Awọn itan keresimesiÀpẹrẹ
Kí ni ìdí tí mo fi jẹ́ ẹni tí ó gba ojúrere gàn?
Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ ìròyìn ayọ̀ fún ẹ tí o bá ti ronú rí pé o kò já mọ́ nǹkan kan, pé o kò tó fún iṣẹ́ náà tàbí pé wọn ò kà ẹ́ sí. Kí n'ìdí? Ìdí ni pé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni olórí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn Kérésìmesì.
Fún ìṣẹ́jú kan, gbàgbé gbogbo ohun tí o mọ̀ nípa ìtàn Kérésìmesì. Ṣé o ti ṣe tán? Rò ó wò ná, ká sọ pé o wá mọ̀ pé Ọlọ́run máa tó wá s'áyé, o sì mọ̀ pé inú ìdílé èèyàn ni wọ́n máa bí I sí. Irú àwọn èèyàn wo ni Ọlọ́run yàn láti jẹ́ òbí Rẹ̀?
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìdílé kan tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tí ó l'ágbára, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bí kìí bá ṣe àwọn, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ tọkọtaya kan tí wọ́n ní ohun ìní tàbí ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tẹ̀mí.
Àmọ́ rántí pé, ọ̀pọ̀ nǹkan ìyàlẹ́nu ló ṣẹlẹ̀ nínú Ìtàn Kérésìmesì. Nítorí Ọlọ́run kò yan tọkọtaya olówó àti alágbára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yan ọ̀kan l'ára àwọn èèyàn tí o kò lè retí.
Ọ̀dọ́ ni Màríà, kò sì tíì lọ́kọ, ìlú kékeré kan ló ń gbé. Kò ní agbára kankan, kò sì ní ipa tó pọ̀ lọ títí. Ènìyàn lásán ni, àmọ́ Ọlọ́run yàn-án láti ṣe ohun tí ó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀.
Ońṣẹ́ Ọlọ́run kan sọ fún Màríà pé ó l'óyún Olùgbàlà tí a ṣè'lérí, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé wúńdíá ni. Lónìí, a ó ka bí Màríà ṣe f'èsì nígbà tí ó rí ipa ìyanilẹ́nu tí ó máa kó nínú ìtàn Ọlọ́run. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí Màríà mọ̀ pé Ọlọ́run ń rí àwọn èèyàn bíi tiẹ̀, Ó sì bìkítà nípa wọn. Àti pé Olùgbàlà yìí yóò gbé àwọn èèyàn tí ayé kà sí aláìjámọ́ nǹkan kan ga.
Ìtàn Kérésìmesì kò jẹ́ k'éèyàn ronú pé èèyàn gbọ́dọ̀ ní ọrọ̀, kí ó jẹ́ ẹni tí ó ń ṣ'àkóso, tàbí kí ó jẹ́ ẹni tí ó ń gbé orí pèpéle kí ó tó lè ṣ'àṣeyọrí. Àwọn tí kò já mọ́ nǹkan kan, àwọn gbáàtúù, àt'àwọn tí kò tóótun ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run. Nítorí náà, Ó yàn láti bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ láti fi han ayé pé Òun bìkítà fún gbogbo ènìyàn.
Nígbà tí o tún ti ronú pé o kò já mọ́ nǹkan kan tàbí pé o kò tóótun, rántí Ìtàn Kérésìmesì. Ìránnilétí tí ó l'ágbára ni pé ìníyelórí wa wá lát'ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Ẹni tí Ó rí wa, tí Ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí Ó sì fẹ́ bá wa ṣe àjọṣepọ̀ láti pe àwọn ẹlòmíràn s'ínú ìdílé Ọlọ́run.
Gbàdúrà: Ọlọ́run mi, mo dúpẹ́ gan-an fún ìfẹ́ẹ̀ Rẹ. Ràn mi l'ọ́wọ́ kí n lè gbé ìmọrírì ara mi ka'ríi bí O ṣe nífẹ̀ẹ́ mi tó, láì gbe l'órí èrò àwọn ẹlòmíràn. Jọ̀wọ́ darí mi sí àwọn èèyàn tí ara ń ni, tí wọ́n ro pe won kò já mọ́ nǹkan kan, kí n bàa lè máa ṣe irú àbójútó tí Ìwọ náà ṣe fún mi. Ní orúko Jésù, àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ìtàn gidi ló ní ìyípadà ìtàn - àkókò àìròtẹ́lẹ̀ tí ó yí gbogbo nǹkan padà. Ọ̀kan lára àwọn ìyípadà ìtàn tó tóbi jùlọ nínú Bíbélì ni ìtàn Kérésìmesì. Ní ọjọ́ márùn-ún tó ń bọ̀, a máa ṣàwárí bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan yìí ṣe yí ayé padà àti bí ó ṣe lè yí ayé rẹ padà lónìí.
More