Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ṣáájú ÌgbéyàwóÀpẹrẹ

Ìsopọ̀ṣọ̀kan
Báwo laó ti mú ìfẹ́ wa jí ìjí-ọ̀tun pẹ̀lú wíwà ní àsopọ̀ jálẹ̀ àkókò ìgbéyàwó?
Ẹ lo àkókò tó ní ìtumọ̀ pẹ̀lú ara yín
Sísọ ìfẹ́ di ọ̀tun jẹ́ ìpinnu tí a ní láti dìídì ṣe. Ó nííṣe pẹ̀lú:
- fífi ìṣúra sínú ìbárẹ́ wa nípasẹ̀ ṣíṣe àwọn ǹkan tí àwa méjèèjì gbádùn
- ṣíṣe ìsopọ̀ ti ìtàkùrọ̀sọ àti ìmọ̀lára
- ṣíṣe ètò àti ní ìjáde ọlọ́sẹ̀-ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú enìkejì wa láti mú kí ìbáṣepọ̀, inú dídùn, àti ìfẹ́ àárín wa gbèrú síi
Ṣe àwárí àwọn àìní ti ìmọ̀lára enìkejì rẹ
Ṣíṣe àwárí ǹkan tí máa mú enìkejì wa ní ìmọ̀lára ìfẹ́ tí a ní sí wọn. Gbìyànjú láti mú ìsopọ̀ṣọ̀kan àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ dé bá ìfẹ́e yín. A lè yàtọ̀ kedegbe nípa ọ̀nà tí a fi ńṣe àfihàn tàbí gba ìfẹ́.
Àwọn èdè ìfẹ́ márùn-ún
- Ọ̀rọ̀ ìfẹ́
- Ẹ̀bùn tó ní ìtumọ̀
- Ìfẹ́ ojúkojú
- Àkókò tí ẹ ní papọ̀
- Ìṣe ìkáàńú
Gbogbo ọ̀nà ìfihàn ìfẹ́ máráàrún ló ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó, àmọ́ a máa ní ọ̀kan tàbí méjì nínú àwọn èdè ìfẹ́ wọ̀nyí tí ó báwa lára mu ju èyí tó kù.
Tí o bá ti parí ètò kíkà tòní lọ sí www.5lovelanguages.com láti dáhùn àwọn ìbéèrè mélòó kan láti mọ èdè ìfẹ́ tó ṣe pàtàkì jùlọ fún ọ.
A fa ẹ̀kọ́ nípa Èdè Ìfẹ́ Márùn-ún Náà jáde látinú ìwée Dr Gary Chapman, The 5 Love LanguagesⓇ: The Secret to Love That Lasts (© 2015). Èyí tí a tọwọ́ọ ilé iṣẹ́ Northfield Publishing tẹ̀ síta. A tọrọ ìyànda kí a tó lò ó.
Bí a ti ń tẹ pẹpẹ ìbálòpọ̀ tó dára nínú ìbáṣepọ̀
Ìbálòpọ̀ ma ń sọ wá di ọ̀kan, nípa ti ẹ̀mí, ara, àti ìmọ̀lára.
