Awọn itan keresimesiÀpẹrẹ

The Christmas Story

Ọjọ́ 4 nínú 5

A Wá Láti Jọ́sìn Fún

Ọlọ́run ń pe oríṣi agbo ènìyàn méjì láti yọ ayọ̀ ìbí Jésù. Ẹgbẹ́ méjèèjì ń yani lẹ́nu, àwọn méjèèjì sì ń sọ ohun kan fún wa ní pa Ọlọ́run. 

Ìpè àkọ́kọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn kan. Áńgẹ́lì kan yọ sí wọn ó sì sọ ìròhìn ayọ̀ náà fún wọn. Lẹ́yìn èyí àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà lọ láti jọ́sìn Jésù.

Ìpè ìkejì lọ sí ta sí gbogbo ayé. Lẹ́yìn ìbí Jésù, ìràwọ̀ kan yọ lóríi Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àwọn irúfẹ́ ènìyàn kan láti gbùngbùn míràn ayé rí ìràwọ̀ yí wọ́n sì tẹ̀lé e. A kò mọ púpọ̀ nípa wọn tàbí iye àwọn tó rin ìrìn àjò yí. Ṣùgbọ́n wọ́n wá Jésù rí, wọ́n sì sì ń pẹ̀lú ẹ̀bùn wọn.

Kí wá ni ohun tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àwọn àlejò oríṣi méjì tí ó wà nínú ìtàn yí? Yàtọ̀ sí àwọn ǹkan wọ̀nyí, ó fi hàn bí Jésù ṣe kó onírúurú ènìyàn jọ.

Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ò yàtọ̀ sí Màríà àti Jósẹ́fù. Ènìyàn tí kò dàbí alárà ni wọ́n láti ìletò kékeré, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ alábódé láti gbọ́ bùkátà ojojúmọ́.

Ṣùgbọ́n àwọn àlejò òkèèrè kò leè ṣe aláìmáyàtọ̀. Ìlú míràn ni wọ́n ti wá ó sì ṣeéṣe kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ míràn. Ó tún jọ pé wọ́n ní ọrọ̀ àti òkìkí, tí Màríà àti Jósẹ́fù kò ní. 

A mọ̀ pé àwọn ìyàtọ̀ oríṣiríṣi yìí lè mú ìpínyà wà láàrin àwọn ènìyàn. Gbogbo wa láti ríi, ìbáàjẹ́ àjọṣepọ̀ ẹni pelu àwọn míràn tàbí nínú ìgbé-ayé àwọn ẹlọ̀míràn. Ṣùgbọ́n ìtàn Kérésìmesì mú kó ṣeéṣe kí gbogbo ènìyàn jọ sẹ́ pọ̀. Ọlọ́run Ń fẹ́ kí gbogbo ènìyàn jẹ́ ọ̀kan nínú ẹbí Rẹ̀. Fún ìdí èyí, Ọlọ́run pe gbogbo àti àwọn tó wà ní tòsí àti àwọn tó wà ní jìnà réré láti ṣe àjọyọ̀ fún Jésù.

Ìbí Jésù kó ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kò jọra jọ. Èyí hàn nínú ìtàn Kérésìmesì, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun tí à ń bá pàdé ní gbogbo ìgbà ní ìgbé ayé Jésù. Ó Ń pilẹ̀ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú onírúurú ènìyàn tí ìpìlẹ̀ wọn kò ti lẹ̀ jọra. Àti pẹ̀lú láti ipasẹ̀ àwọn àjọṣepọ̀ yí, Ó ṣe okùnfà ìwópalẹ̀ àwọn ohun ìdìgbòlù bíi àwùjọ tá gbé, ọrọ̀ ajé, àti ìṣèlú àwọn ǹkan tí ń mú ìyapa wà. 

Ọlọ́run Ń kó ìdílé ká àgbáyé—fún ìdí èyí Ó ún tọ́ wa láti jọ̀wọ́ àwọn èrò inú tó dá lóríi to let go of an “àwa ní ìdojúkọ sí ẹ̀yin.” Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ohun tí à yọ̀ lé lórí nígbà Kérésìmesì: Jésù Ń fi agbára tó wà nínú ìrẹ̀lẹ̀, àjọṣepọ̀, àti ìkáàánú.

Gbàdúrà: Ọlọ́run mi, Ẹ ṣeun tí Ẹ pè mí láti jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Yín l'ágbàáyé. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ kí ń leè fi iyè sí báwo ni mọ ti ṣe leè pi lẹ̀ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó yàtọ̀ sí mi. Sì fi hàn mí ẹni tí mọ leè pè láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ. Ní orúkọ Jésù, àmín.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

The Christmas Story

Gbogbo ìtàn gidi ló ní ìyípadà ìtàn - àkókò àìròtẹ́lẹ̀ tí ó yí gbogbo nǹkan padà. Ọ̀kan lára àwọn ìyípadà ìtàn tó tóbi jùlọ nínú Bíbélì ni ìtàn Kérésìmesì. Ní ọjọ́ márùn-ún tó ń bọ̀, a máa ṣàwárí bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan yìí ṣe yí ayé padà àti bí ó ṣe lè yí ayé rẹ padà lónìí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọ̀wọ́ lọ sí www.life.church