Àwọn Ìkùnà Wa Gẹ́gẹ́ bí KristẹniÀpẹrẹ
Ṣíṣẹ́ Ọlúwa láti ọwọ́ Peteru
Ìtàn àjíǹde tí àwọn ènìyàn ò kọbi ara sí jẹ́ ìtàn bí Apostei Peteru ṣe ṣẹ́ Olúwa. Ìtàn àjíǹde nípa ìkùnà Peteru yìí ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan ńinú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Àjíǹde tí a kọ sínú àwọn Ìwé Ìhìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti Májẹ̀mú Titun.
Ó hàn sí mi pé ó dàbí ìtàn yìí ṣe pàtàkì nítorí pé ó ṣe àfihàn fún wa ìwòye ìhìnrere níppa àwọn ìkùnà wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Lákọ̀ọ́kọ́, ìtàn náà kọ́ wa pé Ọlọ́run ṣe ìdámọ̀ kókó ìkùnà wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Lẹ́ẹ̀kejì, ìtàn náà kọ́ wa pẹ̀ Ọlọ́run ti rí ìkùnà wa ṣáájú gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Lẹ́ẹ̀kẹta àti ní pàtàkì jùlọ, ìtàn yìí kọ́ wa pé Ọlọ́run ń dárí ìkùnà wa jìn wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.
Nípasẹ̀ ìlànà kíkà ọlọ́jọ́-márùn-ún yìí, a ó fi ojú ìhìnrere wo ọ̀kọ̀ọ̀kan agbọn àwọn ìkùnà wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Èyí yóò gbà wá níyànjú gan-an nígbà tí, nínú ìrìn wa pẹ̀lú Ọlọ́run, a kùnà láti jẹ́ gbogbo ohun tí a mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ ká jẹ́, a sì kùnà láti jẹ́ gbogbo ohun tí a fẹ́ jẹ́ fúnra wa.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà ọlọ́jọ́-márùn-ún agbaní-níyànjú yìí ṣe àlàyé òtìtọ́ náà pé, nínú àṣẹ-ìdarí Rẹ̀, Ọlọ́run ti rí ìkùnà wa ṣáájú, àti pé nínú àánú Rẹ̀, ó dárí jin àwọn ìkùnà wa.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Returning to the Gospel - West Africa fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://returningtothegospel.com/