Dìde sí Ẹ̀rù RẹÀpẹrẹ
Kíni Àwọn Ìṣe Bárakú?
Ǹjẹ́ o ti fi ìgbà kankan ronú sí àwọn ìtọ̀sẹ̀ ìmọ̀lára rẹ? Ṣàkíyèsí àwọn èrò àtúnrò tí wọ́n máa ń fa sábàbí ìmọ̀lára kannáà ṣáá tí wọ́n sì máa ń fa áwọn ìwà bárakú. Láti ní òye àwọn ìtọ̀sẹ̀ yìí ó gba kí a ṣí àwọn kọ́lọ́fín ọkàn wa kí á sí tú palẹ̀ àwọn ìrántí tí a rò pé a tí bò mọ́lẹ̀. A gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní bi ara wa: Kínìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi? Kíni ó kọ́ mi? Báwo ni mo ṣẹlẹ̀ dá wọ́ kí ó tún ṣẹlẹ̀ dúró?
Láì janpata kìí ṣe gbogbo ìtọ̀sẹ̀ ni kò dara. Àwọn ìtọ̀sẹ̀ kan rẹwà tó bẹ́ẹ̀ tí ó yẹ kí á tún wọn lójú ṣe kí á sì dì wọ́n mú títí di ọjọ́ alẹ́. Ẹ̀bùn tó ṣe pàtàkì jù tí o lè fún ara rẹ ní agbára láti ṣàwárí àwọn ìṣe àtìgbàdégbà tó ti wá di ohun bárakú nínú ayé rẹ. Àwọn ìṣe gbogbo ìgbà yí kò ní kóra nílẹ̀ tán pátápátá, ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí o dá wọn mọ̀ kí o sì gba agbára tí wọ́n ní láti fi darí ìgbésí ayé rẹ.
Mo ti nílò láti ṣiṣẹ́ takuntakun láti máa tọ́ka àwọn ìmọ̀lára mi kí n sì máa ṣà fihàn wọn ní gbà tó bá yẹ. Tí o bá rí àyípadà nínú ìhùwàsí ẹ, fi àyè sílẹ̀ láti ṣe àṣàrò sábàbí àyípadà náà. Má kàn dá'gunlá bíi pé kò ní túmọ̀. Wa gbòǹgbò ohun tí ó ún dè ọ́ lọ́nà láti ní ayọ̀ kíkún. Yíò yà ọ́ lẹ́nu bí sísọ ẹ̀dùn ọkàn ẹni jáde ṣe ń mú ara tu ni.
Ǹjẹ́ o lè rántí àwọn ìtọ́ka sí ayé rẹ tí ó ún fún ọ ní ìtìjú, ìnira, tàbí ìdójútì? Ǹjẹ́ àwọn ìrántí kan pàtó so mọ́ ìtọ́ka sí yìí? Báwo ni ìwòye ara rẹ àti àwọn ẹlọ̀míràn ṣe yípadà nítorí ìdí èyí? Mí mọ gbòǹgbò ìṣe àtìgbàdégbà rẹ nìkan ni ọ̀nà tí o lè gbà mu kúrò láyé rẹ pátápátá. Ní kété tí o bá kó fìrìfìrì àwọn ìṣe àtìgbàdégbà tí ó ń fa àìdàṣáká nínú ayé rẹ to, o nílò láti kọjú lòdì síi. Ìkọjú lòdì yí ní láti wá bíi ìgbógun ti àwọn èrò tàbí ìmọ̀lára pẹ̀lú èrò tó yanrantí Júù lọ.
Fífi àìlera ẹni hàn Ọlọ́run ma ń gba agbára kúrọ̀ lọ́wọ́ àwọn ohun gbogbo tó lòdì sí ayé wa. Àwọn ǹkankan wà nínú ayé wa tó lágbára ju ohun tí a lè dá yanjú. A ní lò ìlọ́wọ́sí àt'ọ̀run làti rán wa létí pé ohun àmúlò kan wà fún wa tí ó lágbára ju àwọn ohun ìdábùú tí ó yí wa ká. O kò ma ja ìjà yí níwọ nìkan. Ọlọ́run ní ète àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún ayé rẹ. Gbẹ́kẹ̀lé ìlànà Rẹ̀, nínú èyí tí a rí ayọ̀, àlàáfíà, àti ìfẹ́. Èyí ni ìrònú tí óhún yíni padà thinking láti tàn ìmọ́lẹ̀ sí pa ọ̀nà tó is ṣókùnkùn jùlọ.
Nípa Ìpèsè yìí
Tí a kò bá dojú kọ àwọn ohùn àìbalẹ̀àyà, iyèméjì, àtiẹ̀rù, wọn á gbàkó so ayé rẹ. O kò leè pa àwọn ohùn yìí lẹ́nu mọ tàbí kí o dá'gunlá sí wọn. Nínú ètò ẹ̀kọ́ kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, Sarah Jakes Roberts fi hàn bí a ṣe lè pè níjà àwọn àsémọ́ àtẹ̀yìnwá àti bí a ṣe ń kó mọ́ra àwọn ohun tí kò rọrùn kí á lè di ẹnití kò ṣeé dá duro.
More