Dìde sí Ẹ̀rù RẹÀpẹrẹ

Don't Settle For Safe

Ọjọ́ 1 nínú 3

Kò Sí Àwáwí Mọ́

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń sapá láti borí ìbẹ̀rù wọn ló ti ní ìjákulẹ̀ tó pọ̀ débi pé gbogbo àlá tí wọ́n bá ń lá ló máa ń ní ìbẹ̀rù pé àwọn ò ní lè borí. Nígbà tí èrò inú rẹ bá kún fún èrò pé "kí ló máa ṣẹlẹ̀ ká ní", kò síbi tó o ti lè ní ìgbàgbọ́. Bó o bá ti múra sílẹ̀ de àbájáde búburú jù lọ, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tó o wà nínú àhámọ́. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wàá rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín pípa ọkàn-àyà rẹ mọ́ àti dídènà rẹ̀. Wàá mọ bí o ṣe lè jáwọ́ nínú sísọ ohun rere tí Ọlọ́run ṣèlérí fún gbogbo àwọn tó ń gbé níbàámu pẹ̀lú ète Rẹ̀.

Ìwọ ọ̀rẹ́ mi tó o ti là á já, o ò ní fi ìgbésí ayé tó jẹ́ pé àìlówò tàbí ìrírí tó o ti ní sẹ́yìn ló ń darí rẹ. O ní agbára kan tó lè ṣiṣẹ́ nínú rẹ láti dá ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè sọ ọ di ẹrú nípa ti èrò orí àti ti ìmọ̀lára, èyí tó ti mú kó dá ọ lójú pé ìgbésí ayé tó dára ju èyí lọ kò sí lọ́wọ́ rẹ. A ò lè lo agbára yẹn ká sì máa wá àwáwí lẹ́ẹ̀kan náà. Ó yẹ kí ọkàn rẹ, èrò inú rẹ, àti ọwọ́ rẹ lómìnira láti mú gbogbo ohun tó wà níwájú rẹ.

Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ ká lè máa ronú lọ́nà tó tọ́, ká máa bá ara wa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tọ́, ká sì máa hùwà tó tọ́. Àye wà fún èdè tó sọ pé: màá ṣe! Ìdàgbàsókè máa ń wáyé nígbà tá a bá fojú ara wa rí àwọn ìrírí wa àti bí wọ́n ṣe yí wa padà. O lè ṣe àtúnṣe sí ohun tó o ti ṣe tẹ́lẹ̀, kó o sì máa tẹ̀ síwájú láìyẹsẹ̀, àmọ́ o ní láti mọ ohun tó mú kó o jáwọ́. Bí àwọn èèyàn mìíràn yàtọ̀ sí ìwọ fúnra rẹ bá fún ọ ní ìpèníjà náà láti mú ara rẹ lára dá kó o sì di ẹni pípé, nígbà náà ìrìn àjò rẹ yóò máa béèrè fún ìyọ̀ǹda kí o tó tẹ̀ síwájú.

Má ṣe jẹ́ kí ìjọba tiwa-n-tiwa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Àwọn tó sún mọ́ ẹ lè má mọ bí wọ́n ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ nílò ìbànújẹ́ rẹ kí wọ́n má bàa ronú nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n rí ìtura. Yẹra fún ìdẹwò láti sọ pé kí àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà ẹ́ kó o tó lè rí ìwòsàn.

A ṣe afárá láti ẹni tó o jẹ́ tẹ́lẹ̀ sí ẹni tí Ọlọ́run yàn pé kó o jẹ́ láti inú àwọn bíríkì ìfọ̀kànbalẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ tó lágbára bí amọ̀, àti ètò àrà ọ̀tọ̀ kan tó pé pérépéré, kódà àwọn nǹkan tó máa ń dùn ẹ́ tẹ́lẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe dáadáa. Ìmúratán rẹ láti jáwọ́ nínú àwọn àwáwí àti ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́ láti máa tẹ̀ síwájú wulẹ̀ jẹ́ kó o ṣe àkọ́kọ́, àmọ́ iṣẹ́ ṣì wà láti ṣe.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Don't Settle For Safe

Tí a kò bá dojú kọ àwọn ohùn àìbalẹ̀àyà, iyèméjì, àtiẹ̀rù, wọn á gbàkó so ayé rẹ. O kò leè pa àwọn ohùn yìí lẹ́nu mọ tàbí kí o dá'gunlá sí wọn. Nínú ètò ẹ̀kọ́ kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, Sarah Jakes Roberts fi hàn bí a ṣe lè pè níjà àwọn àsémọ́ àtẹ̀yìnwá àti bí a ṣe ń kó mọ́ra àwọn ohun tí kò rọrùn kí á lè di ẹnití kò ṣeé dá duro.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Sarah Jakes Roberts àti Thomas Nelson tí wọ́n kọ ètò yí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://bit.ly/YV-DontSettleforSafe