Àyànfẹ́ - Níní Òye Obìnrin Nínú KrístìÀpẹrẹ

Chosen -  Unveiling the Woman in Christ

Ọjọ́ 2 nínú 3

ÀWỌN TÍ WỌ́N YÀN FÚN ÒGO RẸ̀

"Àní, gẹ́gẹ́ [ìfẹ́ Rẹ̀] bí o ti yàn wá [ní ti gidi Òun ló yàn wá yà. fún ara rẹ̀ bí tirẹ̀]nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ (a yà sí mímọ́, a sì yà sọ́tọ̀ fún Un) àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀, àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀,nínú ìfẹ́". - Éfésù 1:4 (AMPC)

Ọlọ́run kì í pa ohun tó ti kọjá tì, ó máa ń yí i pa dà!

Ó ti rẹ̀ Ruth.

Wọ́n bí i sí ínú ìran tí àwọn ègún dà láàmú àti ìsìn ọlọ́run tí kì í dárí jini, Rúùtù rí i pé ipò tí óun wà ti di ẹrù ìnira fún òun. Ìgbésí ayé ìdílé rẹ̀ kò fara rọ rárá lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀, ó yàn láti tẹ̀lé ìyá ọkọ rẹ̀, Naomi, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti gbọ́ nípa ọlọ́run tí ń dárí jini.

Ìtàn Rúùtù, bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin inú Bíbélì, tọ́ka sí ìràpadà táa rí nínú ìṣípayá Jésù. Àwọn ìtàn wọn ṣe pàtàkì, kì í ṣe nítorí pé wọ́n jẹ́ oníwà mímọ́- ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n tọ́ka sí ìyípadà tí jésù mú wá nípasẹ̀ ìgbàlà.

Ráhábù náà ti rẹ̀wẹ̀sì, ó sì yíjú sí Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó fi ìlú rẹ̀, olódi tí ó dà bíi pé ó ní ààbò sílẹ̀. Bíi tí àwọn obìnrin yìí, láìka ibi tí á ti wá sí, ìyípadà sí Ọlọ́run máa ń yí ìtàn wa padà. Kò ka ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn sí pàǹtí, ó máa sọ ọ́ di ohun kan tó lẹ́wà.

Ọ̀kan lára ohun tó máa ń kó ẹ̀gàn bá àwọn obìnrin ni ìtàn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá nínú ọgbà Édẹ́nì.

Nítorí pé wọ́n tan Éfà jẹ, obìnrin náà ni wọ́n máa ń kà sí ẹni tí ó ń gba nǹkan gbọ́. Àmọ́, a ti mú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run jáde ṣáájú ìṣẹ̀dá.. In Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ọ̀kan lára àwọn ìlérí ìgbàlà ni; wípé irú-ọmọ obìnrin náà yóò fọ́ orí ọ̀tá náà.

Èyí ni ìkéde ìbí Jésù. Ọlọ́run ti yàn láti rà wá padà àti láti mú wa padà bọ̀ sípò, ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ hàn nínú wa nípasẹ̀ bí Jésù ṣe di ènìyàn nínú Màríà.

Bí Ó bá lè fọkàn tán obìnrin náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí ó di ènìyàn, mélòómélòó wá ni ọ̀rọ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀!!

Obìnrin Ọ̀wọ́n, mọ̀ pé a ti yàn ẹ, a sì ti yàn ẹ fún Ògo Rẹ̀! Tẹ́wọ́gba ìdánimọ̀ rẹ nínú Ọlọ́run bí o ti ń lọ nípa ọjọ́ rẹ!

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Chosen -  Unveiling the Woman in Christ

Gẹ́gẹ́ bí obìnrin, a sábà máa ń rí i pé a ní láti ṣe onírúurú nǹkan nínú ìgbésí ayé wa. Àmọ́ ní àárín ìgbòkègbodò yìí, ó ṣe pàtàkì láti rántí irú ẹni tá a jẹ́ nínú ọkàn àyà wa: Àwọn Obìnrin Tí Ọlọ́run Yàn, tàbí Obìnrin Nínú Kristi. Àmì yìí ni ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé wa, bá a ṣe lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i. Darapọ mọ wa fun ọjọ mẹta to n bọ bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìdánimọ̀ yìí ní kíkún sí i!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ The LOGIC Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://thelogicchurch.org/en/