Ohun Gbogbo Dọ̀tunÀpẹrẹ
Ohun kan tó jẹ́ ìwúrí fún mi nípa ṣíṣe àṣàrò aládáṣe nínú Kọ́ríńtì kejì ni wípé, Pọ́ọ̀lù kìí sá fún àwọn ìbárẹ́ tí kò rọrùn. Láti tán ìmọ́lẹ̀ sì èyí, àwọn aráa Kọ́ríńtì ní ǹkan mélòó kan tí wọ́n bá Pọ́ọ̀lù fà, àìlè yọjú sí wọn nígbà tóní ohun ńbọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí Pọ́ọ̀lù tó bẹ̀rẹ̀ síní ṣe alààyè àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀, ó kọ́kọ́ rán wọn létí ìfẹ́ tí òhun ní sí wọn.
Àwọn ìjọ kòní ìdáhùn tó dára fún Pọ́ọ̀lù nínú ìwé Kọ́ríńtì Kínní. Olùrànlọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́-ìránṣẹ́, ìyẹn Tímótì, ti ṣe àbẹ̀wò sí ìjọ ní Kọ́ríńtì lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù fi ìwé náà ránṣẹ́ sí wọn, lẹ́yìn èyí ló wá jábọ̀ gbogbo kùdìẹ̀-kudie to ṣe àkíyèsí rẹ̀ nínú ìjọ náà—àwọn ọ̀rọ̀ to nííṣe pẹ̀lú ìhùwàsí, ìgbàgbọ́ tí kò gbilẹ̀ mọ́, àti ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Fún ìdí èyí ni Pọ́ọ̀lù fi gbéra tósì lọ sí Kọ́ríńtì láti Éfésù láti mú ohun gbogbo bòsípò fúnra rẹ̀, èyí tí ó mẹ́nubà nínú 2 Corinthians 2:1-2 gẹ́gẹ́ bíi “àbẹ̀wò oníbànújẹ́.”
Ẹsẹ̀ Bíbélì ti òní fihàn wípé àwọn aráa Kọ́ríńtì fẹ́ mọ ìdí tí Pọ́ọ̀lù kò fi yọjú sí wọn. Lótìítọ́ ni ó fẹ́ràn wọn tọkàntọkàn, àwọn alátakò kan gbìmọ̀pọ̀ láti fa ìdàrúdàpọ̀ nínú ìjọ Kọ́ríńtì, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti fi ìdí àìṣòótọ́ múlẹ̀ nípa ìfọkàntán tí Pọ́ọ̀lù fihàn. Tí a bá gbà mí láyè láti dájọ́, ní ìkòríta yìí, màá ní ǹkan tó burú jọjọ ni èyí tí wọ́n ṣe. Nkò fẹ́ẹ tí a bá ṣìmí gbọ́, pàápàá lẹ́yìn àwọn àkókò tí mo ti ṣe làálàá, fi arami jìn, tí moti kúrú, tàbí ga láti tẹ́ ẹlòmíràn lọ́rùn. Kìí ṣe pé mo ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé gbogbo ìgbà ni irú ǹkan báyìí máa ń ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n tóbá ṣẹlẹ̀ ìbéèrè méjì ló máa ń jà fita-fita lọ́kàn mi: 1. Ṣé mo jẹ́rìí Olúwa pẹ̀lú ìrísí àwọn ènìyàn nípa mi, tí mo sì wà láìní ìdààmú ọkàn níwájú rẹ̀ (v. 12)? 2. Ǹjẹ́ mo lè tẹ̀síwájú láti máa fẹ́ràn àwọn tó fẹ̀sùn kànmi?
Kìí ṣe ìgbóríyìn tí ẹnìkan bá sọ fún ọ wípé ò ńṣe àwáwí nípa ohun kan. A lè níi lérò wípé èsì tí ó dára jù lákòókò náà ni láti dákẹ́ láìṣe alààyè kankan. (Ìwé Òwe 9:8 ní kía má dá ẹnití ń gànwá lẹ́kun.) Ṣùgbọ́n nígbà míràn ṣíṣe alààyè ìdí tí afi hùwà bákan ṣe pàtàkì, ó sì máa ń di òkun ìbárẹ́ mú kó ba má jàá. Báwo ni ìwọ yóò wá timọ àkókò tó dára láti gbéjà aráa rẹ tàbí láti dẹ́kun ìgbèjà? Àyẹ̀wò kan tí mo máa fi ń mọ̀ ní èyí: Tí ìgbèjà araà mi yìí bá ṣẹ́yọ lára 'kẹ́nu-mákànmí' tí ó sì ní àmì ìgbéraga, ìbínú, ìfòyà, tàbí ìwà mo-dárajùọ́-lọ́, ẹran-ara ló ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n, tí ìgbèjà araà mi yìí bání àmìi ìfẹ́ sí ẹni tí mò ń gbìyànjú láti ṣe alààyè fún yìí tósì nííṣe pẹ̀lú títan ìmọ́lẹ̀ sì ǹkan tóbá rújú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ìrẹ̀lẹ̀, ìkáàńú, àti ìṣòòótọ́, Ẹ̀mí ló n darí. Ṣe àkíyèsí wípé ìgbèjà ara rẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ńṣe jálẹ̀ ìwé tí à ń gbéyẹ̀wò yìí, kìí ṣe láti dáàbòbo ara rẹ̀ lásán, ṣùgbọ́n nítorí ìfẹ́ tíó ní fún àwọn aráa Kọ́ríńtì.
Kíni ìhùwàsí rẹ ní kété tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn ọ́ tàbí tí a ṣì ọ́ gbọ́?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ní ìrìn ajó lo sí Ìwé Kọ́ríńtì, Gbogbo ohun jé tuntun sàyèwò ẹ̀kọ́ ìsìn Póòlù tí ìgbàgbọ́ onígboyà ní ayé yìí tí Olórun pé wa láti nígboyà. Kelly Minter ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé ìrìn Kristeni dá bíi pé o yàtò sí ìtèsí àdánidá, àmó fí hàn dájú pé o dára jú ayérayé àti àìlópin. Ní ètò kíkà olójó márùn-ún, yóò sàyèwò àwon awuyewuye bí: bí won se yanjù àwon ìbasépò tó sòro, gbigbéklè Olórun, pèlú orúko rere rè, mimú ìdúró ìdánimọ̀ rè nínú Kristi, lilóye ète ìjìyà àti ìpèsè Olórun nínú è, àti báwo ní a se lè jé ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere nínú ayé.
More