Ìhámọ́ra Ọlọ́runÀpẹrẹ

The Armor of God

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo ọmọdé kùnrin ló féràn láti máa ṣe eré "ọlọ́pàá àtí olè" bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìjà yìí yàtọ̀ sí ìjà gidi pẹ̀lú ìbọn àti ọfà iná. Ní ojú ìjà gidi, tí àwọn ọ̀tá bá ta ọfà iná sí àárín àwọn alátakò wọn, iná yìí ni wọ́n á máa gbìyànjú láti pa, kàkà kí wọ́n máa jagun.

Ní àkọ́kọ́, iṣẹ́ ọfà iná ni láti dá àwọn ọtá láàmú, kìí ṣe láti pa tàbí parun.

Arábìnrin, ó wu ọ̀tá láti dà ọ́ láàmú. Kí ó baà lè dà ọ́ l'ọ́kàn rú. O ní láti mọ̀ wípé ó mọ̀ọ́mọ̀ ta àwọn ọfà yìí ni. Ó ti mọ àwọn iṣẹ́, ẹ̀rù àti àìlera rẹ, ó sì ń f'ojú sí àwọn agbègbè wọ̀nyí ní pàtó. Ó mọ̀ wípé oun kò lè pa ọ́ run nítorí o wà lábẹ́ ààbò Jésù tí kò l'ópin. Àmọ́ ó fẹ́ fa ojú rẹ kúrò l'ára oun tó ní láárí pẹ̀lú ìrònú, ìjàyà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àti àníyàn. Ó fẹ́ kí o d'ojú kọ ibòmíràn kí ó baà lè yọ́ wọlé láti éyìn wà.

Nínú Efesu 6, Pọọlù ṣ'àfihàn ìgbànú, ìgbáyà àti bàtà gẹ́gẹ́ bíi àmúre èmi tí onígbàgbọ́ gbọ́dọ̀ máa wọ̀ nígbà gbogbo. Ìsẹ́jú sí ìsẹ́jú. Ọjọ́ sí ọjọ́. Àmọ́ fún ìhámọ́ra ìgbàgbọ́, ó pàṣẹ wípé kí a "gbé e wọ̀.”

Wò ó ní ọ̀nà yìí: noosi lè máa wọ aṣọ iṣẹ́ rẹ̀ lójoojúmó, àmọ́ tó bá di àsìkò kan, ó lè mú àwọn ẹ̀rọ àti irin-iṣẹ́ míràn fún ìtọ́jú aláìsàn. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa wo aṣọ iṣẹ́ tí a fi fún wa l'átọ̀runwá lójoojúmó, kí a sì wà ní ìmúrasílẹ láti "mú" àwọn ohun èlò míràn tí ó bá ti yẹ.

Àkọ́kọ́ l'ára àwọn ìhàmọ́ra wọ̀nyí ni ìhámọ́ra ìgbàgbọ́. Nígbàkigbà tí a bá ní ìfura pé ọfà iná fẹ́ máa ṣọṣẹ́ nínú ayéè wa, a bẹ̀rẹ̀ síí lo ìgbàgbọ inú ìṣúra gẹ́gẹ́ bíi ààbò lórí ayé wa.

Má jáfara! Ọtá á rán ọfà ina sínú ayé rẹ nígbà tí a bá pè ọ́ láti rìn pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Àwọn ọfà yìí fẹ́ láti mú ẹ kúrò nínú ọnà ìṣẹ́gun: rírìn nínú ìgbàgbọ́!

Ìgbàgbọ́ á màa pa oró ọfà iná. Kíni Ọlọ́run ń sọ fún ẹ láti ṣe? Se é! Pẹ̀lú ìgbàgbọ́.

Ìwé mímọ́

Day 3Day 5

Nípa Ìpèsè yìí

The Armor of God

Ní gbogbo ọjọ́, lójoojúmó, àwọn ogun àìrí njà ní àyíká rẹ - àìrí, àìgbọ́, sùgbón o ń ríi ipà rẹ ẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà nínú ayé è rẹ. Àwọn ọmọ ogun èṣù ńwá ònà láti ṣe búburú nínú gbogbo ohun tí ó ṣe pàtàkì ṣí ọ: ọkàn rẹ, èèrò rẹ, ìgbéyàwó rẹ ẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìbáṣepọ̀ rẹ, àwọn ohun tí o nla kàkà fún, àlá à rẹ, ọjọ́ iwájú rẹ̀ ẹ. Sùgbón èrò ìjà a rẹ dúró lóri pé kí ó ká ọ mọ́ láì ro àti lái gbaradi. Bí àtì kiri yìí àti bí ó ṣe ká ọ mọ́ láì gbaradi yìí bá ti su o, ètò yìí wà fún ọ. Ọ̀tá yìí má n kùnà pátápátá tí ó bá pàdé Obìnrín tí o gbaradi. Ìhámọ́ra Ọlọrun ju àlàyé Bíbélì lásán nípa ohun èlò tí onígbagbọ ní, o jẹ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti wọ̀ ọ́, àti kíkọ́ ọna bi a o se yori funrarawa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Priscilla Shirer àti ẹgbẹ́ ẹ Lifeway Christian Resources fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.lifeway.com