Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ṣáájú ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ìfaramọ́
Ṣíṣe ìfaramọ́ á máa mú kí a lè jẹ́rìí ara wa, yóò múu rọrùn láti fọkàn tán ẹnìkejì pẹ̀lú sísọ èrò ọkàn wa tó jinlẹ̀ jùlọ; ìṣòótọ́ a máa fún wa láyè láti fọwọ́sowọ́pọ̀ fún ètò ọjọ́ iwájú; yóò gbà wá láàyè láti gbìyànjú ohun titun, láti ṣe àṣìṣe, láti dáríjì, fún ìgboyà láti mẹ́nuba àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ ní láti ṣe àṣàrò lé lórí -- ìfaramọ́ ni ‘adùn ìgbéyàwó’, òhun ni ìyèe rẹ̀.
Àwọn àbájáde méjì tí ìfaramọ́:
- Ìbárẹ́
Ìfaramọ́ nínú ìgbéyàwó ló ń tán òùngbẹ fún ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́. Ìgbéyàwó nìkan kọ́ ni ọ̀nà tó wà láti kojú ìdàwà, àmọ́ òhun ni ìbàrẹ̀ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ rinlẹ̀ jù. - Ìgbé ayé nínú ẹbí
Ìfẹ́ tó ní ìfaramọ́ láàárín àwọn òbí túmọ̀ sí wípé àwọn ọmọ wọn ma ní àpẹrẹ rere fún ìbáṣepọ̀ ọlọ́jọ́-pípẹ́ tóní ìfaramọ́. Ara àwọn ọ̀nà tí àwọn òbí fi lè fẹ́ràn ọmọ ni kí lọ́kọ-láyà fẹ́ràn ara wọn. Ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lè já ìdè àwọn ìbáṣepọ̀ míràn tó ní ìkùnọ̀ nínú ẹbí.
Ṣètò àsopọ̀ orí-kò-jorí láàárín ẹ̀yin méjèèjì
Gbogbo lọ́kọ-láyà gbọ́dọ̀ ṣíṣe lórí àwọn ǹkan wọ̀nyí:
- ẹni tí yóò máa ṣe ǹkan pàtó
- ẹni tí yóò máa ṣe ìpinnu
- ẹni tí yóò dárí àwọn iṣẹ́ tó ka iwájú yín
A lè ti ní àwọn ìrírí kan látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa (tàbí ẹni tó tọ́ wa) nípa ojúṣe ọkọ àti aya nínú ìgbéyàwó, ó sì ṣeé ṣe kí ìrírí ẹnìkejì wa má bàá tiwa mu.
Ẹ ṣe ìtàkùrọ̀sọ nípa ìrètí yín fún ẹni tí yóò máa ṣe àwọn ǹkan nínú ìbáṣepọ̀ àti bí èyí ti lè yàtọ̀ sí ìrírí tìrẹ nínú ẹbí tí a bí ọ sí.
Ẹ tẹríba fún ara yín (Éfésù 5:21)
Ìlànà Májẹ̀mú Titun nípa ìtẹríba
- ó fún àwọn Kristẹni ní ọ̀nà titun kedegbe láti máa bá ara wa gbé
- nílò ìfifúnni láti apá méjèèjì
- àìka ìdarí ọkọ sí
Ìkọ́ni Kristẹni ti mú kí a rí ìgbéyàwó gẹ́gẹ́bí ìbáṣepọ̀ tó nílò ìfifúnni ní orí-kò-jorí.
‘Ìtẹríba’ kò túmọ̀ sí àìlè-sọ̀rọ̀
- ìtẹríba ni ìdàkejì jíjẹ gàba
- ó túmọ̀ sí fífi ẹnìkejì wa ṣáájú
- ipele ìfẹ́ tí yóò fi àìní ẹnìkejì ṣáájú tiwa
Ẹ jùmọ̀ ṣàwárí ojúṣe tí ó rọrùn jù fún ẹnìkààǹkan
- ẹ lo àwọn ìyàtọ̀ yín láti ran ẹnìkejì lọ́wọ́
- ní àwọn ipele ayé tí ẹ ti ní ǹkan papọ̀, gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ adarí
- ní àwọn ipele mìíràn, ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹnìkejì rẹ
Níní ìfẹ́ báyìí jẹ́ iṣẹ́ ojojúmọ́ ó sì nílò ṣíṣe ìfarajìn fún ẹnìkejì.
Ìtẹríba ẹnìkan fún èkejì ṣe pàtàkì fún ìfẹ́ nínú ìgbéyàwó.
Májẹ̀mú ìgbéyàwó náà
Májẹ̀mú tí a máa ńṣe nígbà ìgbéyàwó jẹ́ ìpinnu láti fi ara wa jìn ní kíkún sí ẹnìkejì pẹ̀lú ìfẹ́, ó sì jẹ́ ìpinnu tí a ní láti máa sọ dọ̀tun lójojúmọ́.
Májẹ̀mú ìgbéyàwó ló ń di lọ́kọ-láyà mú nígbà tí wọ́n bá ní ìpèníjà, èyí tí ọkọ àti ìyàwó kan kò lè sára fún.
Ẹ̀jẹ́ tí ẹnìkààǹkan wá bá dá ló ń ró ìgbéyàwó lágbára pẹ̀lú àǹfààní láti lè fi ọkàn wa hàn pẹ̀lú ìṣòótọ́ sí ẹnìkejì.
- àwọn ǹkan wọ̀nyí ló ma fún wa ní ìgboyà láti ṣe àfihàn ara wa fún ẹnìkejì gẹ́lẹ́ bí a ti rí (pẹ̀lú àwọn apá a ìṣẹ̀dá wa tí kò hàn sí ẹnikẹ́ni) èyí tí yóò wá mú kí ìrẹ́pọ̀ dùn
- àwọn ẹ̀jẹ́ yìí kò dá lórí ǹkan tí ẹnìkejì lè ṣe fún wa bí kò ṣe ǹkan tí a lè ṣe fún wọn
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kìí wáyé fúnra rẹ̀. Ìrètí wa ni wípé o máa ṣàwárí àwọn ìhà, ìlànà àti àṣà tí o nílò láti sọ ìgbéyàwó di èyí tó ní àlàáfíà tó sì nípọn fún gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí ni a fà yọ látinú ìwée Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó Ṣáájú Ìgbéyàwó tí a tọwọ́ọ Nicky àti Sila Lee kọ, àwọn olùkọ̀wé tó kọ Ìwé Ìgbéyàwó Náà.
More