Ohun Gbogbo Dọ̀tunÀpẹrẹ
Ìgbésí-ayé Kristẹni jẹ́ èyí tí ń yani lẹ́nu lọ́pọ̀lọpọ̀. Ohun tí Jésù mú ní òkúnkúndùn jẹ́ ìdákejì èyí tí àwa ènìyàn ń lépa.
Kọ́ríńtì Kejì jẹ́ ìwé tó kún fún àwọn ǹkan to jẹ́ ìdàkejì ara wọn. Ó jẹ́ ìwé tí a fi ṣọwọ́ nípa ìgbàgbọ́ tó nííṣe pẹ̀lú gbígbé gbogbo ìrètí wá lé Ọlọ́run, ní àìgbàgbé wípé lápá kan láti pinnu bí a ó ti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ipá àti ìgbéraga. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ síwa èyí tó bu omi tútù síwa lọ́kàn bí ó ti ṣe ìkéde ìtúsílẹ̀ wa kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ Jésù wá sí ayé, léni to fọn ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ wa rù. Èyí tí Pọ́ọ̀lù pè ní ìlàjà.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gúnlẹ̀ ni ọdún A.D. 50 ólé, Kọ́ríńtì jẹ́ ìlú tó lé téńté nípa ìdàgbàsókè. Ó jẹ́ ìkòríta ọrọ̀-ajé ní ìhà gúsù ilẹ̀ Gíríìsì, Kọ́ríńtì rí tajéṣe, ọrọ̀ wà, àti wípé ó jinlẹ̀ nínú àṣà Róòmù pẹ̀lú Gíríìkì. Ìlú ìṣẹ̀ǹbáyé Kọ́ríńtì ní gbogbo àmúyẹ tí àwọn ìlú ńlá máa ń ní. Ṣùgbọ́n bí a ti mọ̀: níní ohun gbogbo tí a bá nọwọ́sí kò jásí wípé ohun tí a fẹ́ laó rí gbà.
Bí àṣà Kọ́ríńtì tí jinlẹ̀ yìí ní àléébù tirẹ̀, bí ó ti ń ṣẹlẹ̀ lónìí ni àwọn ìlú ìgbàlódé. Iṣẹ́ẹ gbélépawó, òwò-ẹrú, àti oríṣiríṣi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ìbálòpọ̀ ni àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn òrìṣà wá ní gbogbo ìlú.
Ìwé tí afi ṣọwọ́ yìí jẹ́ ìwúrí fún mi nítorí tí ìjọ Ọlọ́run bálè dúró ní irú àkókò yìí, ó lè ní ipa l'àwọn ibi tí èmi àtìrẹ ń gbé. Lótìítọ́ ni mo máa ń rò ó wípé àṣìlò, ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà, àìní ìdájọ́ jinlẹ̀. Ṣùgbọ́n, tí ìhìnrere Jésù bálè yí àwọn aṣẹ́wó, olówóogbó, abọ̀rìṣà, àti àwọn adarí sínágọ́gù ní Kọ́ríńtì padà, ó dájú wípé ìhìnrere ti Jésù Kristì yóò yí àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ìlú wá lónìí padà. Lótìítọ́ èrò náà máa ń wá sími lọ́kàn wípé ilé ìjọsìn nìkan láti lè rí àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ní àwọn ènìyàn tó gbé àsíá Rẹ̀ ró ní Kọ́ríńtì. Gẹ́lẹ́ bó ti ní èmi àti ìwọ ní àárín àwọn ènìyàn tí a ń gbé. Kọ́ríńtì Kejì ránwa létí wípé ìjọ Ọlọ́run ń tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ nínú òkùnkùn dípò nínú ibi tí ìtànná tiwà tẹ́lẹ̀.
Bí o ti ń ka Kọ́ríńtì kejì, gbìyànjú láti ṣe àwárí àwọn ǹkan tóní ìdàkejì. Sì ṣe àkíyèsí ìfẹ́ tí kìíyẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní fún àwọn aráa Kọ́ríńtì. Bí o ti ń gbé àwọn ǹkan tó yàtọ̀ gedegbe wọ̀nyí yẹ̀wò, má ṣe gbàgbé wípé ati ró ọ lágbára láti gbé ìgbé-ayé tó yàtọ̀ gedegbe—láti ìgbà tí Jésù ti kú tósì jíǹde—ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, ọ̀tun sì tidé. Tí a bá ṣe àgbéyèwò rẹ̀, gbogbo ǹkan ni ohun titun àti ògbó fi yàtọ̀ síra wọn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ní ìrìn ajó lo sí Ìwé Kọ́ríńtì, Gbogbo ohun jé tuntun sàyèwò ẹ̀kọ́ ìsìn Póòlù tí ìgbàgbọ́ onígboyà ní ayé yìí tí Olórun pé wa láti nígboyà. Kelly Minter ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé ìrìn Kristeni dá bíi pé o yàtò sí ìtèsí àdánidá, àmó fí hàn dájú pé o dára jú ayérayé àti àìlópin. Ní ètò kíkà olójó márùn-ún, yóò sàyèwò àwon awuyewuye bí: bí won se yanjù àwon ìbasépò tó sòro, gbigbéklè Olórun, pèlú orúko rere rè, mimú ìdúró ìdánimọ̀ rè nínú Kristi, lilóye ète ìjìyà àti ìpèsè Olórun nínú è, àti báwo ní a se lè jé ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere nínú ayé.
More