Ìgbẹ́kẹ̀lé, Isé àsekára, Ati ÌsimiÀpẹrẹ
Ìgbẹkẹ̀lé, Isẹ́ àsekára, àti Ìsinmi
"Isé àsekára" gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ tí ó gbajúmọ̀ jù ní òwò síse ní òde òní. Àwọn olùdókoòwòShark Tank tẹra mọ́ àwọn alákòṣo ìsòwò wípé kí wọ́n sisẹ́ àsekára sí láti ta ọjà. Ó jọ wípé gbogbo àwọ́n ènìyàn ṣisẹ́ kékèké lẹ́gbẹ̀ pẹ̀lú isẹ́ òòjọ́ wọn. Ṣùgbọ́n kíni Bíbélì ní láti sọ nípa isẹ́ àṣekára? Lẹ́gbẹ̀ kán Ìwé Mímọ́ fọwọ́sí isẹ́ àsekára. Kólósè 3:23 pàsẹ wípé "Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn." Ṣùgbọ́n bí Krìstíanì se ń fọwọ́sí isẹ́ àsekára, a gbọdọ̀ mọ̀ bí a ó ṣe dá ẹ̀dọ̀fù tí ó wà nínú isẹ́ àsekára pọ̀ mọ́ gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run kí á lè rí ìsinmin nítòótó.
Ìwé Jóṣúà 6 pèsè àpẹrẹ fún ohun bí ó se yẹ kí á gba ẹ̀dọ̀fù yì dáradára. Bí Jóṣúà ṣe ń darí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì lọ sí ilẹ̀ ìlérí, wọ́n dojú kọ ìsòro kan: Odi Jẹ́ríchò tíó dàbí èyí tí wọn ò le là kọjá. Bí Ìwé Joshua 6:2 se kọọ, "Olúwa sọ fún Jóṣúà pé, "Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́," sùgbọ́n kàkà kí Ọlọ́run fún Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ní agbára tí ó ju agbára lọ láti gba Jẹ́ríchò pẹ̀lú ipá wọn, ohun tí Ọlọ́run béèrè ni wípé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé òhun. Ọlọ́run sọ fún Jósúà kí ó darí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kí wọ́n rìn yíká odi Jẹ́ríchò ní ọjọ́ méje, tí ó parí pẹ̀lú igbe ńlá yíká Odi ìlú yìí.
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú gbogbo àwọn ìtàn àkọọ́lẹ̀, Ọlọ́run yàn láti lo "àwọn ohun nkan òmùgọ̀ ayé láti dójúti àwọn ọlọgbọ́n." Kàkà kí Jósúà àti àwọn ọmọ Ísráẹ́lì borí ogun yìí pẹ̀lú agbára wọn, Ọlọ́run ṣe ìlànà tí ó mú dájú wípé Òhun Ọlọ́run nìkan ni yíò gba gbogbo ògo. Kí á tó fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ní ìsẹ́gun, Ọlọ́run sọ fún wọn wípé kí wọn gbẹ́kẹ̀lé òhun láti pèsè fún wọn. Láì sẹ́jú, Jósúà ṣe gẹ́gẹ́bí Ọlọ́run ti bèèrè. Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì gbẹ́kẹ̀lé ìlànà Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, wọ́n sisẹ́ àṣekára: wọ́n ńrìn yíká, wọn fọn fèrè, wọ́n kígbe títí tí Odi Jẹ́ríchò fi subú.
Kìí ṣe ìrìn, Igbe, àti isẹ́ àṣekára àwọ́n ọmọ Ísráẹ́lì ni ó mú Odi Jẹ́ríchò wálẹ̀. Ọlọ́run ni ó sé. Mo ṣì rò pé èyí ni ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì àti àwa rí. Isẹ́ àṣekára wa dára! Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ wípé isẹ́ àṣekára wa ni ó pèṣe èsìn isẹ́ wa yíò rí gẹ́gẹ́bí pé kí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì gbàgbọ́ wípé igbe tí àwọn ké ni ó mú odi Jẹ́ríchò subú.
Bí Jósúà àti àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ti fi hàn wá, a kò gbodọ̀ wá láti sàwárí ẹ̀dọ̀fù tíò wà láárìn gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti isẹ́ àṣekára; dípò rẹ̀ óyẹ kí á fàá mọ́ra ni. Àwọn èrò yìí ò lòdì ṣíra wọn, ó yẹ kí á dà wọ́n pọ̀ ni. Ṣùgbọ́n bí Sólómọ́nì ṣe sọ ní Ìwé Òwe 16, Ìgbẹkẹ̀le àti iṣẹ̀ àṣekára tẹ̀lé ara wọn ní ọ̀nà tí yíò buyì fún Ọlọ́run tí yíò ṣì fún wa ní ìsinmi nítòótọ́. Ẹṣe yìí ni a ó máa wò ní ọjọ́ mẹ́ta síwájú.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bíbélì pàṣẹ fún wa pé kí a ṣiṣẹ́ karakara, ṣugbọn o tun so fún wa wípé Ọlọrun níí má se àbájáde iṣẹ wa, kìí se àwa. Bí ètò ọlọjọ mérin yìí yíò ṣe fi hàn wá, Kristiani tí o ba n sise gbọdọ gba ibaṣepọ tí o wa nínú kí a gbẹkẹle àti kí a ṣiṣẹ́ karakara láti le rí Ìsinmi tí ọjọ ìsinmi tootọ.
More