Àyànfẹ́ - Níní Òye Obìnrin Nínú KrístìÀpẹrẹ

Chosen -  Unveiling the Woman in Christ

Ọjọ́ 1 nínú 3

KÌÍ ṢE ÌLÀNÀ NÍKAN

Ó dà bíi pé ó wulẹ̀ jẹ́ ọjọ́ mìíràn ni fún un, àwọn ibi kan náà, àkọsílẹ̀ ohun kan náà láti ṣe.

Àjèjì tí kò tíì rí yìí ló máa yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà títí láé.-kò tíì mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Ìpàdé Jésù pẹ̀lú obìnrin ará Samáríà náà yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ló padà sí ìlú rẹ̀, Ó si ń sọ nípa rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn. Ìyẹn ni agbára Ìhìn Rere!

Ìhìn Rere ń borí àwọn ohun tí ó ń dènà, ó ń mú ìtìjú àti ẹ̀rí ọkàn tó ń dáni lẹ́bi kúrò, ó sì ń dá àwọn onígbàgbọ́ nídè sílẹ̀ láti mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ ní kíkún. Gbogbo ìlú ló gbọ́ nípa bí Jésù ṣe lo àkókò tí ó péye pẹ̀lú obìnrin yìí, fífi agbára tí Ìhìn Rere ní láti yíni padà hàn.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó ń ṣiyèméjì bíi ọ̀pọ̀ lára wa máà ń ṣe, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Ìṣípayá Jésù, ó wá mọ òtítọ́ àdánidá ti Baba wa ọ̀run. Obìnrin nínú Kristi mọ̀ wípé Ọlọ́run dára, láìka ipò tó wà láyìíká rẹ̀ sí. Kò jẹ́ kí ipò tí ó wà mú kí ó máa wo Ọlọ́run lọ́nà tó yàtọ̀. Kò bá èrò rẹ̀ tàbí ìlànà ẹ̀sìn rẹ̀ mu, ó mọ̀ pé inú kírísítì ni ọlọ́run ti fara hàn.

Màríà, arábìnrin Lásárù àti Màtá lóye òtítọ́ yìí dáadáa. Àwọn tí ó ń ṣàkóso àṣà àti ìlànà lákòókò yẹn á bínú gan-an láti rí obìnrin kan tí ó jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù, tí ó ń fetí sílẹ̀, tí ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ bíi ti ọmọ ẹ̀yìn.Ní ti gidi, Màtá retí pé kí Màríà ṣe ju bó ṣe yẹ lọ nígbà tí ó ń gbàlejò nílé wọn. Àmọ́, Mary yan ohun kan tí gbogbo wa nílò - Kristi fúnra Rẹ̀ (Lúùkù 10:42).

Kì í ṣe pé a nílò Kristi láti dáhùn àdúrà wa nìkan ni. A nílò rẹ̀ nítorí pé ẹni tí a jẹ́ wá látinú ìfihàn ẹni tí Òun jẹ́. A gba idanimọ wa gẹgẹbi Ọmọ Ọlọ́run nipasẹ iṣẹ́ ìràpadà Rẹ̀ lórí Àgbélébùú.

Láìka gbogbo èyí sí, Jésù mọ̀ọ́mọ̀ gba Samáríà kọjá nínú Jòhánù 4:4. Ohun tó dà bí ọjọ́ kan lásán ó wá dà bí ẹni pé ohun àrà ọ̀tọ̀ ni, nítorí pé ọlọ́run ló ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìbòjú, n ṣètò ohun kan tí ó dára. Nípa gbígbọ́ Ìhìn Rere nípasẹ̀ Jésù,obìnrin ará samáríà náà yí padà pátápátá. A ṣí ẹni tó jẹ́ gan-an payá gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run, tí a yàn, tí a sì fẹ́ràn rẹ̀ gan-an bíi tàwọn júù ìgbà ayé rẹ̀. Pẹ̀lú idanimọ tuntun, ó mú kí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin púpọ̀ sí i mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ nínú Kristi.

Bó ti wù kí ìtàn rẹ ṣe bẹ̀rẹ̀

A ti yàn ẹ̀, a sì ti fìdí ẹ múlẹ̀ nínú Kristi

Má ṣe tẹ̀ lé ìlànà

O ti di ẹni tuntun, o ti ní àwọn àǹfààní tuntun àti ogún tuntun; gbogbo rẹ̀ ló wà nínú Kristi

Ṣi máa dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ àti ìmọ̀ Jésù Olúwa wa!

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Chosen -  Unveiling the Woman in Christ

Gẹ́gẹ́ bí obìnrin, a sábà máa ń rí i pé a ní láti ṣe onírúurú nǹkan nínú ìgbésí ayé wa. Àmọ́ ní àárín ìgbòkègbodò yìí, ó ṣe pàtàkì láti rántí irú ẹni tá a jẹ́ nínú ọkàn àyà wa: Àwọn Obìnrin Tí Ọlọ́run Yàn, tàbí Obìnrin Nínú Kristi. Àmì yìí ni ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé wa, bá a ṣe lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i. Darapọ mọ wa fun ọjọ mẹta to n bọ bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìdánimọ̀ yìí ní kíkún sí i!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ The LOGIC Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://thelogicchurch.org/en/