Ìyípadà-Pátá Kúrò Nínú Afẹ́sódìÀpẹrẹ
Tó o bá jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí èrò rẹ, tó o sì ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, wàá ní òmìnira. Bí Jésù ṣe sọ, "ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ ní òmìnira" (Jòhánù 8:32). Ọ̀rọ̀ náà "mọ̀" túmọ̀ sí ohun tó ju pé kéèyàn mọ nǹkan kan. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kó o gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ náà. Ìwọ náà mọ̀ pé o mọ̀ pé òótọ́ ni. Òtítọ́ yìí ló máa ń jẹ́ kó o mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an. Ohun tó túmọ̀ sí láti mọ òtítọ́ kó o sì di òmìnira nìyẹn.
Irú "ìmòye" tí Jésù sọ pé ó máa sọ ọ́ di òmìnira ni "ìmọ̀" tó mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ . Kì í ṣe wíwàníyàn ni. Kì í ṣe ìrètí. Kì í ṣe ìdánwò ni. O mọ̀ pé o mọ̀ nítorí pé o ti fojú ara rẹ rí i pé òótọ́ ni.
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe gbogbo ìgbà la máa ń rí ẹ̀rí tó dájú pé ìgbàgbọ́ tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ òtítọ́ kò ní já sásán. Ìdí nìyẹn tí ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀, tó sì ṣe pàtàkì gan-an láti borí àṣà tó ń sọni di bárakú. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, o gbọ́dọ̀ gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́, lẹ́yìn náà kó o wá fi Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sílò nínú ipò rẹ gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ kó bàa lè máa gbọ̀n pẹ̀lú rẹ, kó sì máa ṣe iṣẹ́ tó ń dáni sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ. Òtítọ́ máa ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ohun tó o rò pé ó burú, àmọ́ kìkì nígbà tó o bá gbà pé òótọ́ ni. O gbọ́dọ̀ mú èrò inú rẹ, ìṣe rẹ, ọkàn-àyà rẹ àti ìfẹ́ ọkàn rẹ bá Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìlànà rẹ̀ mu ní ti ipò èyíkéyìí tàbí ìrònú èyíkéyìí tó o bá dojú kọ kó bàa lè dá ọ sílẹ̀ lómìnira.
Kí lo mọ̀ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ àṣà tó ti di bárakú fún ọ?
A retí pé ètò yìí á fún ẹ níṣìírí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí o ṣe lè yí ìgbésí ayé rẹ padà, tẹníhìn-ín.
Nípa Ìpèsè yìí
Níìgbàtí ìgbé ayé rẹ bá kúrò ní ìlànà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ọlọ́run, ó fẹ́rẹ̀ dájú wípé wàá ní ìrírí àwọn àtunbọ̀tán tí ó ní ìrora. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lóti tiraka pẹ̀lú ìlera wọn, wọ́n pàdánù iṣẹ́, àti àwọn ìbáṣepọ̀, wọ́n bá ara wọn nínú ìmọ̀lára pé wọ́n jìnà sí ọlọ́run nítorí àwọn ìkúndún bárakú. Yálà ìkúndùn bárakú tí ó le bíi oògùn olóró tàbí àwòrán ìwòkúwò tàbí ìkúndùn bárakú tí ó ṣẹ́ pẹ́rẹ́, bíi oúńjẹ tàbí ìdánilárayá, àwọn ìkúndùn bárakú a máa da ètò ayé wa rú. Jẹ́ kí Tony Evans ońkọ̀wé tí ó tàjù fi ọ̀nà òmìnira hàn ọ́.
More