Àwọn Irúgbìn: Kíni àti Ìdí Àpẹrẹ

Seeds: What and Why

Ọjọ́ 4 nínú 4

Day 4- ÀWỌN IRÚGBÌN ÌJỌBA ỌLỌ́RUN NÁÀ

Nítorí náà, a túnmise nítorí Jésù, àti pé ìyípadà tí ó dé bá mi bí ojúṣe mi ni láti máà fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ènìyàn. Ìyẹn dún létí, ṣùgbọ́n ńje nnkan míràn tún wà pẹ̀lú rẹ?

(Máàkù 4:30-32, [NLT])

"Jésù sọ wípé, “Báwo ni à bá ṣe ṣe àlàyé ìjọba Ọlọ́run? Ó dàbí wóró musitadi kan tí a gbìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, ṣugbọn nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà, ó wá tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, ó ní ẹ̀ka ńláńlá, àwọn ẹyẹ wá ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sábẹ́ òjìji rẹ̀.” (Máàkù 4:30-32, [NLT]).

Jésù ni musitadi náà tí a gbìn sínú ilẹ̀; Ó wà bí Oníwà tútù a sì fi ojú tẹ́mbẹ́lú Rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, nnkan ti ó hú jáde nínú Rẹ̀ tóbi jú ohunkóhun tí ó síwájú Rẹ̀ nínú ọgbà náà, Àgbáyé! Nísinsìnyí, kini ìjọba Ọlọ́run ti Ó ń ṣe àlàyé rẹ yí?

(Máàkù 4:3-9, [NLT])

“Ẹ fi etí sílẹ̀! Ọkunrin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí òkúta tí erùpẹ̀ díẹ̀ bò lórí. Láìpẹ́, wọ́n yọ sókè nítorí erùpẹ̀ ibẹ̀ kò jinlẹ̀. Nígbà tí oòrùn mú, ó jó wọn pa, nítorí wọn kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; wọ́n bá kú. Irúgbìn mìíràn bọ́ sí orí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí ẹ̀gún dàgbà, ó fún wọn pa, nítorí náà wọn kò so èso. Síbẹ̀ irúgbìn mìíràn bọ́ sí ilẹ̀ tí ó dára, wọ́n yọ sókè, wọ́n ń dàgbà, wọ́n sì ń so èso, òmíràn ọgbọ̀n, òmíràn ọgọta, òmíràn ọgọrun-un!" Lẹ́yìn náà Ó sọ pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!” (Máàkù 4:3-11, [NLT]).

Lẹyin náà, Nígbà tí ó ku òun nìkan, àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila bèèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó fi ń sọ̀rọ̀. (Máàkù 4:10, [NLT]).

Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn bí òwe bí òwe ni fún àwọn ẹlòmíràn tí ó wà lóde".(Máàkù 4:11, [NLT]).

(Mátíù 28:18-20, [NLT])

"Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé. Nítorí náà kí ẹ lọ sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn mi; kí ẹ máa ṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọ ati ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn túntún wọ̀nyí láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”(Mátíù 28:18-20, [NLT]).

Àwa náà ni iṣẹ apinfunni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fúnra Rẹ̀. Bákan náà ni ó ṣe rí nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, láti ṣe ìtọ́jú àwọn irúgbìn kí ó sì kún orílẹ̀ àgbáyé, kí ì ṣe pẹ̀lú irúgbìn àbáláyé, ṣùgbọ́n tí Ẹ̀mí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:11-12, [NLT])! A ti fi àṣẹ fún wa láti lọ gẹ́gẹ́ bí àwọn àgbẹ̀ àti láti gbìn irúgbìn Ọ̀rọ̀ náà, ìròyìn rere tí Ìhìnrere náà (Mátíù 28:18-20,[NLT]! A kò fi àṣẹ fún wa láti wá ilẹ̀ tí ó dára nìkan láti gbìn Ọ̀rọ̀ náà sì, ṣùgbọ́n sì inú GBOGBO ilẹ̀ nípa ìgbìyànjú láti fún gbogbo ènìyàn ní ànfàní láti gba irúgbìn náà àti láti mú ìkórè jáde nínú wọn. (Mátíù 28:18-20, [NLT]).

(Ìfihàn 14:14-15, [NLT])

"Lẹ́yìn náà mó rí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ẹnikan jókó tí ó "dàbí Ọmọ ènìyàn". Ó ní adé wúrà ni orí Rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ Rẹ̀. (Ìfihàn 14:14, [NLT]). "Lẹ́yìn èyí ni Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.” (Ìfihàn 14:15, [NLT]).”

Ọjọ́ kan wà nígbàtí iṣẹ́ ọkọ, gbíngbìn irúgbìn yíò parí tí Jésù yíò wá láti kò ìkórè ìkẹyìn. Èyí yí ni Ìjọba Ọlọ́run, a sì ni iṣẹ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà rẹ. Irúgbìn yẹn ni Jésù, ìkórè sì ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí a mú wá sínú ẹbí yi, tí a ṣe àtúnṣe wọn nípasẹ̀ irúgbìn àìkú

A ti ṣe àtúnṣe wá a sì ti yí wa padà kúrò ní irúgbìn Ọlọ́run, àti pé nísinsìnyí a ní àwọn èròjà kan náà tí Òun náà ni. Ìfarahàn tí ó tóbi julọ nínú èyí ni ìfẹ́, ó sì ní láti ṣiṣẹ́ kan gbogbo agbègbè ìgbésí ayé wa pátápátá. Kíni ìfarahàn ìfẹ́ tí ó tóbi jù tí ó wà níbẹ̀, bíkòṣe láti jẹ́kí ìgbìmọ̀ Ọlọ́run ti o fífún wá kí ó wà sì ìmúṣẹ́, kí a sì fi ìgbésí ayé wa máà ṣe ìtànkálẹ̀ irúgbìn Jésù kí Ìjọba Ọlọ́run lè máà dàgbà sì?

Èyí ni ibi tí ó ti wà, ibi tí ó ńlọ́, àti ìdí tí ó fi wá nihin yí.

Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Seeds: What and Why

Àwọn irúgbìn wà níbi gbogbo. Ọ̀rọ̀ rẹ, owó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti ìwọ alára, je irúgbìn! Báwo làwọn irúgbìn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa? Ẹ jẹ́ kí á wo ohun tí Bíbélì ní láti sọ, kí a sì wá rí bí ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wa láti sún mọ́ Ọlọ́run àti ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Abundant Life Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ kàn sí https://alcky.com