Àyànfẹ́ - Níní Òye Obìnrin Nínú KrístìÀpẹrẹ
Kò Sí Ààlà Nínú Kristi
Nínú ètò áti aṣẹ̀dá tí Ọlọ́run ṣe fún aráyé, Ó dá akọ àti abo, ó sì fi wọ́n sí ipò ọlá àṣẹ tó ga jù lọ tí ẹ̀dá èyíkéyìí lè wà - ínú Kristi! Obìnrin náà kì í ṣe ohun tí wọ́n kàn ṣàgbéyẹ̀wò lẹ́yìn náà tàbí àfikún àmọ́ ó jẹ́ ara ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tó dá àgbáyé.
"Nítorí náà, Ọlọ́run dá èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá a; akọ àti abo ni Ó dá wọn." - Gẹ́nẹ́sísì 1:27 YCB
Ọlọ́run dá Ádámù nínú Gẹ́nẹ́sísì 2, a sì mú Éfà láti ínú ẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ìṣubú ènìyàn wá ṣẹlẹ̀. Àmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú kírísítì ni a ti rà padà, kì í ṣe ẹni tí wọ́n ti dè mọ́ ìwà Ádámù. Nípasẹ̀ ikú, ìsìnkú, àti àjíǹde Kristi, wọ́n ti di ara ìdílé ọlọ́run.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, a jíròrò ìdánimọ̀ wà nínú kristi. Irú ẹni tá a jẹ́ nínú Kristi yìí ń mú àwọn àbá tuntun wá, àwọn àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ ara ìdílé Ọlọ́run. A kò ní láti dúró láti gbádùn àwọn àǹfààní wọ̀nyí, gbogbo wọn ni a lè rí gbà nínú kírísítì ní gbàrà tí a bá ti gbàgbọ́.
Nínú ìwé Númérì 27:5-10, àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi béèrè ohun kan tó dà bíi pé kò ṣeé ronú kàn. Àjogúnbá tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọkùnrin ajogún ní àṣà ìbílẹ̀ jẹ́ fún wọn ní ipò ṣùgbọ́n àlàfo wọn kan ṣoṣo ni pé obìnrin ni wọ́n.
Ṣùgbọ́n ohun tí Òfin Mósè yà sọ́tọ̀, Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run dá àfikún fún un. Nípasẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àfikún yìí wá di ìlànà fún àwọn obìnrin mìíràn nínú àṣà yẹn. Ọlọ́run fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pèsè fún àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì ó sì ti fún yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní nínú Krísítì.
Gbogbo ohun tí o nílò fún ìwàláàyè àti ìfọkànsin Ọlọ́run ó ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó nínú Kristi.
Obìnrin Ọ̀wọ́n Nínú Kristi, gbé nínú ìmọ̀lára ẹ̀dá tuntun rẹ.
Ẹ mú kí ẹ̀dá tuntun yín wà láàyè lójú àwọn ipò tí ó le nípa gbígbé pẹ̀lú Ìhìn Rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Kì í ṣe pé ó ń fún wa lókun láti borí àwọn ìṣòro náà nìkan, gbogbo ìbùkún Ọlọ́run fún ìgbésí ayé wa wà nínú rẹ̀.
Bá a ṣe ń parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí, sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹlu agbára lórí ara rẹ
Àwọn Ìpolongo:
- Èmi ni òdodo Ọlọ́run nínú Kristi Jésù
- Èmi ni ẹni tí Olúwa rà padà
- Èmi ni olólùfẹ́ Baba wa ọ̀run
- A ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí
- Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi gan-an ni
- Ọlọ́run ń ràn mí lọ́wọ́ lọ́nà tó lágbára
- >Ọlọ́run pa mí mọ́ ó sì ń dáàbò bò mí
- Àwọn Áńgẹ́lì ń ràn mí lọ́wọ́
- A bù kún mi pátápátá
- A ti dárí jì mí títí láé
- Èmi ni ẹni tí Olúwa mú lára dá
- Mo ní ìlera Ọlọ́run
- Mo ní ojú rere àti ọgbọ́n Ọlọ́run
- Èmi sì jẹ́ aláásìkí,Gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe ló máa ń yọrí sí rere
- Mo ní ìfọwọ́sí ọ̀pọ̀lọpọ̀
- Kò sí ohun tó lòdì sí mi
- Kò sí ohun tí ń kú ní ọwọ́ mi
- Mi ò kì í ṣìnà
- Ohun tó ju ti ẹ̀dá lọ kò ṣàjèjì sí mi.
- Gbogbo nǹkan ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ fún ire mi
- Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi ju Èṣù lọ
- Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ fún mi!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin, a sábà máa ń rí i pé a ní láti ṣe onírúurú nǹkan nínú ìgbésí ayé wa. Àmọ́ ní àárín ìgbòkègbodò yìí, ó ṣe pàtàkì láti rántí irú ẹni tá a jẹ́ nínú ọkàn àyà wa: Àwọn Obìnrin Tí Ọlọ́run Yàn, tàbí Obìnrin Nínú Kristi. Àmì yìí ni ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé wa, bá a ṣe lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i. Darapọ mọ wa fun ọjọ mẹta to n bọ bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìdánimọ̀ yìí ní kíkún sí i!
More