Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ṣáájú ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ìrìn-àjò afẹ́
Ìgbéyàwó máa pèsè àǹfààní tó tóbi jù láyé àti ìpèníjà tó nípọn jù:
- àǹfààní tó wà níbẹ̀ láti tẹ́ pẹpẹ ìbáṣepọ̀ tó rinlẹ̀, èyí tó ní àǹfààní tó ju bí a ti lérò
- ìpèníjà tó wà níbẹ̀ láti máa kọ ìtumọ̀ níní ìfẹ́ sí ẹlòmíràn, láti pa àìní tiwa tì àti láti ṣàwárí ohun tó ṣe pàtàkì fún ẹnìkejì wa, àti láti ṣe àtúnṣe sí ìwà wa
Ẹ fẹnu kò nípa ohun tí ó kàn
A lè ní ìwà tó yàtọ̀, ṣùgbọ́n níní ìpohùnpọ̀ nípa àwọn ǹkan tó ṣe pàtàkì yóò mú kí ìbáṣepọ̀ lọ́kọ-láyà dúró déédéé.
- ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa ìlépa, èròńgbà, àti ìrètí ẹnì kàǹkan yín
- ẹ fi ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe ìṣáájú, lẹ́yìn èyí ìgbéyàwó, lẹ́yìn èyí àwọn ọmọ (ìyẹn tí ẹ bá ní), lẹ́yìn èyí ni àwọn ènìyàn àti ǹkan tó wà ní àyíká yín
Ipele mẹ́rin tí àfojúsùn yín máa nípa lé lórí:
1. Ìbánidọ́rẹ̀
- ẹ má kàn dá wà gẹ́gẹ́bí lọ́kọ-láyà; ìgbéyàwó kàǹkan ló nílò àkójọpò olùrànlọ́wọ́
- pa ìgbéyàwó rẹ mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìbáṣepọ̀ mìíràn tó lè ṣe àkóbá fún-un
- fa àlà tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáàbò bo ara rẹ kúrò nínú ewu yíyan àlè
2. Àwọn ọmọ àti ìgbé-ayé inú ẹbí
- ẹ sọ̀rọ̀ lórí ìrètí yín nípa ọmọ bíbí
- ẹ máa pèsè àyè fúnra yín pàápàá nígbà tí ẹ bá ń tọ́ ọmọ wẹ́wẹ́ lọ́wọ́
3. Iṣẹ́
- ẹ máṣe fi iga gbága
- ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ ó ti pa iṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́jú àwọn ọmọ
4. Ìwàláàyè ẹ̀mí
- ṣíṣe àṣàrò nínú ìpìlẹ̀ àwọn ìgbàgbọ́ yín ma fà yín súnmọ́ ra síi (ẹ lè gba kíka àwọn ètò Alpha rò láti kọ́ síi nípa ìgbàgbọ́ Kristẹni àti láti lè mu ìrọ̀rùn dé bá ìjíròrò yín nípa àwọn ǹkan ti ẹ̀mí)
- ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ àti ìṣe tí ẹ ma nífẹ̀ẹ́ láti fi kọ́ àwọn ọmọ yín, ìyẹn tí ẹyin òbí bá ní ìrírí ìgbàgbọ́
Bí ẹnì kàǹkan wa ti ń wojú Ọlọ́run láti gbà àti ní ìrírí ìfẹ́ Rẹ̀, yóò wá rọrùn láti fẹ́ràn ẹnìkejì wa.
Àwọn aláfẹ́ àti àwọn òní-ìtọ́jú
Lótìtọ́ọ́ ni a ma jẹ́ àdàlu, ṣe àkíyèsí tí ọ̀kan nínú yín bá ní ìhùwàsí ‘ìgbafẹ́’ tí ẹnì kejì sì jẹ́ ‘oní-ìtọ́jú’,
Àwọn aláfẹ́
- wọ́n fẹ́ ṣe ìtọ́wò gbogbo adùn tí ayé ní. Wọ́n rí ìgbéyàwó fúnra rẹ̀ bíi afẹ́ èèyàn méjì. Àwọn aláfẹ́ ma ń mú ìyè àti ìrírí titun bá ìbáṣepọ̀.
Àwọn oní-itọju
- ìrísí wọn nípa ìgbéyàwó ni ibi tí wọ́n lè forí pamọ́ sí lẹ́yìn gbogbo afẹ́ àti ìpèníjà inú ayé. Àwọn oní-ìtọ́jú máa ń mú ètò àti ìdákẹ́-rọ́rọ́ bá ìbáṣepọ̀.
Ìgbafẹ́ àti ìtọ́jú ló ní ipa tí wọ́n ń kó nínú ìbáṣepọ̀
- tí afẹ́ bá sáfẹ́rẹ́, ó lè mú ìdádúró bá ìbáṣepọ̀
- tí afẹ́ bá sì tún pọ̀jù, ó lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì
Gẹ́gẹ́ bíi lọ́kọ-láyà, ojúṣe yín ní láti ràgàbo àǹfààní tó wà nínú afẹ́ àti ìsinmi.
Gbogbo ìgbéyàwó lo gbọ́dọ̀ fi àyè tótó sílẹ̀ fún afẹ́ àti ìtọ́jú. Nígbà tí ẹ bá lo àwọn ǹkan méjì wọ̀nyí ní ìwọ̀tún-wòsì, ìgbéyàwó yín yóò wà dàbí afẹ́ àìnípẹ̀kun.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kìí wáyé fúnra rẹ̀. Ìrètí wa ni wípé o máa ṣàwárí àwọn ìhà, ìlànà àti àṣà tí o nílò láti sọ ìgbéyàwó di èyí tó ní àlàáfíà tó sì nípọn fún gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí ni a fà yọ látinú ìwée Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó Ṣáájú Ìgbéyàwó tí a tọwọ́ọ Nicky àti Sila Lee kọ, àwọn olùkọ̀wé tó kọ Ìwé Ìgbéyàwó Náà.
More