Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ṣáájú ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ìbáraẹnisọ̀rọ
Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó nípọn jẹ́ ohun-èlò pàtàkì fún ìgbéyàwó tó ní àlàáfíà. Nígbà tí a bá gbéyàwó tán ni a máa mọ̀ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan tí a ṣèbí a mọ̀ nípa ìgbésí ayé ni kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún gbogbo ènìyàn.
Oníkálukú wa ló ní ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tirẹ̀, àwọn ǹkan tó sì ń fa èyí ni:
- ìhùwàsí wa
- irú ẹbí tí a bíwa sí
1. Ìhùwàsí wa
Ọlọ́yàyà
Ọ̀kan nínú wa lè kúdùn láti máa sọ gbogbo ọkàn rẹ̀. L'ọ́rọ̀ kan, bí ọ̀rọ̀ bá ti wá sí wa lọ́kàn ni a tií sọọ́.
Oníwà pẹ̀lẹ́
Ẹnìkejì wa lè jẹ́ ẹni tí máa ṣe àgbéyèwò tó péye sí èrò kí ó tó sọọ́ síta gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀.
Oní Ìtúpalẹ̀
Ọkàn nínú àwa méjèèjì lè nílò láti ṣe ìtúpalẹ̀ tó péye kí ó tó lè ní ìpinnu lórí ǹkankan.
Lílo Ọgbọ́n Inú
Ẹnìkejì wa lè lo ọgbọ́n inú lọ́pọ̀ ìgbà fún ìgbésẹ̀ àti ṣíṣe ìpinnu láìṣe ìtúpalẹ̀ kankan.
Tí a bá máa ní ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ó ṣe pàtàkì fún wa láti bárawa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìṣòótọ́ nípa àwọn ìyàtọ̀ tó wà nínú ìhùwàsí wa.
2. Irú ẹbí tí a bíwa sí
Oníwà tútù ni àwọn ẹbí kan, àwọn mìíràn sì jẹ́ aláriwo. Àwọn ẹbí kan a máa fa ìjọ̀ngbọ̀n, àwọn mìíràn a máa sá fún wàhálà. Àwọn ẹbí kan a máa ní sùúrù fẹ́nìkejì níbi ìtàkùrọ̀sọ, àwọn mìíràn a máa já ọ̀rọ̀ gbà mọ́ ẹnìkejì lẹ́nu.
A ní láti ṣe ìdámọ̀ àwọn ìwà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí ó jẹyọ nínú ẹbí ẹnì kàǹkan wa, pàápàá tí ẹbí ẹnìkan bá fẹ́ràn láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí ẹbí ẹnìkejì sì fẹ́ràn láti fi ìfẹ̀hónú wọn wọ́lẹ̀ tàbí fipamọ́.
Ìdíwọ́ sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tóní ìtumọ̀
1. Àìfàyè-sílẹ̀
Ṣe ìyàsọ́tọ̀ àkókò fún ìtàkùrọ̀sọ lóòrè-kóòrè.
- ṣe ètò fún àkókò yìí lóríi kàlẹ́ńdà rẹ (àkókò kò lè yara rẹ̀ sọ́tọ̀).
- pa àkókò náà mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdíwọ́, pàápàá èyí tí ẹ̀rọ alágbèéká àti àwọn ẹ̀rọ mìíràn lè fà.
Ṣe ìdámọ̀ ìgbà tí o nílò láti jọ̀wọ́ ohun gbogbo fún ìtẹ́tísí ẹnìkejì rẹ.
2. Ìkùnà láti sọ ohun tí ń gbé wa lọ́kàn
Àwọn mìíràn ní láti kọ́ bí wọ́n tí ń sọ ohun tí ń gbé wọn lọ́kàn nítorí ó ṣeé ṣe kí wọ́n mà ní èèyàn tí ó kọ́ wọn ní ǹkan yìí bí wọ́n ti ń dàgbà
- ó lè má rọrùn láti sọ àwọn ǹkan tó ń gbé ọ lọ́kàn nítorí ìfojúkéré-ara-ẹni, tàbí ìbẹ̀rù nípa bí ẹnìkejì yóò ti fèsì.
- gbìyànjú láti fi èrò ọkàn rẹ hàn sí ẹnìkejì rẹ.
- tí ẹnìkejì rẹ bá ń tiraka láti fi èrò ọkàn wọn hàn fún ọ, fi ṣe ojúṣe láti tẹ́tí sí wọn láì bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n.
Fífi èrò wa láti ìsàlẹ̀ ikùn hàn ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀.
3. Ìkùnà láti tẹ́tí sí ẹnìkejì
Ìtẹ́tísíni ṣe kókó láti kọ́ ìpìlẹ̀ òye àti ìbáṣepọ̀ nínú ìgbéyàwó.
Ìkùnà láti tẹ́tí máa ń fa ìdàrú-dàpọ̀ nínú ìbáṣepọ̀. Ní ìdàkeji, nígbà tí a bá rí ènìyàn tẹ́tí sí wa, ó ma ń mú wa rí ara wa bíi ẹni tí:
- a mọ̀ dáradára
- ó nìyí
- a gbárùkù tì
- a fẹ́ràn
Ọ̀pọ̀ nínú wa lóní àwọn ìwà tí kò bójúmu nípa ìtẹ́tísíni tí a ní láti borí, àwọn ìwà bíi:
- àìpọkànpọ̀ nígbàtí ẹnìkejì bá ń bá wa sọ̀rọ̀
- sísọ ìtàn tiwa nígbà tí ẹnìkejì bá ń ṣàlàyé ǹkan
- ṣíṣe ìfúni l'ámọ̀ràn lójú ẹsẹ̀ dípò ṣíṣe ìkẹ́dùn
- ṣíṣe ìfini lọ́kàn balẹ̀ asán tàbí sísọ fún wọn wípé kò sí ǹkan nígbà tí ẹnìkejì bá ṣe àlàyé nípa ìmọ̀lára búburú tí wọ́n ní
- Sísọ̀rọ̀ sí ẹnìkejì lẹ́nu tàbí pípa rí ọ̀rọ̀ fún wọn
Bí a ti ń tẹ́tí
Ó gba sùúrù láti kọ́ bí a ti ń tẹ́tí dáradára. Títẹ́tí dáradára túmọ̀ sí:
- gbígba ẹnìkejì láàyè láti parí ọ̀rọ̀ tí wọn fẹ́ sọ
- pípa ìrísí wa tì pẹ̀lú ìgbìyànjú láti rí ayé bí ẹnìkejì wa ti ríi
- ìgbìyànjú láti ní òye ohun tí wọ́n ń sọ bí a kò tilè fi taratara gbà á wọlé
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kìí wáyé fúnra rẹ̀. Ìrètí wa ni wípé o máa ṣàwárí àwọn ìhà, ìlànà àti àṣà tí o nílò láti sọ ìgbéyàwó di èyí tó ní àlàáfíà tó sì nípọn fún gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí ni a fà yọ látinú ìwée Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó Ṣáájú Ìgbéyàwó tí a tọwọ́ọ Nicky àti Sila Lee kọ, àwọn olùkọ̀wé tó kọ Ìwé Ìgbéyàwó Náà.
More