Gbogbo Ǹkan Tí Mo NílòÀpẹrẹ

Everything I Need

Ọjọ́ 1 nínú 3

Gbogbo Ǹkan Tí Mo Nílò: Ìpín Mi


“Kí ni ìdí tí ọkàn mi á fi rẹ̀wẹ̀sì, kí ló fẹ́ fa òjìji tó bo'lẹ̀,
Kí ló fẹ́ mú ọkàn mi ṣàárẹ̀, tàbí ṣe àfẹ́rí ayé mi lọ́run;
Nígbàtí Jésù jẹ́ ẹ̀tọ́ mi, Ọ̀rẹ́ mi òtítọ́ ló jẹ́.
Níwọ̀n ìgbà tó ń ṣọ́ ẹyẹ ológoṣẹ́, mo mọ̀ wípé ojú rẹ̀ kò ní kúrò l'ára mi.
Mò ń kọrin nítorí inú mi dùn, mò ń kọrin nítorí mo ní òmìnira.
Ojú Rẹ̀ wà lára ẹyẹ ológoṣẹ́, mo sì mọ wípé ó fẹ́ràn mi.”
-Civilla D. Martin, 1905


N kò mọ̀ bí ìwọ ṣe ríi sí, àmọ́ ọ̀rọ̀ náà ti forí ṣọ́pọ́n lójú tèmi nítorí àwọn onírúurú ìpolówó oúnjẹ (tí kò ní ọ̀rá nínú) tí wọ́n ti fi sóde lẹ́nu bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Ìpín = oúnjẹ. Ìpín, tó nííṣe pẹ̀lú oúnjẹ, ń tọ́ka sí yíyọ́ ayé jẹ. Ó túmọ̀ sí sísé ara ẹni, fún àpẹẹrẹ kíkọ̀ láti jẹ abọ́ ìjẹkújẹ tó wà ní iwájú rẹ, tàbí láti dẹ́kun jíjẹ àkàrà òyìnbó tó kún fọ́fọ́ fún ṣokoléètì lẹ́yìn tí o tọwọ̀. Ìpín dàbí ìgbà tí a bá mọ̀ọ́mọ̀ mú ǹkan tó kéré sí èyí tí a fẹ́ gangan. Ó túmọ̀ sí wípé mo ní láti kó ara mi ní ìjánu, àti wípé ǹkan náà kò ní padà tẹ́ mi lọ́rùn. 

Bí mo bá sọ pé “ìpín,” ìwọ máa sọ wípé…  Ìṣàkóso!

Mi ò mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ yí ìpín ni Civilla Martin ní lọ́kàn nígbàtí ó ń kọ orin ìgbàgbọ́ aládùn tó sọ̀rọ̀ nípa tọkọtaya kan, ní àwọn tí àìsàn ń bá fíra, síbẹ̀ wọ́n ń làá kọjá pẹ̀lú ìdùnnú àti ìgbàgbọ́? (Ṣe àwárí nípa ìtàn orin yìí láti mọ ohun tó fa àkọsílẹ̀ rẹ̀!) Ó dá mi lójú wípé kìíṣe ìséaraẹni ni ó ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, bí àwọn ọ̀nà tí à ń gbà kóra wa ní ìjánu láti má jẹ ṣúgà àjẹjù bí ó ti wọ́pọ̀ lóde òní. Àwọn ìwà ìséaraẹni àti ìkóraẹni-ní-ìjánu wọ̀nyí ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹyọ láìpẹ́ yìí ni.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọrún ọdún mọ́kàndínlógún, àwọn wóróbo àti ìjẹkújẹ òde òní kò tíì wọ́pọ̀. Kò tíì sí àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń pòpọ̀ lójú ẹsẹ̀ ní ìgbà náà, àti wípé oúnjẹ tó rọrùn jù láti sè nígbà náà ní wàhálà nínú ju àwọn oúnjẹ ojú ẹsẹ̀ òde òní. Tí mo bá fojú inú wò ó, àwọn ẹbí àti ojúlùmọ̀ a máa jẹ̀gbádùn iyán tí a gún lódó ju èyí tí a fi ẹ̀rọ ìgbàlódé gún lọ. Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí, a lè ṣètò iyán ní ìṣẹ́jú-àá yá!

