Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Àlàáfíà OlórunÀpẹrẹ

God's Peace

Ọjọ́ 1 nínú 4

ÀLÁFÍÀ NÍNÚ ÀÀBÒ

BÍBÁ ỌLỌ́RUN S'Ọ̀RỌ̀
Àwọn nkan wo ni ó n pa ọ́ mọ́ ni ààbò l'ójoojúmọ́? Wíwà ní àìléwu n fún ni ní rílára àlàáfíà. Dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Ọlọ́run fún àwọn ohun tí ó n pa ẹ́ mọ́ - àwọn beliti ìjokòó, àwọn àgádágodo enu ilẹ̀kùn, àwọn òbí, àwọn ọlọ́pàá, àwọn oníjà iná àti pàápàá àwọn itaniji èéfín.

ÀRÒJINLẸ̀
Tani tàbí kíni ó lè pariwo tí o bá jó àkàrà tàbí ògì rẹ? (ìwọ, màmá tàbí bàbá re àti itaniji èéfín)

LÍLỌ JINLẸ̀
Ní ayé àtijọ́, a kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nípa iná nígbà tí ẹnìkan ní ìta bá gbá igi kékeré kan. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ó ti sùn, síbẹ̀síbẹ̀, nígbà míràn ò ní gbọ́ ariwo náà. Báyìí àwọn ilé míràn ní àwọn àpótí oníke kékeré pẹ̀lú àwọn batiri tí ó n kìlọ̀ nígbà tí iná bá wà. O lè sùn ní àlàáfíà láìsí ìbẹrù wípé ìwọ kì yóò gbọ́ ariwo iná ní ìta. Ọlọ́run fún ọ ní àlàáfíà tí ó dára jùlọ tí ó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti ní ààbò nì gbogbo ìgbà. Jésù sọ nínú Johannu 14:27, “Alaafia ni mo fi sílẹ̀ fun yín. Alaafia mi ni mo fun yín. Kì í ṣe bí ayé ti í fúnni ni mo fun yín. Ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín.”

BÍBÁ ARA WA S'Ọ̀RỌ̀
- Kíni àwọn nkan tí ó bà ó l'ẹ́rù?
- Nígbà tí o bá n b'ẹ̀rù, báwo ni o ṣe lè rántí pé Ọlọ́run fẹ́ fún o ní àlàáfíà Rẹ̀?
- Báwo ni o ṣe lè gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run síi lónìí?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

God's Peace

Ọ̀rọ̀ ọlọ́run sọ fún wa wípé óún pèsè àláfíà “èyí tí ó kọjá òye” (Fílípì 4:7 NIV). Nínú ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́-mẹ́rin yíí, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ma wo àwọn ibi tí atilè rí ìrírí àláfíà yen. Ní ojojúmọ́, fi àdúrà ní kíákíá, kíka ìwé...

More

We would like to thank Focus on the Family for providing this plan. For more information, please visit: www.FocusontheFamily.com

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa