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ Peteru: ‘Peteru, ṣé o fẹ́ mi?’ Kristi bèèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ Peteru lẹ́ẹ̀mẹta, gkgẹ́ bí ẹ̀ẹ̀mẹta tí Peteru ti ṣẹ́ Ẹ́.
Mo gbàgbọ́ pé Kristi ṣe èyí láti fi dá Peteru lójú pé ìgbàgbọ́ Peteru nínú Kristi, àti ìgbàlà rẹ̀ kò tíì kùnà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Peteru ti pàdánù ìgboyà rẹ̀ nínú àgbàlá olórí àlùfáà. Èyí ni Kristi tó jíǹde, ẹni tí ó ti wà lórí àgbélèbú, lórí àgbélèbú ó sì tik ó gbogbo ẹ̀bi, ìkùnà, ìtìjú, ẹ̀sín, ìfiṣẹlẹ́yà, àti ẹ̀ṣẹ̀ Peteru sí orí ara Rẹ̀.
Jọ̀wọ́ kíyèsí bí Kristi tó jíǹde kò ṣe bú Peteru kín ó sì sọ fún un pé: ‘Mo rò pé o ní láé o kò ní ṣẹ́ mi ni?’ Èyí ni ohun tí èmi àti ìwọ ìbá ti ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Pé Kristi kò bú wa, ó fi ìdí Ìhìnrere òtítọ́ ti Johanu múlẹ̀: Ọlọ́run kò rán ọmọ Rẹ̀ wá sínú ayé láti dá aráyé lẹ́bi, ṣùgbọ́n láti gba aráyé là nípasẹ̀ Rẹ̀. Kristi kò bú Peteru nítorí pé kò wá láti wá dá Peteru lẹ́bi, ṣùgbọ́n láti gbà á là.
Ẹ̀yin ará mi lọ́kùnrin àti lóbìnrin, Kristi ti ru gbogbo àwọn ìkùnà, ẹ̀bi àti ìtìjú wa. Nígbà tí a bá fi ìgbàgbọ́ wa sínú ohun tí Kristi ti ṣe fún wa lórí àgbélèbú, Ọlọ́run á dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn wá, Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀ yóò sì bá wa gbé, tí ó sì ń fi ìgbésí-ayé Kristi tó jíǹde fún wat í ó sì ń ró wa lágbára láti kọ ẹ̀ṣẹ̀.
Kristi tik ú fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti lè ṣẹ̀ tàbí èyí tí a ó ṣẹ̀. Nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá gún wan í kẹ́sẹ́ pé a ti ṣẹ̀, a ní láti gbà bẹ́ẹ̀, kí á sì fi ìgbàgbọ́ gba ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ tí í ṣe tiwa nínú Kristi. Ìdí nìyí tí Paulu fi rán wa létí pé ọ̀kan nínú ìlérí ògo ti ìhìnrere nip é Ọlọ́run gbà wá là pẹ̀lú líla ojú Rẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run mọ ohun tó burú jù nípa wa yálà sáájú tàbí lẹ́yìn ìgbàlà wa, ìpinnu Rẹ̀ láti fi lè gbà wá là nínú Kristi ni òpin ìpinnu tí ẹnikẹ́ni kò lè yípadà!
Ní kúkúrú, Ọlọ́run mọ kókó ìkùnà wa, àti pé ẹni tí ó mọ àwọn ìkùnà wa ṣáájú wọn, ti ti ipa Kristi àti ìhìnrere pinnu láti dárí jin gbogbo ìkùnà wa.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà ọlọ́jọ́-márùn-ún agbaní-níyànjú yìí ṣe àlàyé òtìtọ́ náà pé, nínú àṣẹ-ìdarí Rẹ̀, Ọlọ́run ti rí ìkùnà wa ṣáájú, àti pé nínú àánú Rẹ̀, ó dárí jin àwọn ìkùnà wa.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Returning to the Gospel - West Africa fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://returningtothegospel.com/