Àwọn Irúgbìn: Kíni àti Ìdí Àpẹrẹ

Seeds: What and Why

Ọjọ́ 1 nínú 4

Ọjọ́ 1- Kí ni 'Irúgbìn' ?

Ó ṣeé ṣe kó má yà ọ́ lẹ́nu pé orí kìíní ìwé Gẹ́nẹ́sísì ni Bíbélì ti kọ́kọ́ mẹ́nu kan irúgbìn. Gẹnẹsisi ni ibi ti a yoo fi ipilẹ ti oye, fun irugbin, àti fún ète àti ìhùmọ̀ Ọlọ́run fún irúgbìn. (Gẹ́nẹ́sísì 1:11, [YCB])

“Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀” (Genesis 1:11, [YCB]).

Orílẹ̀-èdè tí ọ̀rọ̀ Hébérù tí á tú sí "irúgbìn" ti wá ni Zara, èyí tí ìwé àtòjọ atọ́kà-ọ̀rọ̀ ti Strong, àti àwọn mìíràn, túmọ̀ sí, “láti fúnrúgbìn, láti tú irúgbìn ká” (Strong, 2010). Ìtumọ̀ yìí ṣe kedere nínú apá tó kẹ́yìn ẹsẹ náà, níbi tí ó ti tọ́ka sí pé, irúgbìn yẹn ló ń mú kí ohun tó wà ṣáájú rẹ̀ pọ̀ sí i (Gẹ́nẹ́sísì 1:11, [YCB]).

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni a ti rí i tí a kọ́kọ́ mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ irúgbìn náà, bákan náà ni àkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ nípa ìwàláàyè (Gẹ́nẹ́sísì 1:11, [YCB]). Ìbátan náà jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀-ṣe, gbogbo ohun ẹ̀mí ló ń dàgbà tí wọ́n sì ń di ìlọ́po ìlọ́po nípasẹ̀ irúgbìn kan.

Àwọn ìbéèrè tí a lè mú jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú èyí pọ̀ gan-an! Bí irúgbìn kò bá ṣeé yà kúrò nínú ẹ̀mí, nígbà náà, ibo nínú ìgbésí ayé wa ni a ń retí pé kí á so irúgbìn jáde? Bí gbogboẹ̀mí bá wá láti inú irúgbìn, irú irúgbìn wo láti wá? Ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù ni pé, kí ló yẹ kí gbogbo èyí túmọ̀ sí fún mi (Gẹ́nẹ́sísì 1:12, [YCB])

“Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára(Gẹ́nẹ́sísì 1:12, [YCB]).

Ní àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀, a máa wá ìdáhùn sí áwọn ìbéèrè yìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n rí ìtùnú nísinsìnyí, nínú mímọ̀ pé láti inú Genesis 1:12, Ọlọ́run dá irúgbìn fún ire! Ohun rere ni Ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé tí ó ti di aláìṣòótọ́ là ń gbé, Ó ní ètò ìràpadà láti mú irúgbìn èyíkéyìí padà sí ipò ti ó dára, ní kíkún, àti ìhùmọ̀ pípé (Gẹ́nẹ́sísì 1:12, [YCB]).

Mo rọ̀ yín láti ṣàṣàrò lórí àwọn èrò inú Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí, kí ẹ sì wá irúgbìn nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ yín. Kò sí ẹ̀dá kan ṣoṣo tó wà láàyè lónìí tí kò ṣeé tọpasẹ̀ sí látì ìbéèrè, ó sì débí nítorí Irúgbìn.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Seeds: What and Why

Àwọn irúgbìn wà níbi gbogbo. Ọ̀rọ̀ rẹ, owó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti ìwọ alára, je irúgbìn! Báwo làwọn irúgbìn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ kó ṣe pàtàkì sí wa? Ẹ jẹ́ kí á wo ohun tí Bíbélì ní láti sọ, kí a sì wá rí bí ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wa láti sún mọ́ Ọlọ́run àti ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Abundant Life Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ kàn sí https://alcky.com