Bí a ti ńṣe ìfilọ́lẹ̀ àti ìdàgbàsókè ètò ìbálòpọ̀ tó dára nínú ìgbéyàwó:
1. Ẹ fi ọkàn ṣọ̀kan
Ẹ múra láti sọ̀rọ̀
- sísọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lè má rọrùn nítorí yóò múwa sọ àwọn èrò ìdákọ́nkọ́ ọkàn wa síta
- sọ fún enìkejì ohun tí máa mú ara rẹ jí gìrì àti èyí tí maá mú ara rẹ silé nípa ìbálòpọ̀
Fi òpin sí àwọn ìbárẹ́ àtijọ́ tó ní ìbálòpọ̀ nínú
- àwọn ìbáṣepọ̀ àtijọ́ lè fa owú àti àìlè-jẹ́rìí enìkejì
- tó bá ṣeé ṣe, fòpin sí ìbárẹ́ rẹ lórí ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ọkàn rẹ ti fàsí nígbà kan rí kí o sì ṣe ìparẹ́ àwọn ímeèlì, àtẹ̀jíṣẹ́, àti fọ́nrán wọn
2. Pa ọkàn rẹ pọ̀
Ipò tí ọkàn wa wà nííṣe pẹ̀lú bí ìbálòpọ̀ yóò ti dára sí
- àwọn ǹkan tó rẹwà, tó ní ọlá, àti iyì nípa ìbálòpọ̀ ni kí ó gba ọkàn wa kan
- sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrètí àti ìbẹ̀rù rẹ tó nííṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀
Àwọn ìṣòro tó súyọ láti ibi ìfipá-bánilòpọ̀ tàbí ìrírí tó jọ mọ́ọ lè nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀.
Tí wíwo àwòrán àwọn tó wà ní ìhòòhò bá jẹ́ ìpèníjà nínú ìbáṣepọ̀ tìrẹ, ní ìtàkùrọ̀sọ tí kò mú àbùkù dání pẹ̀lú enìkejì rẹ. Gbígbé ìgbésẹ̀ láti ní ìyípadà nínú ìhùwàsí rẹ yìí yóò ní ipa tó dára fún ìbáṣepọ̀ rẹ àti wípé yóò mú kí ó ṣeé ṣe láti ní ìrírí ìbálòpọ̀ tó dára nínú ìgbéyàwó.
Ìfojú-kéré-araẹni àti àìní ìfẹ́ sí bí ara wa ti rí lè kóbá ìhà tí à ń kọ sí ìbálòpọ̀
- mú ìdáraẹnilójú enìkejì rẹ nípọn síi nípasẹ̀ sísọ fún wọn bí wọ́n tí rẹwà àti bí wọ́n ṣe ń dá ọ lọ́rùn
- ẹ máa bu ọlá fún ẹwà ara yín, bí àwọn olólùfẹ́ inú Orin Sólómọ́nì ti ṣe
3. Ẹ pèsè àgọ́ ara yín sílẹ̀
Ìyàtọ̀ gedegbe wà nínú bí ara ọkùnrin àti obìnrin ti ń jí gìrì lákòókò ìbálòpọ̀.
- tọ pinpin ǹkan tí máa mú ẹnìkejì rẹ jí gìrì nípasẹ̀ kíkà látinú ìwé àti ọ̀rọ̀ sísọ
- ẹ fi àyè tó pọ̀ sílẹ̀ fún ìmúra àti ìjígìrì lákòókò ìbálòpọ̀
Ẹ jẹ́kí ìjẹ́rìí fún ẹnìkejì wà láàárín ẹ̀yin méjèèjì.
- ìbálòpọ̀ tó dára dá lórí gbígba àwọn ẹ̀ka ìbáṣepọ̀ wa tó kù láàyè láti gbèrú
- àsopọ̀ tó nípọn ń bẹ láàárín fífi ara wa fún májẹ̀mú ìgbéyàwó àti fífi ara wa jìn sí ìbálòpọ̀ wa
- fi ìkóraẹni-ní-ìjánu ṣe ojúṣe – èyí ma wúlò nígbà tí a bá ṣe àkíyèsí wípé ọkàn wa ń fà sí ẹlòmíràn yàtọ̀ sí ẹnìkejì wa
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn ìgbéyàwó tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ kìí wáyé fúnra rẹ̀. Ìrètí wa ni wípé o máa ṣàwárí àwọn ìhà, ìlànà àti àṣà tí o nílò láti sọ ìgbéyàwó di èyí tó ní àlàáfíà tó sì nípọn fún gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ètò ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí ni a fà yọ látinú ìwée Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó Ṣáájú Ìgbéyàwó tí a tọwọ́ọ Nicky àti Sila Lee kọ, àwọn olùkọ̀wé tó kọ Ìwé Ìgbéyàwó Náà.
More