Ìyípadà-Pátá Kúrò Nínú Afẹ́sódìÀpẹrẹ

A U-Turn From Addiction

Ọjọ́ 2 nínú 3

Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí àwọn ènìyàn fi há sínú àfẹ́sódì wọn ni pé wọ́n gbé ìlànà ìrònú wọn kalẹ̀ lórí irọ́. Irọ́ ńlá tí ó ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àfẹ́sódì ni pé o lè lo ẹran-ara láti mú ẹran-ara bọ̀sípò. Ṣugbọn Paulu sọ fún wa ní 2 Kọ́ríńtì 10; A kì í jagun nípa ti ẹran-ara. Ẹran-ara kò lè tún ẹran-ara ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni, o lè gbìyànjú láti ṣàkóso rẹ̀, ìyẹn sì lè ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Ṣùgbọ́n o kò lè yanjú ìṣòro ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹran-ara tí ẹ̀ṣẹ̀ ti di mọ́líkì fún. Ohun tí o gbọ́dọ̀ ṣe ni kí o kọ́kọ́ lọ sí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Òtítọ́ Rẹ̀ ni ó tú ọ sílẹ̀. Òtítọ́ Rẹ̀ ni ó fọ́ ọ́ tí ó sì mú ìyè wá. Òtítọ́ rẹ̀ ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn irọ́ tó dè ọ́ ní pápá mọ́ra nínú ìjìyà, tí ó sì mú kí o há sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn àbájáde rẹ̀.

Wíwá ọ̀nà láti tú ara rẹ sílẹ̀ kúrò nínú agbára ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìgbìyànjú tìrẹ ni a lè fi wé ìyá àgbà rẹ tí ó ń tiraka láti fọ aṣọ pẹ̀lú pátákó ìfọṣọ. Yóò gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ láti ṣe é, síbẹ̀síbẹ̀, àwọn aṣọ náà kò ní mọ́ pẹ̀lú gbogbo akitiyan náà. Aṣọ náà yóò padà ṣá, bẹ́ẹ̀ni yóò rẹ ìyá àgbà rẹ teyín-teyín, àti wípé yóò padà sú wọn. Ọlọ́run ti pèsè ojútùú sí ẹ̀ṣẹ̀ wa nípasẹ̀ ìwẹ̀nùmọ́ iṣẹ́ ìgbàlà tí Ọmọ Rẹ̀ ti ṣe. Ìrúbọ Jésù fún wa ní àfààní sí agbára Ẹ̀mí Rẹ̀ nínú wa. Ẹ̀mí yìí máa jẹ́ kí a mọ̀ òtítọ́ àti láti tẹ́wọ́ gbà á (Johannu 16:7-11). Ẹ̀mí náà ma ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí Jésù sọ nínú Jòhánù 8, tó túmọ̀ sí pé kí a “máa tẹ̀síwájú nínú Ọ̀rọ̀ mi.” Ọ̀rọ̀ náà "tẹ̀síwájú" túmọ̀ sí láti dá yàtọ̀, fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀—dúró ṣinṣin. O gbọ́dọ̀ dúró nínú òtítọ́, kìíṣe ṣíṣe àbẹ̀wò sí i nìkan.

Ibo ni àwọn ìgbìyànjú rẹ láti kojú àfẹ́sódì nípasẹ̀ ẹran-ara yọrí sí? Ọ̀nà wo lo lérò pé ó sàn ju èyí lọ?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

A U-Turn From Addiction

Níìgbàtí ìgbé ayé rẹ bá kúrò ní ìlànà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ọlọ́run, ó fẹ́rẹ̀ dájú wípé wàá ní ìrírí àwọn àtunbọ̀tán tí ó ní ìrora. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lóti tiraka pẹ̀lú ìlera wọn, wọ́n pàdánù iṣẹ́, àti àwọn ìbáṣepọ̀, wọ́n bá ara wọn nínú ìmọ̀lára pé wọ́n jìnà sí ọlọ́run nítorí àwọn ìkúndún bárakú. Yálà ìkúndùn bárakú tí ó le bíi oògùn olóró tàbí àwòrán ìwòkúwò tàbí ìkúndùn bárakú tí ó ṣẹ́ pẹ́rẹ́, bíi oúńjẹ tàbí ìdánilárayá, àwọn ìkúndùn bárakú a máa da ètò ayé wa rú. Jẹ́ kí Tony Evans ońkọ̀wé tí ó tàjù fi ọ̀nà òmìnira hàn ọ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Urban Alternative (Tony Evans) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tonyevans.org/