Àwọn Ìkùnà Wa Gẹ́gẹ́ bí KristẹniÀpẹrẹ
Ìmọ̀tẹ́lẹ̀
Matiu sọ nípa pé Kristi ti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé ọ̀kan nínú wọn yóò fi Í hàn. Ó ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lẹ́nu láti gbọ́ èyí. Wọ́n fèsì nípasẹ̀ sísọ pé, ‘kò lè jẹ́ èmi! Rárá! Kì í ṣe èmi!’
Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ‘Ní àṣálẹ́ yìí gan-an ni gbogbo yín yóò sá lọ nítorí Mi.’ Bákan náà ni wọ́n tún fèsì nípa sísọ pé: ‘Rárá, rárá, rárá! A kò ní ṣe bẹ́ẹ̀!’ Ní àsìkò náà, kò sí ẹni tí ó fura sí Judasi nínú wọn. Peteru fèsì nípa sísọ pé, ‘Èmi? Láéláé! N kò ní fi Ọ́ hàn, kódà bí gbogbo àwọn wọ̀nyí bá ṣe bẹ́ẹ̀! O mọ̀ mí, Olúwa! Èmi pẹ̀lú ti múra sílẹ̀ láti kú fún Ọ!’ ṣùgbọ́n Jesu fèsì pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀ pé kí àkùkọ tó kọ ní ọjọ́ kejì, Peteru yóò ṣẹ̀ Òun ní ẹ̀ẹ̀mẹta.
Ní ọ̀nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ìkùnà Judasi àti Peteru àti ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ni Olúwa ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ó y ani lẹ́nu pé Johanu kọ ọ́ pé lẹ́yìn tí Kristi ti sọ fún Peteru pé Peteru yóò ṣẹ́ Òun, Ó tẹ̀síwájú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti tu Peteru àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù nínú pé, ‘Máṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàámú. Gba Ọlọ́run gbọ́, kí o sì gbà Mí gbọ́ pẹ̀lú.’
Àwọn wọ̀yẹn jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyanu tòótọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé Kristi mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo wọn kò ní pẹ́ sá Òun tì. Nígbà tí Kristi sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ohun tí ó tilẹ̀ ń sọ sí wọn nìyí:
‘Mo mọ̀ dájú pé ọ̀kan nínú yín yóò fi Mí hàn, àti pé ọ̀kan nínú yín yóò ṣẹ́ Mi, àti pé gbogbo yín ni yóò sá Mi tì. Ṣùgbọ́n bákan náà, Mò ń lọ sórí àgbélèbú láti kú fún yin, nítorí náà, ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dààmú.’
Ǹjẹ́ ìyẹn ò way ani lẹ́nu?
Ní kúkúrú, ọpẹ́ fún Ọlọ́run! Gbogbo àwọn ìkùnà wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ni Ọlọ́run ti rí tí Ó sì ti mọ̀ ṣáájú, ẹni tí ó fẹ́ wa bẹ́ẹ̀.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìlànà ọlọ́jọ́-márùn-ún agbaní-níyànjú yìí ṣe àlàyé òtìtọ́ náà pé, nínú àṣẹ-ìdarí Rẹ̀, Ọlọ́run ti rí ìkùnà wa ṣáájú, àti pé nínú àánú Rẹ̀, ó dárí jin àwọn ìkùnà wa.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Returning to the Gospel - West Africa fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://returningtothegospel.com/