Awọn itan keresimesiÀpẹrẹ
Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú
Ìtàn Kérésì kún fún oríṣirísi ìyanu. Ní ọjọ́ márùnún ní ṣísẹ̀ǹtẹ̀lé, a ó máa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn kókó àti kòmóòkùn ìtàn láíláí yìí, kí a sì ṣ'àwárí ohun tí ó túmọ̀ sí fún wa lónìí.
Ṣe ó jọ bíi ẹni pé Ọlọ́run jìnà réré sí ọ rí? Bóyá ó dàbíi ẹnipé Ó dákẹ́ tàbí kò tilẹ̀ rí ohun tí ò ń là kọjá. Bí ó bá rí báyìí fún ọ, kìí ṣe ìwọ nìkan.
F'ojú inú wòó pé o jẹ́ ara àwùjọ kan tí àwọn ọ̀tá gbógun tì. Wọ́n ń ṣ'àkóso orílẹ̀-èdè rẹ, wọ́n sì mú ayé le koko. O dàgbà sínú ìtàn bí Ólọ́run ṣe ní ìfẹ́ àwọn ènìyàn rẹ tó. Ṣùgbọ́n bí ọdún ṣe ń g'orí ọdún, o lè máa wòó pé, Ṣé lóòtọ́ ni Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa báyìí?
Báyìí gan an ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ará Ìsràẹ́lì àtijọ́ ṣe l'érò ní àwọn ọdún tó ṣáájú ìwásáyé Jésù. A tẹ̀ wọ́n lórí ba, àwọn olórí jẹgúdújẹrá tí wọn ní sì wọ́n lò ní ìlò ẹrú. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run yíó ran Olùgbàlà wá láti dá wọn n'ídè kí Ó sì mú wọn padà bọ̀ sí'pò ní pípé.
Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni o máa ń r'etí tí o sì ń gbàdúrà kí ńkan lè yípadà ṣùgbọ́n tí kò dá ọ lójú bóyá Ọlọ́run yíó dáhùn? Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ náà k'ojú ohun tí àwọn ènìyàn Ìsráẹ́lì k'ojú. Ṣùgbọ́n nínú dídúró wọn, Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn.
Ṣugbọ́n Ọlọ́run kò kàn dúró lásán. Ó ń ṣiṣẹ́ l'ábẹ́nú láti ṣe ohun tó yanilenu tí ó sì kún fún ìyanu tí enikẹni kò l'èrò.
Kò kàn rán olùgbàlà kan ṣáá. Ó wá fúnraarẹ̀. Ṣùgbọ́n kìí ṣe bíi alágbára tàbí jagunjagun. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ó rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀, Ó di ọ̀dọ́mọdé jòjòló nínú ọmọbìnrin kan tí à ń pé ní Màríà.
Bí o bá ti kọ'minú rí pé bóyá Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ, ronú nípa ìtàn Kérésì. Nítorí pé Ọlọ́run wà fún wa nígbà gbogbo, Ó sì ń ṣ'iṣẹ́, kódà bí a kò tilẹ̀ ríi nígbà gbogbo.
Gbàdúrà: Ọlọ́run Ọ̀wọ̀n, O ṣeun nítorí O wà pẹ̀lú wa. Jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ làti gbẹ́kẹ̀lé Ọ, kódà nígbàtí mi ò kẹ́ẹ́fín Rẹ nítòsí mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìgboyà nínú ìfẹ́ Rẹ bí mo ti ń ṣe àṣàrò lórí ìtàn ìyanu Kérésì. Ní orúkọ Jésú, àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ìtàn gidi ló ní ìyípadà ìtàn - àkókò àìròtẹ́lẹ̀ tí ó yí gbogbo nǹkan padà. Ọ̀kan lára àwọn ìyípadà ìtàn tó tóbi jùlọ nínú Bíbélì ni ìtàn Kérésìmesì. Ní ọjọ́ márùn-ún tó ń bọ̀, a máa ṣàwárí bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan yìí ṣe yí ayé padà àti bí ó ṣe lè yí ayé rẹ padà lónìí.
More