Ìgbẹ́kẹ̀lé, Isé àsekára, Ati ÌsimiÀpẹrẹ

Trust, Hustle, And Rest

Ọjọ́ 3 nínú 4

Isẹ́ Àṣekára

Ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn, a ti ńgbé ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ wa yẹ̀wò, bí àwa krìstíánì yíò ṣe gba aáwọ̀ tí ó wà nínúu iṣẹ wa mọ́ra, láàrín gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun àti Isẹ́ àṣekára láti jẹ́ kí gbogbo nkan lọ déédé nínú iṣẹ tí a Yàn láàyò. Bí a ṣe ríi lánàń, Sólómọ́nì se ètò ní ṣísẹ̀ ntẹle tí yíò tọ́ èrò wa nípa ètò yí sọnà, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kí á gbé isẹ́ wa lé Ọlọ́run lọwọ (Ìwé Òwe 16:3). Ní ẹsẹ kẹṣán orí yìí, Sólómọ́nì rọ̀ wá wípé kí á ṣiṣẹ kára, ó sọ wípé, Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n OlúWA ní í pinnu ìgbéṣẹ̀ rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run pè wá pé kí á gbẹ́kẹ̀ lé òhun, ṣùgbọ́n ó fún wa ní òye láti gbèrò àti se. Kété tí a bá ti gbé isẹ́ wa lé lọ́wọ́, a pè wá láti ṣisẹ́ kára, kí á sisẹ́ "pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, gẹ́gẹ́bí isẹ́ fún Ọlọ́run" ( Kólósè 3:23).

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwa Krìṣtẹnì má tẹra mọ́ gbígbẹ́kẹ̀lé nìkan tàbí isẹ́ àṣekára nìkan. Àwọn Kriṣtẹni a má lo ọ̀rọ̀ yìí "dídúró de Ọlúwa" bíi agbára láti ṣe ọ̀lẹ, àwọn míràn sisẹ́ kárakára títí yíò fi kóbá ìlera wọn, ní ara, ẹ̀mí àti èrò. Ẹwà tí ó wà nínú Ìwé Òwe 16:9 ni wípé, ó ṣe ìbùkún fún gbígba aáwọ̀ tí ó wà nínú òótọ́ méjì yìí. Bẹ́ẹ̀ni, a gbọ́dọ̀ rí wípé, "Ọlọ́run ní ṣe ìpinnu ìgbéṣẹ̀ waa," ṣùgbọ́n o yẹ, ó sì dára wípé "kí á gbèrò ìgbéṣẹ̀ wa," láti ṣe gbogbo ohun tí a fẹ́ se.

Iṣẹ́ wa jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí a fi ń fẹ́ràn ọmọnìkejì wa àti siṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ayé. Rántí wípé, iṣẹ́ ti wà ṣáájú ìṣubú nínú ọgbà Ídẹ́nì. Iṣẹ́ jẹ́ ohun tí ó dára tí Ọlọ́run pèsè láti fi ìwà rẹ hàn àti pé kí á lè fẹ́ràn, kí á siṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èyí, ìlépa fún iṣẹ́ wa tí ó ntì wá láti siṣẹ́ kárakára le jẹ́ ohun tí ódára. Ṣùgbọ́n bí a ó se ríi ní ọ̀la tí ó kásẹ̀ ètò yí nílẹ̀, bí iṣẹ́ àsekára wa bá wà pẹ̀lú gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ni a ó tòó ní ìsinmi nítòótó

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Trust, Hustle, And Rest

Bíbélì pàṣẹ fún wa pé kí a ṣiṣẹ́ karakara, ṣugbọn o tun so fún wa wípé Ọlọrun níí má se àbájáde iṣẹ wa, kìí se àwa. Bí ètò ọlọjọ mérin yìí yíò ṣe fi hàn wá, Kristiani tí o ba n sise gbọdọ gba ibaṣepọ tí o wa nínú kí a gbẹkẹle àti kí a ṣiṣẹ́ karakara láti le rí Ìsinmi tí ọjọ ìsinmi tootọ.

More

A fé láti dúpe lówó Jordan Raynor fún ìpèsè ètò yìí. Fún alaye die sí, Jowo lo si: http://www.jordanraynor.com/trust/