Ọ̀nà Ọlọ́run sí ÀṣeyọríÀpẹrẹ
Kò sí ẹni t'ó máa ń gbèrò láti kùnà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè yí ọwọ́ aago ìgbà padà sẹ́hìn láti ṣe àtúnṣe àwọn ohun t'ó ti bàjẹ́ l'áwọn ọdún sẹ́hìn, síbẹ̀ a ní ànfààní láti ṣ'àṣeyege láti ìgbà yí lọ. A lè bẹ̀rẹ̀ tàbí kí á tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò à-timú ìpinnu Ọlọ́run fún wa ṣẹ.
Ọlọ́run fi àṣírí gbígbé ayé aláṣeyọrí hàn wá ní Orin Dáfídì 25:14. Láti mọ májẹ̀mú Ọlọ́run ni láti mọ ojúrere àti ìbùkún rẹ̀. Ó hàn kedere pé májẹ̀mú rẹ̀ àti ààbò wà pọ̀ ni. Fi ìdarí ayé rẹ sí abẹ́ májẹ̀mú Ọlọ́run kí o lè ṣe àṣeyọrí nínú ẹ̀mí.
Àmọ́ ìlànà kan wà nínú ẹsẹ yí: o ní láti bẹ̀rù Ọlọ́run kí o lè mọ májẹ̀mú rẹ̀. Àwọn ìgbésẹ̀ àti àyọrísí wà fún à-ti-ṣe àṣèyọrí nínú ẹ̀mí. Èyí wà gẹ́gẹ́ bí irú ọ̀wọ̀ atí ọlá tí o bù fún Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èyí á wá nípa lórí irú ìpele àṣeyọrí rẹ. O kò lè ṣàìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run nínú àwọn ìpinnu rẹ kí o wá máa retí àṣeyọrí nínú nnkan ti ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀wọ̀ àti ìgbọ́ràn ni ìpìlẹ̀ àṣeyọrí.
Àwọn ibo nínú ayé rẹ ni oò ti fi ẹ̀rù tòótọ́ fún Ọlọ́run hàn?
Kínni ó túmọ̀ sí láti ní májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run?
A lérò pé ètò Bíbélì yí ràn ọ́ lọ́wọ́. Kọ́ síi nípa Tony Evans àti Ìdìde Àwọn Ọkùnrin Ìjọba Ọlọ́runhere.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbogbo ènìyàn ló ńwá àṣeyọrí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni kò rí i nítorípé ohun tí wọn ń lé ní òye àdàmọ̀dì lórí ohun tí gbígbé ìgbé ayé àṣeyọrí túmọ̀ sí. Kí a tó lè rí àṣeyọrí tòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbá'jú mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó túmọ̀ sí. Jẹ́ kí gbajúgbajà òǹkọ̀wé nì Tony Evans fí ọ̀nà sí àṣeyọrí tóòtọ́ ti ìjọba Ọlọ́run hàn ọ́ àti bí ọ ṣe lè wá a rí.
More