Ìgbé Ayé Tí A Yípadà: Èrèdí Rẹ̀Àpẹrẹ
Àwọn Ọ̀nà Tààrà
Gbígbé ìgbé ayé ète tí Ọlọ́run ní fún wa túmọ̀sí gbígbé ayé jíjọ̀wọ́ ara wa sílẹ̀ fún Ọlọ́run. Nígbàtí a bá jọ̀wọ́ ara sílẹ̀ fún ìfẹ́ Rẹ, kò túmọ̀ sí wípé kí á kàn jókò láì se nkànkan. Ó túmọ̀ sí wípé kí á máa wáa nígbàkúgbà bí a sé ńtẹ̀ síwájú.Bíbélì se ìlérí fún wa wípé Ọlọ́run yóò se àwọn ọ̀nà wa ní tààrà, ṣùgbọ́n kí Ọlọ́run lè sàkóso ìgbésẹ̀ waa, a ní láti máa gbé àwọn ìgbésẹ̀ náà.
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, Ọlọ́run fún mi ní ìmòye àti ìfẹ́-okàn láti bẹ̀rẹ̀ isẹ́ ìránsẹ́ tí yíò máa ran àwọn obìnrin lọ́wọ́ láti kọ́ bí wọn ó se máa fi irú ẹnití wọ́n jẹ́ nínú Krístì múlẹ̀. Nígbànáà, Mi ò ní èrò bí hun ó se dá nkàn tó tóbi báyì ṣílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé mo mọ̀ wípé kò kàn ní ṣẹlẹ̀ lójijì, ṣùgbọ́n mi ò tilẹ̀ mọ̀ bí hun ó se bẹ̀rẹ̀! A ó nílò ibi tí a ó má lòsí, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, owó, ìfẹnukò tí a buwọ́ lù, onímọ̀ràn òfin, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Kàkà kí gbogbo rẹ̀ ó ṣú mi, mo pinu láti lo àyè tí Ọlọ́run fún mi yìí àti láti gbékẹ̀le pẹ̀lú àbájáde gbogbo àfojúsùn mi. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ sí, a se ìpàdé alákọ̀kọ́. Mo mọ̀ pé kò bá má ṣẹlẹ̀ láìsí ìgbọràn láti gbé ìgbésẹ̀ kíní àti láti jọ̀wọ́ ara mi sí ìfẹ́ rẹ ní gbogbo ìgbésẹ̀ mi nínú ọ̀nà yì.
Inú Ọlọ́run má ńdùn nígbàtí a bá wá nínú ìgbèrò wa. Pẹ̀lú nígbàtí mo yà sí ọ̀nà míràn, mo ti rí tí ó yí ọ̀nà mi padà t ó sì mú mi padà sí ibi tí ó fẹ́ kí nwà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó hàn sí mi wípé Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà, àti àwọn ìgbà ti mo mọ̀ pé ó ti ọ̀nà. Mo gbàgbọ́ wípé ó ńse gbogbo rẹ nítorí ó mọ̀ pé ọkàn mí fẹ́ sìn. Tí a bá gbà á ní gbogbo àsìkò, jọ̀wọ́ ọ̀la wa, àti kí á má gbìyànjú láti se ìgèrò tó ó bu ọlá fún un, Ète rẹ̀ fún ayé wa yíò túbọ̀ hàn kedere.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwo le má mọ èbúté ìkẹyìn, bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tí o rò pé Ọlọ́run ńdarí rẹ̀ láti gbé nísìsiyì. Tí o bá ní ìmọ̀ nípa àwọn omọdé, o le gbèrò láti sìn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn omodé ní ilé ìjọsìn ibi tí ò ńlọ. Bí o bá ní ìmọ̀ láti máa sètò, bóyá o le fẹ́ràn láti má sètò gbígba asọ titun ní ilé ìkó asọ sí ní agbègbè rẹ. Bí oò bá tíì mọ ibi tí Ọlọ́run darí rẹ sí, bẹ̀rẹ̀ sí pe àwọn ènìyàn láti wá jọ́sìn ní ilé ìjọsìn rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Krístì, a pè wá láti mú àwọn ènìyàn wọ ìjọba Ọlọ́run
Ìwé Kólósè 3:23 sọ wípé, "Ohunkóhun tí ẹ̀nyin bá ńse, ẹ máa fi tọkàntọkàn se é, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, kì sí íse fún ènìà;"(BM).Ní ọ̀rọ̀ míràn, Kàn bẹ̀rẹ̀ láti má fi tálẹ́ńtì rẹ se rere kí o sì má fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún fun ìsẹ́ ìjọba Ọlọ́run. Gbígbé ìgbésẹ̀ tí kò dá o lójú fún Ọlọ́run, sàn ju kí o má se nkànkan.Má jẹ́ kí ẹ̀rù àti si ìgbésẹ̀ gbé dá ọ dúró láti sún síwájú. Olúwa jẹ́ olóòtọ́ tí yíò se ohun tí ó kọjá òye lọ nínú ọrẹ rẹ̀.
Ọlọ́run, mo dúpẹ́ tí o kà mí kún ètò ńlá rẹ̀. Mo mọ̀ wípé o ní ìran fún ayé mì, mo sì gbẹ́kẹ̀ mi lé ọ wípé ìwọ yíò darí ìgbésẹ̀ mi sí ìpinnu tó o ti sètò fún mi. Ràn mí lọ́wọ́ kí n tẹ̀ síwájú láti se ohun tí mo ti bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ ètò yí. Ràn mí lọ́wọ́ kí n rí ara mì nípasẹ̀ ìwòrán òtítọ́ rẹ̀. Fi ohun tí mo fẹ́ràn jù lọ hàn mí, ohun tí mo mọ̀ọ́ se dáradára, ohun tí mo ti jẹ́, ibi tí o darí ì mi sí, àti bí àpapọ̀ gbogbo àwọn nkàn yì yíò se yàn mí láti se isẹ́ rẹ ní àrà ọ̀tọ̀. Tẹ̀ síwájú láti máa sọ mí di ọ̀tun kí n lè gbáradì láti sìn ọ nínú ipò tó o ti dá ṣọ́tọ̀ fún mi. Gbogbo ohun tí mo fẹ́ se ní láti bu ọlá fún ọ pẹ̀lú gbogbo ayé è mi. Tọ́ mi sọ́nọ̀ kí o sì se ọ̀nà mi ní tààrà. Ní orúkọ Jésù tí ó lágbára jùlọ àti tí ó se iyebíye jùlọ, àmín.
A gbàdúrà pé kí Ọlọ́run lo ètò yí láti sisẹ́ ìránsẹ́ sí ọkàn re.
Gbé àwọn ètò míràn tí ó jẹ mọ́ gbígbé ayé àyípadà wò
Túbọ̀ kọ́ síi nípa Changed Women's Ministries
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ti fìgbà kankan wòye nípa ohun tí Olórun dá ẹ láti ṣe àbí o tí béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ ìdí tí o fi la àwọn ìrírí kán kọjá? A ṣèdá rẹ ní ònà tó yàtọ̀ fún iṣẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí ìwo nìkàn lè ṣe. Bí o kò tilẹ̀ mọ ọ̀nà tí o máa gbegbà, tàbí ìṣísẹ̀ rẹ fẹ́ mẹ́hẹ, ètò ọlọ́jọ́ márùn-ùn yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú Ọlọ́run, kí Ó ba lè darí rẹ lọ sí ibi tí Ó ti ṣètò fún ẹ.
More