Gbígbé Nípa Ti Ẹ̀mí Mímọ́: Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì Pẹ̀lú John PiperÀpẹrẹ

Live By The Spirit: Devotions With John Piper

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́ dídùn inú Ọlọ́run

Ẹ̀mí Mímọ́ ni Ọlọ́run. Ẹnì tó ń gbé inú wa, tí ó n' darí wa, tí ó ń wẹ̀ wá mọ tí ó sì mú wa je mímọ́ kìí ṣe enikeni ti o yàtò sì Ọlọ́run - Ẹ̀mí Mímọ́. Èrí tó kéré jù lọ fún èyí ni orúkọ tí a máa ń pe nígbà púpò “Ẹ̀mí Ọlọ́run.” Ẹ̀mí náà kò jẹ “tí Ọlọ́run” nítorípé Ọlọ́run ṣedà rẹ̀ ṣùgbọ́n nítorí pé Ó ṣàjọpín irúfẹ ẹ̀dá tí Ọlọ́run jẹ́ ó sì tì inú Ọlọ́run wá láti ayérayé. (Wò 1 Kọ́ríńtì 2:10-12).

Tí Ọmọ Ọlọ́run bá jé ayérayé bákan náà pẹ̀lú Baba, gẹ́gẹ́ bí ìwé Jòhánù 1:1–3 ṣe fi hàn kedere pé Ó jẹ́, á jẹ́ wí pé Ẹ̀mí Mímọ́ náà jé ayérayé bákan náà pẹ̀lú àwọn Méjèèjì, nítorí, ní ìbámu pẹ̀lú ìwé Róòmù 8:9–11, Ẹ̀mí Krístì je ẹ̀mí kan náà tí a pè ní Ẹ̀mí Ọlọ́run. Bí èyí kò bá ri bé, a máa ní láti ronú wò pé àkókò kan wà ti Ọlọ́run Ọmọ àti Ọlọ́run Baba kò ní Ẹ̀mí Ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Mímọ́ se pàtàki sí ìbáṣepọ̀ láàárín Baba àti Ọmọ. Ní ìyálò ọ̀rọ̀ Handley C.G. Moule, Ẹ̀mí jẹ́ “àbájáde, ìsopọ̀, àti Ọkọ̀, inú dídùn àti ìfẹ́ ayérayé tí ó wà láàrin wọn” (Ẹnì àti Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, p. 28).

Latètèkọsé nínú ayérayé tí Ọlọ́run Bàbá tí fẹ́ràn Ọmọ, ni Ẹ̀mí tí kò lópin, Ẹ̀mí Mímọ́ ìfẹ́ ati inú dídùn laarin wọn tí ohun tìkára rẹ jẹ Ẹni Àtọ̀runwá, tí wá. Torí náà, bí Jésù ṣe ńgbàdúrà fún ìjọ nínú ìwé Jòhánù 17:26, O béèrè lọ́wọ́ Bàbá Rẹ̀ fún ohun tí kò kéré jù Ẹ̀mí Mímọ́ lọ nígbà tí o wípé, “Mo tí sọ orúkọ Rẹ́ di mímọ̀ fún wón, èmi yóò sì máa sọ di mímọ̀ sì waju síi, kí ìfẹ́ tí Ẹ ti fi fẹ́ràn mi lè wà nínú wón, àti kí Èmi kí ó lè wá nínú wón.

Òtítọ́ tí ó lógo jùlọ nínú gbogbo òtítọ́ tí a o ṣàwárí rẹ nínú àwọn ètò ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì ọlọ́jọ́ méje yìí ni pé nígbà tí Èmí Mímọ́ bá wọ inú ayé wa, kí ṣe wípé Ó má wá gẹ́gẹ́ bí Èmi Baba tàbí tí Ọmọ nìkan lásán, sugbon yóò wà gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ìfẹ́ ailopin láàárín Baba àti Ọmọ, kí a lè fẹ́ràn Baba pẹ̀lú ìfẹ́ tí Ọmọ fi féràn Baba, àti wípé kí a lè feran Ọmọ pelu ìfẹ́ Baba.

Kọ́ ẹ̀kọ́ síi: http://www.desiringgod.org/messages/the-holy-spirit-he-is-god

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Live By The Spirit: Devotions With John Piper

Èkọ́ Àṣàrò Bíbélì Méje látọwọ́ John Piper nípa Ẹ̀mí Mímọ́

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ John Piper àti Desiring God fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: http://www.desiringgod.org/