Ọ̀rọ̀ náà ìpín ni a tún lè túmọ̀ sí ìwọ̀n. Òṣùwọ̀n tó pé yéké kìíṣe èyí tí wọ́n tẹ́ nínú. Òṣùwọ̀n tó jẹ́ tiwa gangan… tí kìíṣe t'ẹlòmíràn. Ó jẹ́ òṣùwọ̀n ǹkan tí a nílò tó sì pé yéké. Ìtumọ̀ ìpín kan tó wọ́pọ̀ (gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀-orúkọ) ni “ǹkan tó tọ́ sí tàbí tó jẹ́ ẹ̀yà ǹkankan: fún àpẹẹrẹ ẹ̀tọ́ tí a rí gbà bí ẹ̀bùn tàbí ogún .”

Ẹ̀bùn , tàbí ogún an - jẹ́ ohun tí a kò ṣiṣẹ́ fún, bíkòṣe ọ̀wọ̀ tí a rí gbà nípasẹ̀ ìsọdọmọ nínú ẹbí Ọlọ́run. Jésù jẹ́ ìpín wa. Ogún wa sí rere. Àjogúnbá wa nínú ẹbí pẹ̀lú gbogbo àǹfààní àti oyè tó rọ̀ mọ́ jíjẹ́ ọmọ.

Orin Dáfídì 16:5 [AMP] sọ wípé, “Olúwa ni ìpín ìní mi, àti tí ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro. Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere.” Àwa ní ogún rere nítorí Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run rere. A ní ìpín, tí òṣùwọ̀n rẹ̀ pé yéké, èyí tí a ti fi fún wa láti pa wá mọ́, tó ń mú wa ró, tó ń mú wa fò lórí ìjì àti láti ja ìjàkadì nípasẹ̀ ìṣòótọ́ àti agbára Rẹ̀. Ìpín àti òṣùwọ̀n Rẹ̀ fún wa jẹ́ ẹ̀bùn tí kò l'ábùkù tí a nílò ní ayé yìí.


Àṣàrò:

  • Nígbàkúùgbà tí èrò nípa ọ̀rọ̀ náà ìpín bá wá sí ọ lọ́kàn, ǹjẹ́ o máa ń ronú nípa níní ànító àti àníṣẹ́kù, àbí àìní ló máa ń wá sí ọ lọ́kàn? Ǹjẹ́ a lè sọ wípé o yó ní àkókò yí? Kí ló fa irúfẹ́ èsì yí? (Ó mọ̀ wípé kìíṣe ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni à ń sọ lákòókò yí!)
  • Ǹjẹ́ o ti fi ìgbà kankan béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ohun tí òṣùwọ̀n ìpín rẹ jẹ́? Tí o kò bá tíì bèrè, wáyé láti bèrè lọ́wọ́ Rẹ̀. Bèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ nípa ohunkóhun tó lè fa ìdíwọ́ fún ìpín náà. Máṣe rẹ̀wẹ̀sì. Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́!
Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Everything I Need

Ọlọ́run ti lọ ṣáájú wa ó sì ń pa wá mọ́ ní ọwọ́ ẹ̀yìn. Gbogbo ìdojúkọ wa ló ti yanjú. Gbogbo àlàfo ìdojúkọ ló sì ti dí pẹ̀lú. Ìpèníjà kò lè dé bá a lójijì. Ẹ̀kọ́ Àṣàrò Bíbélì ọlọ́jọ́-mẹ́ta yìí ma gbà ẹ́ ní ìyànjú nípa òtítọ́ wípé Ọlọ́run ni Olùpèsè ohun tó tọ́, àti èyí tó yẹ, fún ìgbésí ayé rẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Holly Magnuson fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí http://www.hollymagnusonco.com