Ọ̀nà Ọlọ́run sí ÀṣeyọríÀpẹrẹ

God’s Path to Success

Ọjọ́ 2 nínú 3

Nínú ọ̀ràn tẹ̀mí, àṣeyọrí ni a rí nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ fún ìgbésí ayé rẹ. Ohun tí Bíbélì sọ nípa àṣeyọrí nìyẹn. Nínú àṣà ìbílẹ̀ wa lóde òní, ọ̀pọ̀ èrò tí kò tọ̀nà ló wà nípa ohun tí àṣeyọrí túmọ̀ sí. Àwọn kan máa ń rò pé owó téèyàn ní ló máa jẹ́ kéèyàn ṣàṣeyọrí. Àwọn míì sì sọ pé ohun tó máa jẹ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o ṣe dáadáa nínú iṣẹ́. Lóde òní, iye àwọn tó ń tẹ̀ lé ẹ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló máa ń fi hàn. Àmọ́ ìṣòro tó wà nínú gbogbo èrò yìí ni pé wọn ò bá ìlànà Ọlọ́run mu.

Jésù fún wa ní ìtumọ̀ àṣeyọrí nígbà tí ó sọ pé, “Mo yìn ọ́ lógo ní ayé, lẹ́yìn tí mo ti parí iṣẹ́ tí ìwọ ti fi fún mi láti ṣe” (Jòhánù 17:4).

Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan náà lọ́nà tó yàtọ̀ nígbà tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Mo ti ja ìjà rere náà, mo ti parí eré náà, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” ( 2 Tímótì 4:7).

Ní ti tòótọ́, Ọlọ́run sọ fún Jóṣúà pé àṣeyọrí rẹ̀ dá lórí ṣíṣàṣàrò rẹ̀ dáadáa lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú títọ́ àwọn ìpinnu àti ìṣe rẹ̀ sí ìsàlẹ̀ rẹ̀ (Jóṣúà 1:8). Àṣeyọrí wé mọ́ ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run pè ọ́ láti ṣe ṣẹ.

Kí lo rò pé àṣeyọrí jẹ́?

Báwo ló ṣe bá ohun tí Ọlọ́run sọ mu?

Ìwé mímọ́

Day 1Day 3

Nípa Ìpèsè yìí

God’s Path to Success

Gbogbo ènìyàn ló ńwá àṣeyọrí, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni kò rí i nítorípé ohun tí wọn ń lé ní òye àdàmọ̀dì lórí ohun tí gbígbé ìgbé ayé àṣeyọrí túmọ̀ sí. Kí a tó lè rí àṣeyọrí tòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbá'jú mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó túmọ̀ sí. Jẹ́ kí gbajúgbajà òǹkọ̀wé nì Tony Evans fí ọ̀nà sí àṣeyọrí tóòtọ́ ti ìjọba Ọlọ́run hàn ọ́ àti bí ọ ṣe lè wá a rí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Urban Alternative (Tony Evans) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tonyevans.org/