Awọn itan keresimesiÀpẹrẹ

The Christmas Story

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ọmọ Dáfídì

Báwo lo ṣe máa sọ fún àfẹ́sọ́nà rẹ pé o l'óyún Olùgbàlà tí Ọlọ́run ṣè'lérí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìbéèrè tí Màríà ń bi ara rẹ̀ nìyẹn lẹ́yìn tí ó gbọ́ ìhìn rere náà. N'ígbà tí Jósẹ́fù gbọ́, ó kọ́kọ́ pinnu pé òun ò ní bá Màríà ṣe mọ́. Àmọ́, Ọlọ́run fẹ́ kí Jósẹ́fù wà lára àwọn tí ìtàn yìí kàn. 

Nínú ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ ti òní, Ọlọ́run rán ońṣẹ́ kan sí Jósẹ́fù, ó sọ fún-un nípa àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ náà. Ońṣé náà pe Jósẹ́fù ní "Ọmọ Dafidi", èyí jẹ́ kàyéfì, nítorí pé Dafidi kìí ṣe orúkọ bàbá Jósẹ́fù. 

Dáfídì ti gbé ayé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú Màríà àti Jósẹ́fù. Ìlú kékeré ni Dáfídì náà ti wá, iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló sì ń ṣe. Àmọ́ l'ọ́jọ́ kan, Ọlọ́run rán ońṣẹ́ kan sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti sọ fún Dáfídì pé Òun ti yàn-án láti ṣ'àkóso gẹ́gẹ́ bíi ọba. 

Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run ṣè'lérí pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Dáfídì yóò dá ìjọba tuntun tí ó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ s'ílẹ̀, èyí tí ó tó máa bùkún gbogbo ayé. Dáfídì àt'àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ jẹ́ aláìpé, wọ́n sì sábà máa ń ṣe àwọn ìpinnu tí kò dára, èyí tí ó mú kí ìjọba wọn parun. Àwọn èèyàn náà mọ̀ pé tí wọ́n bá máa ní ìjọba tuntun tí ó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, wọ́n nílò Dáfídì tuntun tó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nítorí náà, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran, àwọn èèyàn ń dúró de "Ọmọ Dáfídì" láti dé.

Èyí jẹ́ kí a rántí Jósẹ́fù, tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ olùṣọ́ àgùntàn tó wá di ọba. Jósẹ́fù jẹ́ aláìpé, gẹ́gẹ́ bí gbogbo àtọmọdọ́mọ Dáfídì yòókù títí di àkókò yẹn, ṣùgbọ́n Ọmọ Dáfídì tòótọ́ tí kò ní àbùkù yóò wá sí ayé nípasẹ̀ Màríà—tí ó d'ara pọ̀ mọ́ ìdílé Jósẹ́fù bíi aya. Nítorí náà, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù kìí ṣe baba Jésù nípa t'ara, síbẹ̀ òun àti Màríà ló tọ́ Jésù dàgbà—ó sì t'ipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan l'ára ìdílé Dáfídì.

Jósẹ́fù mú Màríà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìlú Dáfídì. Ibẹ̀ sì ni Màríà ti bí Jésù, tó jẹ́ Ọmọ Dáfídì ní ti òótọ́. Àwọn wo ló sì kọ́kọ́ mọ̀ nípa Ọmọ Dáfídì? Ó dájú pé, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ni. 

Ìtàn Kérésì rán wa létí pé a jẹ́ ara ohun kan tí ó tóbi jù wá lọ. Láti ọjọ́ tí áláyé ti d'áyé ni Ọlọ́run ti ń bá àwọn èèyàn ṣiṣẹ́ láti mú kí ilẹ̀ ayé dà bíi ti ọ̀run. Dáfídì àti Jósẹ́fù ti kó ipa wọn. Àmọ́ ìtàn náà ṣì ń tẹ̀ s'íwájú, ó sì wá di àkókò tiwa báyìí. 

Báwo ni a ṣe lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ wọn? A rí ọ̀nà kan nínú àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì tí a kà lónìí. Kíyèsí bí Jósẹ́fù ṣe ṣe nígbà tí Ọlọ́run pè é. Wàá ríi pé ó máa ń tẹ́tí sílẹ̀, ó máa ń gbàgbọ́, ó sì máa ń yááfì àwọn nǹkan kan láti ran àwọn èèyàn l'ọ́wọ́. Bí a bá ṣe irú ìpinnu yìí, a ó máa mú kí ìtàn Ọlọ́run tẹ̀ s'íwájú. 

Gb'àdúrà: Olódùmarè, O ṣeun fún pípè wa sínú ìtàn Rẹ. Mo mọ̀ pé mo ní ipa tí mo lè kó nínú sísọ ayé di ọ̀run. Nítorí náà jọ̀wọ́ ràn mí l'ọ́wọ́ láti mọ̀ bí O ṣe ń pè mí láti ṣe àyípadà nínú ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn. Ní orúkọ Jésù, ámín. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

The Christmas Story

Gbogbo ìtàn gidi ló ní ìyípadà ìtàn - àkókò àìròtẹ́lẹ̀ tí ó yí gbogbo nǹkan padà. Ọ̀kan lára àwọn ìyípadà ìtàn tó tóbi jùlọ nínú Bíbélì ni ìtàn Kérésìmesì. Ní ọjọ́ márùn-ún tó ń bọ̀, a máa ṣàwárí bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan yìí ṣe yí ayé padà àti bí ó ṣe lè yí ayé rẹ padà lónìí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọ̀wọ́ lọ sí www.life.church