Àwọn Irúgbìn: Kíni àti Ìdí Àpẹrẹ
Day 3-MÓ WÁ LÁTI INÚ IRÚGBÌN TÚNTÚN! ...nítorí náà kíni ṣẹ́lẹ́?
Nítorí náà, ìwọ jẹ́ irúgbìn túntún kan, tí a sọ di òmìnira kúrò nínú àwọn ìdènà irúgbìn àdáyébá tí ó ti inú rẹ jáde àti èyí tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ìṣubú ìṣẹ̀dá tí ó wá pẹ̀lú rẹ. Nísinsìnyí, kíni ohun tí ó yípadà nípa wá nígbàtí eléyìí bá ṣẹ́lẹ́ sì wá?
(1 Pétérù 1:22-23, [AMP])
Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó bá jẹ wípé nípa ìgbọràn yín sí òtítọ́ ẹ tí sọ ara yín di mímọ fún ìfẹ́ àtọkànwá àwọn tí ó gbàgbọ́, [rí wípé eyin] ẹ fẹ́ ara yín láti inú ọkàn wá [ni igba gbogbo láì ni imotara-eni-nikan ń wá nnkan ti o dara julọ fún ara yín], nítorí a ti tún yín bí [ìyẹn ni pé, àtúnbí láti òkè—tí a ti yípadà nípa ẹ̀mí, sọdọ̀tun, tí a sì yá sọ́tọ̀ fún ète Rẹ̀] tí kí ì ṣe irúgbìn tí ó jẹ́ ìdibàjẹ́ ṣùgbọ́n [láti ìyẹn ti ó jẹ́] àìdíbájẹ́ àti Àìkú, ìyẹn ni pé, nípa ìyè àti ayérayé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run" (1Peteru1:22-23, [AMP]).
"Àti pé kíni irúgbìn Àìkú ṣe rí, kíni ó sì yẹ kí a máà fi ojú sọ́nà fún? A rí èyí ní ẹsẹ 22, "...ìfẹ́ atọ́kanwá àwọn onígbàgbọ́ [rí wípé eyin] ni ìfẹ́ ara yín láti inú ọkàn wa [ni igba gbogbo láì ni imotara-eni-nikan ń wá nnkan ti o dara julọ fún ara yín]". A ti fi ìfẹ́ yí sì inú wá nígbàtí a ti di àtúnbí, ṣùgbọ́n ojúṣe wá ní láti jẹ́kí a ṣe àfihàn ìfẹ́ náà kì a má ṣe párun" (Mátíù 5: 15-16, [Amp].
Eléyìí lè dàbí ẹni pé ó rọrùn, ṣùgbọ́n a rí wípé a fi idi rẹ múlẹ̀ jákèjádò inú ìwé mímọ:
(Gálátíà 5:13-14, [NLT])
"Nítorí tí a ti pé yín láti gbé nínú òmìnira, arákùnrin àti arábìnrin mi. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ló òmìnira yín fún ìtẹ́lọ́rùn láti dẹ́ṣẹ̀ sì ara yín. Dípò bẹ́ẹ̀, kí ẹ ló òmìnira yín láti sìn ọmọnìkejì yín nínú ìfẹ́. Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Gálátíà 5:13-14, [NLT]).
(1 Kọ́ríńtì 13:2, [NLT])
"Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan". (1 Kọ́ríńtì 13:2, [NLT]).
Ó jẹ́ òye síwájú sí fún wa, nígbàtí a kàn wo ẹ̀yìn láti rí ibi tí irúgbìn túntún náà tí wá.
(Jòhánù 3:16, [AMP])
"Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé [tó bẹ́ẹ̀] àti ti o níye lórí [púpọ̀], pé Òun [pàápàá] fi [ọmọ kan] Rẹ̀ kan ṣoṣo , pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ tí ó sì gbẹ́kẹ̀le [gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà] kí ó má báà ṣègbé ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun" (Jòhánù 3:16, [AMP]).
ÌFẸ́ jẹ oríṣi irúgbìn tí ó jẹ́
Ronú sì loni lórí kini o túmọ̀ sí láti ṣe àtúnṣe nínú ìfẹ́, ẹsẹ àyọkà ìwé mímọ tí ó tẹ́lé ṣe àtúpálẹ̀ ohun tí ìfẹ́ yẹn jọ́.
Kini a lè fi ṣe àkàwé ìgbé ayé rẹ tí ó bá jẹ àpẹẹrẹ àwọn ìfarahàn ìfẹ́ wọ̀nyí?
(1 Kọ́ríńtì 13:4-7, [NLT])
"Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣàánú. Ìfẹ́ kì í ṣe ìlara tabi lérí asán tabi ìgbéraga tàbí kí ó rínifín
Nípa Ìpèsè yìí
Àwọn irúgbìn wà níbi gbogbo. Ọ̀rọ̀ rẹ, owó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti ìwọ alára, je irúgbìn! Báwo làwọn irúgbìn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa? Ẹ jẹ́ kí á wo ohun tí Bíbélì ní láti sọ, kí a sì wá rí bí ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wa láti sún mọ́ Ọlọ́run àti ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa.
More