Ìyípadà-Pátá Kúrò Nínú Afẹ́sódìÀpẹrẹ

A U-Turn From Addiction

Ọjọ́ 1 nínú 3

Púpọ̀ nínú àwọn ọmọ Ọlọ́run ni a ti kó ní ìgbèkùn nípa ti ẹ̀mí. Wọ́n ti há sínú ìpápámọ́ra ẹ̀ṣẹ̀ tí wọn kò lè já fúnra wọn. Bóyá ọtí mímú ni, àbí kíkó ọ̀rọ̀ jọ, inú dídi, owú, wọ̀bìyà, ìkẹ́dùn ara-ẹni, àwòrán oníhòòhò, egbògi olóró, tẹ́tẹ́, ìsọkúsọ, ìkànnì ìbánidọ́ọ̀rẹ́, sísọ̀rọ̀-òdì sí ara ẹni, ìbínú tàbí ìríra—àfẹ́sódì àwọn ǹkan ìmọ̀lára tàbí kẹ́míkà ńṣe ìfàsẹ́yìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lónìí.

Ọ̀rọ̀ tí a lò nínú Bíbélì dípò ǹkan tí à ń pè ní àfẹ́sódì lóde òní ni odi-gíga. Afẹ́sódì, tàbí—odi-gíga nípa ti ẹ̀mí, jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn èrò àti ìwà búburú tó ti di bárakú tó sì ti di mọ́líkì ni ọkàn wa. A gbàgbọ́ a sì ń hùwà bí ìgbà tí ipò tí a bá ara wa kò ṣeé yí padà, bó tilẹ̀ lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹ̀ṣẹ̀ wá dí ọ̀gá tó ń dárí èrò, ìpinnu, àti ìṣe wa. 

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ kúrò nínú afẹ́sódì ni láti ṣe ìpinnu pé o fẹ́ ìtúsílẹ̀. Jésù a sábà máa bèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn bóyá wọ́n nílò ìtúsílẹ̀ (Jòhánù 5:6). Bí ẹnìkan bá wà nínú ìgbèkùn tí ó sì wù ú láti wà nínú ìgbèkùn síbẹ̀, kò sí ohunkóhun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe láti mú wọn jáde kúrò nínú àìṣedédé náà. Ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ìwà afẹ́sódì ní láti bẹ̀rẹ̀ látinú sóde. Tí o bá ṣe àkíyèsí pé o ti há sínú afẹ́sódì kan tàbí tí àwọn àpẹẹrẹ èrò búburú ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dárí ì rẹ, bí ìgbà tí ejò bá ká mọ́ ọkàn rẹ ni yóò ti rí. 

Àkókò tó láti yan ipasẹ̀ titun lọ síbi ìtúsílẹ̀. Ìtúsílẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú yíyàn láti kúrò ní ipa búburú àtẹ̀yìnwá àti láti tẹ̀síwájú ní ọ̀nà tó dára. 

Ǹjẹ́ o ṣetán ní tòótọ́ láti ṣe ódìgbà-óṣe sí afẹ́sódì rẹ àti láti gba Jésù láàyè láti tú ọ sílẹ̀?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

A U-Turn From Addiction

Níìgbàtí ìgbé ayé rẹ bá kúrò ní ìlànà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ọlọ́run, ó fẹ́rẹ̀ dájú wípé wàá ní ìrírí àwọn àtunbọ̀tán tí ó ní ìrora. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lóti tiraka pẹ̀lú ìlera wọn, wọ́n pàdánù iṣẹ́, àti àwọn ìbáṣepọ̀, wọ́n bá ara wọn nínú ìmọ̀lára pé wọ́n jìnà sí ọlọ́run nítorí àwọn ìkúndún bárakú. Yálà ìkúndùn bárakú tí ó le bíi oògùn olóró tàbí àwòrán ìwòkúwò tàbí ìkúndùn bárakú tí ó ṣẹ́ pẹ́rẹ́, bíi oúńjẹ tàbí ìdánilárayá, àwọn ìkúndùn bárakú a máa da ètò ayé wa rú. Jẹ́ kí Tony Evans ońkọ̀wé tí ó tàjù fi ọ̀nà òmìnira hàn ọ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ The Urban Alternative (Tony Evans) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://tonyevans.org/