Ìhámọ́ra Ọlọ́runÀpẹrẹ

The Armor of God

Ọjọ́ 1 nínú 5

Àwọn oun tí ó dà ọ́ l'ọ́kàn rú jù nípa ọ̀rọ̀ ayéè rẹ - àwọn oun tí o wòye pẹ̀lú ẹ̀yà-ara máràrún tí a ń lò fún ìmọ̀lára - gangan kọ́ ni kókó. Ohun gbogbo tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé tí a f'ojú rí ní ìbáṣepọ̀ pẹlú ìjàkadì t'inú èmí. Ọ̀tá rẹ - èṣù - fẹ́ kí o wà nínú òkùnkùn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ẹ̀mí, pẹ̀lú ìbòjú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ara. Nítorí nígbà tí ìwọ bá dojú kọ ǹkan ti ara, oun yóò ráyè láti máa ṣe ohun tí ó wùú lábẹ́nú nípa ti ẹ̀mí. Bí o bá kọ̀ láti kọbiara síi, yóò mú kí ìdíbàjẹ́ ayéè rẹ máa peléke si. L'ótìítọ́ ó lè má rọrùn láti rí ọ̀tá wa, ṣùgbọ́n kìí ṣe ìtàn-àròsọ. Ó wà láàyè, ó ń tẹ̀síwájú láti máa lépa, ó sí ń d'ojú ìjà kọ wá nígbà gbogbo.

Wípé o jẹ́ onígbàgbọ́ kìí ṣe àjẹsára fún àwọn ogun tí èmi tí ń bẹ nínú ayé àìrí, ṣùgbọ́n yóò fún ọ ní ànfàní láti lo agbára Baba - agbára Rẹ láti gbèjà àti láti yí gbogbo oun tí a ṣe lòdì sí ọ padà. Tí o bá fẹ́ ṣẹ́gun - tí o bá fẹ́ tẹ̀lé mi láti yí ogun náà padà, láti mú ọ̀tá balẹ̀ àti láti ba iṣẹ́ rẹ jẹ́ nínú ayéè rẹ - àṣírí ibẹ̀ ni ìmọ̀ wípé o ní agbára ju èyí tí ó d'ojú kọ ọ́, nítorí Ẹni tí ó dúró tì ọ́.

Pọ́ọ̀lù kọ ìwé Éfésù nítorí wípé ó fẹ́ ṣí ìyè wa sí ìjà ti ẹ̀mí, àti láti ṣí ojúu wa sí agbára tí ń bẹ nínú gbogbo ẹni tí ó ní ìbáṣepọ̀ pẹlú Ọlọ́run n'ípasẹ̀ Krístì. Nínú Éfésù, Pọ́ọ̀lù ṣáà ń tẹnu mọ́ ọ̀kan l'ára ìhàmọ́ra tí ó ṣe kókó jù lọ, ṣùgbọ́n tí à ń fojú fòdá lọ́pọ̀ ìgbà: ádùrá.

Pọ́ọ̀lù rí ádùrá gẹ́gẹ́ bíi ohun tó ṣe kókó tí a bá ma b'orí Èṣù, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan kọ wípé, "Ìwé Éfésù ní ẹsẹ̀ Bíbélì 55% ó lé tí ó níí ṣe pẹ̀lú ádùrá" ju Ìwé Róòmù, èyí tí í ṣe ìwé tó gùn jù tí Pọ́ọ̀lù fi ṣọwọ́. Àìmọye ìgbà ni ó sì wọnú àdúrà lọ níbi tí ó tí ń kọ ìwé náà. Bó bá sì bẹ̀rẹ̀ àdúrà yí…, àdúrà rẹ̀ máa ń lójú, yóò sì ri dájú wípé ẹni tí ń ka ìwé rẹ̀ mọ pàtó ohun tí àdúrà náà dá lé lórí. Ó mọ̀ wípé ádùrá lè yí gbogbo ayé wa padà. A kò lè yọ àdúrà sílẹ̀ nígbàtí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun nínú ìjàkadì ẹ̀mí.

Ka Éfésù 1:18-21 àti 3:14-19. Nínú gbogbo ǹkan tí Pọ́ọ̀lù gbádùrá lé, èwo lo nílò láti bèèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run jùlọ lónìí?
Day 2

Nípa Ìpèsè yìí

The Armor of God

Ní gbogbo ọjọ́, lójoojúmó, àwọn ogun àìrí njà ní àyíká rẹ - àìrí, àìgbọ́, sùgbón o ń ríi ipà rẹ ẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà nínú ayé è rẹ. Àwọn ọmọ ogun èṣù ńwá ònà láti ṣe búburú nínú gbogbo ohun tí ó ṣe pàtàkì ṣí ọ: ọkàn rẹ, èèrò rẹ, ìgbéyàwó rẹ ẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìbáṣepọ̀ rẹ, àwọn ohun tí o nla kàkà fún, àlá à rẹ, ọjọ́ iwájú rẹ̀ ẹ. Sùgbón èrò ìjà a rẹ dúró lóri pé kí ó ká ọ mọ́ láì ro àti lái gbaradi. Bí àtì kiri yìí àti bí ó ṣe ká ọ mọ́ láì gbaradi yìí bá ti su o, ètò yìí wà fún ọ. Ọ̀tá yìí má n kùnà pátápátá tí ó bá pàdé Obìnrín tí o gbaradi. Ìhámọ́ra Ọlọrun ju àlàyé Bíbélì lásán nípa ohun èlò tí onígbagbọ ní, o jẹ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti wọ̀ ọ́, àti kíkọ́ ọna bi a o se yori funrarawa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Priscilla Shirer àti ẹgbẹ́ ẹ Lifeway Christian Resources fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.lifeway.com