Àlàáfíà OlórunÀpẹrẹ

God's Peace

Ọjọ́ 3 nínú 4

ILÉ ÀLÀFÍÀ

BÍBÁ ỌLỌ́RUN S'Ọ̀RỌ̀
Bèèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìdáríjì tí o bá ti pa ẹnìkan l'ára nínú ìdílé rẹ tàbí tí o bá ti jẹ́ aláìláàánú. Lẹ́hìn náà, dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run fún àwọn ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́.

ÀRÒJINLẸ̀
Lo àwọn àwọ̀ dídán láti ya àwòrán ilé pẹ̀lú òòrùn àti àwọn ẹiyẹ ní ìta àti pẹ̀lú àkàrà òyìnbó, àwọn ẹ̀bùn àti ẹbí kan nínú ilé. Lẹ́hìn náà, lo àwọn àwọ̀ dúdú láti ya ilé òmíràn pẹ̀lú àwọn àwọsánmà ìjì àti mànàmáná ní ìta àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí n bínú sí ara wọn ní inú ilé. Ṣe àfiwé àwọn àwòrán náà. S'ọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ọ̀kán fi ní àlàáfíà ju èkejì lọ.

LÍLỌ JINLẸ̀
Àwọn ìdílé jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní àwọn ẹ̀dùn àti ìfẹ́ oríṣiríṣi. Nígbà kan, àwọn ọmọ ẹbí ní ìdùnnú, àwọn àkókò mìràn, wọ́n ní ìbínú. Bí èniyàn ṣe nrò kò yẹ kí ó yí àlàáfíà inú ìdílé kan padà. Romu 12:18 sọ pé, "Ẹ sa ipá yín, níwọ̀n bí ó bá ti ṣeéṣe, láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu gbogbo eniyan." Gbogbo ènìyàn yìí túnmọ̀ sí àwọn ẹbí tìrẹ náà. Gbígbé pẹ̀lú àwọn tí ó wà nínú ẹbí rẹ lè dàbí iṣẹ́ púpọ̀ ní àwọn ọjọ́ míràn. Ṣùgbọ́n Owe 17: 1 sọ pé ilẹ àlàfíà jẹ́ ìṣura tòótọ́, ohun tí ó yẹ láti ṣiṣẹ́ fún. "Kí á fi alaafia jẹun, láìsí ọbẹ̀, ó sàn ju kí á máa fi ẹran jẹun pẹlu ìyọnu lọ."

BÍBÁ ARA WA S'Ọ̀RỌ̀
- Báwo ni ó ṣe yẹ kí o hùwà sí àwọn mọ̀lẹ́bí?
- Kíni o lè ṣe láti jẹ́ kí àlàfíà wà nínú ẹbí nígbà tí ẹnìkan bá n bínú?
- Báwo ni àlàfíà Olọ́run ṣe lè kún inú ilé re, síbẹ̀síbẹ̀ nígbà tí e bá tako ara yín?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

God's Peace

Ọ̀rọ̀ ọlọ́run sọ fún wa wípé óún pèsè àláfíà “èyí tí ó kọjá òye” (Fílípì 4:7 NIV). Nínú ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-mẹ́rin yíí, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ma wo àwọn ibi tí atilè rí ìrírí àláfíà yen. Ní ojojúmọ́, fi àdúrà ní kíákíá, kíka ìwé mímọ́ ní ṣhókí àti àlàyé, àṣàyàn iṣẹ́-ṣíṣe, àti àwọn Ìbéèrè ìjíròrò kun.

More

We would like to thank Focus on the Family for providing this plan. For more information, please visit: www.FocusontheFamily.com