Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Àlàáfíà OlórunÀpẹrẹ

God's Peace

Ọjọ́ 4 nínú 4

ÌGBÀGBỌ́ TÍ Ó L'ÁGBÁRA MÚ ÀLÀFÍÀ WÁ

BÍBÁ ỌLỌ́RUN S'Ọ̀RỌ̀
Déédé, dúró ṣinṣin, àìlèyípadà, t'ó ṣeé gbékẹ̀lé, alágbára - àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe àpèjúwe ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Sọ fún Ọlọ́run, bí o ṣe n gb'àdúrà, bí o ṣe mọrírì Rẹ̀ tó fún àwọn àbùdá wọ̀nyí.

ÀRÒJINLẸ̀
Pèsè ìsaàsùn méjì tí ó kún fún iyanrìn: kí ọ̀kan tutù kí ó sì dúró ṣinṣin, kí èkejì má dúró ṣinṣin kí ó sì gbẹ. Wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìṣeré kan tàbí òkúta dídán kọjá irú iyanrìn kọ̀ọ̀kan. Ìdí ni láti ri irú iyanrìn tí ó gba nkan ọ̀hún láàyè láti yí s'íwájú síi.

LÍLỌ JINLẸ̀
Gẹ́gẹ́ bí ó ti rọrùn láti yí àwọn nkan kọjá lóri iyanrìn tí ó dúró ṣinṣin, ìgbàgbọ́ tí ó f'ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ́ kí ó rọrùn fún ọ bí o ti n la àwọn ohun rere àti búburú kọjá ní ayé. Ìgbàgbọ́ mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún wá, èyí tí àlàáfíà jẹ́ ọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀. Orin Dáfídì 29:11 sọ pé, “OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára; OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia.” Ṣùgbọ́n nígbà tí o kò bá gbékẹ̀lé Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ rẹ á jọ iyanrìn tí kò dúró ṣinṣin; á nira láti kọjá àwọn ohun líle ní ayé. Ìdí níyì tí o fi nílò láti gb'àdúrà wípé kí Ọlọ́run fà ọ́ súnmọ́-Ọn àti láti kọ́ ìgbàgbọ́ rẹ nínú Rẹ̀.

BÍBÁ ARA WA S'Ọ̀RỌ̀
- Ṣe àpèjúwe àkókò kan tí ìgbàgbọ́ rẹ ti d'àgbà. Kíni ó rán ẹ̀ l'ọ́wọ́ láti d'àgbà nínú ìgbàgbọ́ rẹ?
- Báwo ni ìwo ṣe ní ìrírí àlàfíà Ọlọ́run? Báwo ni ó ṣe rí?
- Ọlọ́run ni aṣèdá àlàfíà àti ohun rere gbogbo. Njẹ́ o ti béèrè l'ọ́wọ́ Rẹ̀ fún ìgbàgbọ́ díẹ̀ síi? Njẹ́ o ti béèrè l'ọ́wọ́ Rẹ̀ fún àlàáfíà Rẹ̀?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

God's Peace

Ọ̀rọ̀ ọlọ́run sọ fún wa wípé óún pèsè àláfíà “èyí tí ó kọjá òye” (Fílípì 4:7 NIV). Nínú ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-mẹ́rin yíí, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ma wo àwọn ibi tí atilè rí ìrírí àláfíà yen. Ní ojojúmọ́, fi àdúrà ní kíákíá, kíka ìwé...

More

We would like to thank Focus on the Family for providing this plan. For more information, please visit: www.FocusontheFamily.com

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa