Gbígbé Nípa Ti Ẹ̀mí Mímọ́: Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì Pẹ̀lú John PiperÀpẹrẹ
Ẹ̀mí Mímọ́ Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Kú
Tí àbùkù bá kàn o fún orúkọ Kristi, alábùkún fún ní o, nítorí Ẹ̀mí ògo àti Ọlọ́run mbẹ lórí e. —1 Pétérù 4:14
Corrie ten Boom sò fún wa bí òun ṣe dààmú gẹ́gẹ́ bí odòmobìnrin bóyá òun máa lè dúró lòdì sí àwọn Jẹ́mánì tí wọn bá dé rú bá rè. Ó nímọ̀lára ààre gidigan nígbà tí ó rò nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀. Bàbá rẹ̀,mo rò pé òun lo, fún un ní àpẹẹrẹ ńlá kan. Ó sò wípé, “Nígbà tí ó mba rìn ìrìn àjò nínú ọkọ̀ rélùwéè, ṣe mọ ń máa fún ọ ní tíkẹ́ẹ̀tì rè ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta síwájú tàbí bí ó ń ṣe worí ọkọ̀ rélùwéè náà?” Ó dáhùn, “Bí mo ń ṣe worí ọkọ̀ rélùwéè náà.” “Nítorí náà Ọlọ́run máa fún ọ ní àkànṣe òkun tí ó nílò láti lókun níwájú ikú nígbà tí ó bá nílò rè gangan ó, kì í ṣe kí ó tó nílò rè.”
Mo nígbàgbọ́ pé 1 Pétérù 4:14 ṣèlérí pé ní wákàtí àdánwò ńlá wa jù lọ Ọlọ́run wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Rẹ̀ láti fún wọn ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́ èyí tí wón kò mò pé àwọn dáńgájíá fún. Èmí Mímọ́ yóò ràn ẹ lọ́wọ́ láti kú.
Àṣà tó dára sò fún wa wípé Nérò lo bẹ́ Pọ́ọ̀lù lórí. Bóyá lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kó gbéyìn ni 2 Tímótì. Ìgbẹ́jọ́ rè nilé ẹjọ́ máa tí bèrè nígbà náà. Ya àwòrán sójà ògbólógbòó kan, ogun ti sọ di págunpàgun fún Alákòóso rè, àbójútó àdáṣe ní Róòmù. A pè sí ilé ẹjọ́. Gbogbo èèyàn ló mò pé òpin àwọn ọjọ́ rè ha ti sún mọ́lé bí. Ọkùnrin táa tí sàmì sí ni. Nígbà náà kò sí èyíkéyìí nínú àwọn òré rè kánkán tọ́ dúró pẹ̀lú ẹ. Ó gbèjà ara rè. Ìpinnu náà ní láti gbọ́ lèkan síí—nígbà náà òpin. Ó padà sí ibùdó rè àti kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí sí Tímótì (2 Tímótì 4:16–17), “Ní ìgbèjà mi àkọ́kọ́ kò sí ẹnì tó dúró pẹ̀lú mi, àmọ́ gbogbo wọn fi mi sílè. Kí a má fi ẹ̀sùn náà kàn wọn! Àmọ́ Ọlọ́run dúró ti mí àti fún mi lókun.”
Mo gbàdúrà pé wa rántí àwọn ọ̀rọ̀ yìí: Èmí Mímọ́ máa ràn ẹ lọ́wọ́ láti kú. Ó. Máa dúró pẹ̀lú ẹ nígbà tí kò sí ẹlòmíràn. Ó máa mú ìgbàgbọ́ rè dúró.O. Máa fún ẹ ni ìkófìrí ògo. Ó máa mú ọ yìn Kristi lógo nínú ikú rè. Ìgboyà tí ìwọ kò rò pé ó ṣeé ṣe láé máa jẹẹ́ tí rè. Ẹ̀mí ògo àti ti Ọlọ́run máa simi lè ó àti gbé ọ lo sì ilè.
Kọ́ ẹ̀kọ́ síi: http://www.desiringgod.org/messages/the-holy-spirit-will-help-you-die
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Èkọ́ Àṣàrò Bíbélì Méje látọwọ́ John Piper nípa Ẹ̀mí Mímọ́
More