Àlàáfíà OlórunÀpẹrẹ
ALAAFIA NIPASẸ TITẸLE AWỌN OFIN ỌLỌRUN
BÍBÁ ỌLỌ́RUN S'Ọ̀RỌ̀
Sọ fún Ọlọ́run ní ohun tí o fẹ́ràn nípa Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Bíbélì. Sọ fun ní ìdí tí o fi fẹ́ràn ẹsẹ̀ tàbí ìtàn kan, kí o sì dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Rẹ̀ fún-un.
ÀRÒJINLẸ̀
Pẹ̀lú Màmá tàbí bàbá tí ó dúró nítòsí, gbìyànjú láti rìn káàkiri yàrá pẹ̀lú bàta yìnyín l'ẹ́sẹ̀ rẹ, àwọn imu wíwẹ̀ tàbí bàtà tí ó tóbi púpọ̀. Wo ibi tí o lè rìn dé láì kọsẹ̀ tàbí subú? Ṣé o rò pé òfin pé a kò gbọdọ̀ wọ àwọn nkan wọnyí ní ilé yóò jẹ́ ìmọ̀ràn tó dára? Ṣe àlàyé.
LÍLỌ JINLẸ̀
Wo Orin Dafidi 119: 165: “Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ, kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.” Ọlọ́run ṣe ìlérí àlàáfíà nlá fún ọ nígbà tí o bá ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sọ. Títẹ̀lé àwọn òfin Ọlọ́run á ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti ṣe àwọn àṣìṣe díẹ, àti pé o kò ní láti ṣ'àníyàn nípa “ìkọsẹ̀” tàbí níní ìpalára nítorí àwọn ìpinnu búburú. Gbígbé ní ìbámu sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àlàáfíà Rẹ̀ láàyè láti ṣ'àkóṣo ọkàn rẹ. Fún ìrántí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, ṣe àtúnyẹ̀wò Orin Dafidi 18:30, 19: 8, 33: 4.
BÍBÁ ARA WA S'Ọ̀RỌ̀
- Ronú nípa òfin kan tí o tẹ̀lé, gẹ́gẹ́ bíi rírìn ní ọ̀nà tàbí kí o má sáré ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ ilé-ìwé. Ṣé ó ṣeé ṣe láti ní ìpalára nígbà tí o bá tẹ̀lé àwọn òfin tàbí nígbà tí o kò bá tẹ̀lé wọn? Ṣe àlàyé.
- Nígbà wo ni o ti ní àlàáfíà nítorí o gbọ́ràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
- Báwo ni o ṣe lè gba àlàáfíà Ọlọ́run padà lẹ́hìn tí o ti kùnà rẹ̀?

Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọ̀rọ̀ ọlọ́run sọ fún wa wípé óún pèsè àláfíà “èyí tí ó kọjá òye” (Fílípì 4:7 NIV). Nínú ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-mẹ́rin yíí, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ma wo àwọn ibi tí atilè rí ìrírí àláfíà yen. Ní ojojúmọ́, fi àdúrà ní kíákíá, kíka ìwé mímọ́ ní ṣhókí àti àlàyé, àṣàyàn iṣẹ́-ṣíṣe, àti àwọn Ìbéèrè ìjíròrò kun.
More
We would like to thank Focus on the Family for providing this plan. For more information, please visit: www.FocusontheFamily.com