Ìgbẹ́kẹ̀lé, Isé àsekára, Ati ÌsimiÀpẹrẹ

Trust, Hustle, And Rest

Ọjọ́ 4 nínú 4

Ìsinmi

Bí a se ríi ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn, gbígbẹ́kẹ̀lé jẹ́ ohun tí ó sòro ṣùgbọ́n ójẹ́ ohun tí yíò jé kí á rí wípé kìí se tiwa láti pinnu èsìn iṣẹ́ waa - Ọlọrun níí má ṣe é. Ní kété tí a bá ti gba ẹsẹ kìíní tí ó se pàtàkì yì, ó tọ́ kí á siṣẹ́ àsekára, láti lo tálẹnti tí Ọlọ́run fún wa láti ṣe iṣẹ́ tí a pè wá ṣí. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe fẹ́ mọ̀ bóyá a ń gbẹ́kẹ̀lé àti bóyá à ń siṣẹ́ àsekára? Ó rọrùn láti dá iṣẹ́ àsekára mọ̀. Ó fihàn nínú àwọn ímeèlì wa, àwọn ìlànà tí a ti kọ sílẹ fún iṣẹ́ wa, àti èrò wa tí ó kún. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè mọ̀ bóyá a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nítòótó, tàbí ara wa, láti gbà èsìn iṣẹ́?Ohun tí yíò jé kí á mọ̀ ní bóyá a wà ní ìsinmi tàbí a kò ṣí.

Ìsinmi jẹ́ ohun tí gbogbo wa nílò. Ìtumò Ìsinmi ju kí á kàn lo àkókò kúrò ní ilé iṣẹ́. Pẹ̀lú bí a kò se dá ìyàtọ̀ mọ̀ nínú ibùgbée wa àti ilé iṣẹ́, ó má ńsòro láti ya ara wa kúrò nínú kí á fẹ́ sáà má siṣẹ́. Kódà tí a bá wà nínú ilé wa, a sì ń wo ímeèlì, Instagram, akọjọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo ìgbà ni a má ńsiṣẹ́. Aà kíí lè mú ara dúró láì ṣe nkankan.

Báwo ni a ṣe lè rí ìsinmi tí gbogbo wa ń là kàkà láti rí?St. Augustine fún wa ní èsìn: "ọkàn wa ń se àwáàrí, títí tí yíò fi rí ìsinmi nínú rẹ̀." A ó máa se àwáàrí títí tí a ó fi rí ìsinmi nínú Ọlọrun nìkan. Èyí túmọ sí wípé bí a se ń siṣẹ́ àsekára, a gbọdọ̀ kọ́kọ́ gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run enití, ó jẹ́ olótìítọ́ tí ó ń pèsè fún àwọn ènìyàn tirẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Tí a bá gbẹ́kẹ̀lé ìwà Ọlọrun, tí a sì lo àwọn ẹ̀bùn tí ó fún wa dáadáa, a lè sinmi pẹ̀lú ìdájú wípé èsìn iṣẹ́ wa wà ní ọwọ́ rẹ ẹ̀, ohun gbogbo wà ní àkóso rẹ ẹ̀ ósì ń se gbogbo ohunkóhun fún dídára tiwa. Bí Sólómọ́nì ti sọ nínú Ìwé Òwe 16:33, "A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa."

Èyí ni ọ̀nà kan ṣoṣo sí ìsìnmi tòótó tí ó pé ní gbogbo ọ̀nà wa, ní ìseṣí, èrò, àti nípa ẹ̀mí, ó sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kí á jọ̀wọ́ ara wa sí ìpinnu Ọlọ́run nípa Ọjọ́ Ìsinmi. Bí Olùṣọ àgùtàn Timothy Keller se sọ: "Óyẹ kí á rò nípa Ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìgbẹkẹ̀lé. Ọlọ́run yan Ọjọ́ ìsinmi láti ràn wá létí wípé òhun ń siṣẹ́ ó sì ń sinmi. Síṣe Ọjọ́ ìsinmi jẹ́ ọ̀nà òtítọ́ láti ràn wá létí pé ayé ò sí ní ìkáwọ́ wa, kìí sì ṣe àwa ni à ń pèsè fún ìdílé wa, kìí ṣìí ṣe àwa ni à ń jẹ́ kí iṣẹ́ wa tẹ ṣíwájú"

Kíni ìdí tí ó ṣẹ pàtàkì kí á gba aáwọ̀ tí ó wà nínú ìgbẹkẹ̀lé àti iṣẹ́ àsekára dáadáa? Nítorí pé lópin ọjọ́, tí a bá gbára lé iṣẹ́ àsekára wa láì gbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, a ńgbìyànjú láti jẹ́ Ọlọ́run tàbí gba ògo rẹ, ọ̀nà méjèèjì yíò jẹ́ kí á maa se àwáàrí láì sinmi. Kristẹni, múra gírí! Àwọn àṣẹ Bíbélì yìí kò lòdì ṣíra wọn. A pè ọ láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹàtikí á siṣẹ́ kárakára. Àti wípé tí a bá gba aáwọ̀ yí, a ó le sinmi dáadáa, nítorí a wà ní àjọse pẹ̀lú ẹni tí ó pè wá.

Bí o bá Gbádùn ètò ẹ̀kọ́ kíkà yìí, ìwọ yíò fẹ́ràn ètò ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mi, tí yíò ràn ọ lọ́wọ́ láti túbọ̀ wo iṣẹ́ rẹ̀ nípaṣẹ ìyìn rere Bèrè níbí lọ́fẹ̀ẹ́ .

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Trust, Hustle, And Rest

Bíbélì pàṣẹ fún wa pé kí a ṣiṣẹ́ karakara, ṣugbọn o tun so fún wa wípé Ọlọrun níí má se àbájáde iṣẹ wa, kìí se àwa. Bí ètò ọlọjọ mérin yìí yíò ṣe fi hàn wá, Kristiani tí o ba n sise gbọdọ gba ibaṣepọ tí o wa nínú kí a gbẹkẹle àti kí a ṣiṣẹ́ karakara láti le rí Ìsinmi tí ọjọ ìsinmi tootọ.

More

A fé láti dúpe lówó Jordan Raynor fún ìpèsè ètò yìí. Fún alaye die sí, Jowo lo si: http://www.jordanraynor.com/trust/