Ìgbé Ayé Tí A Yípadà: Èrèdí Rẹ̀Àpẹrẹ

Living Changed: Purpose

Ọjọ́ 2 nínú 5

Àwọn Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Ǹjẹ́ o ṣe àkíyèsí bí Ásẹ̀dá ṣe tó ìgbésí aiyé rẹ pápọ? Bóyá o mọ tàbí o kò mọ̀, Ọlọ́run ṣe àwọn ètò sí ọ̀nà rẹ, o sí fún ọ ní ànfàní oríṣiríṣi ìmọ rẹ lágbára kí On lè ṣe ọnà rẹ ní réré fún ìdí pàtàkì tí ó fí mu ọ wá s'aye.

Mo jẹ ọmọ ọgbọ̀n ọdún, ọ̀dọ̀mọbìrin, mo rántí sí bí mo ṣe jẹ asíwájú fún ọpọlọpọ ọdun, o sí jẹ iyalẹnu bi o ṣe sopọ mọ ìgbé ayé mí gẹgẹbi àgbàlagbà. Fún ọdún mẹtala gbáko láti ilé ẹkọ jeleosimi, titi mo fí dé ilé ẹkọ gíga. Mo jẹ asíwájú fún ilé ìwé mí àti nínú àwọn ìwude diẹ. Gẹgẹbi àgbàlagbà, èmi kò mọ̀ ìdí tí Ọlọrun ṣe fúnmi ní àwọn ìrírí wọnyi.

Kò pẹ lẹhinna mo lọ sí ìpéjọpọ̀ kàn níbití mọ tí gbọ bí àwọn obìnrin nfi ìtara sọrọ nípa didari awọn enia sí ọdọ Kristi. Mo ro ní ọkàn mí pé " èmi náà yíò ṣe bẹẹ gẹ́gẹ́ ní ọjọ kàn". Ní igbayẹn Ọlọrun mú èròngbà mí wá sí imusẹ. Nípa ìdí èyí mo ní inú dídùn àti ìtùnú duro níwájú àwùjọ enia tí wọn sì nteti sí ohun tí èmi nsọ. Ní gbogbo awọn ọdún, Ọlọrun tí nṣe ipalẹmo iṣẹ tí O yan nípa ìṣẹ̀dá mí.

.

Gbogbo awọn ìrírí ìgbé ayé rẹ mú ọ dì alailẹgbẹ. Ṣé àkíyèsí ẹbùn àmútọ̀runwa tí Ọlọrun fí fún ọ, awọn ìrírí tí ó tí ní, àti ìmọ tí ó tí ní. Ronú ibití ó dàgbà sì, gbogbo Irinajo rẹ, ẹkọ tí ó tí kò. O seese ko tí mọ nipa oríṣiríṣi àṣà, kí ó sí ní ìbáṣepọ̀ ọpọlọpọ kaakiri agbaye, tàbí ó ni idasilẹ ohunkohun ti o lè mú isiri tàbí tí ó lè tá awọn miran jí.. Oríṣiríṣi ìrírí tí ó tí ní, nigba ayé rẹ lè majamọ̀ nkankan, tàbí lójú rẹ, ṣugbọn, apapọ rẹ jẹ ìtọ́sọ́nà sí ohùn tí ó ní ìtumọ tí ó sí le gbé ògo Ọlọrun ga

A rí eleyi nínú ìwé Esteri tí ó sọ ìtàn ọmọbinrin Júù kàn tí ó wà ní ipò àrà ọtọ láti gbà awọn èèyàn rẹ là lọwọ ipakupa to gara. Paapa gẹgẹbi iyawo ati ayaba tí ọba Pasia, kò pàtàkì araré tàbí rú ararẹ̀ ga jù awọn tí ó kú nínú ètò Ọlọrun. Ó kàn nṣe ohun tí ó dára láti gbè ní irọrun. Ṣugbọn nitori ẹnití ó jẹ, ibití ó ngbe, asiko tí o wà, ẹnití ó ni ipa pẹlu, àti ọgbọn tí Ọlọrun fún ùn, ó lòó láti gbà awọn ọmọ Israẹli là lọwọ ikú.

Kòsí ìbéèrè pé Ọlọrun tí fún ọ ní ìmọ̀, ẹbùn, ẹkọ, agbára inawo, ipò, tàbí ipá ti ó jẹ ohun àrà fún ọ. Ìbéèrè náà ní bawo ní iwọ yíò ṣe lòó? Ó ko nilati jẹ ẹnití nfi àkókò kikun ṣe iṣẹ ìwàásù lati ṣiṣẹ fún Ọlọrun. Ó lè ṣiṣẹ fún Ọlọrun ni ìdí òwò tàbí nílé, pẹlu ọpọlọpọ eniyan tàbí diẹ. Pupọ nínú wa le má jẹ́ olókìkí ní ọjọ kan, ṣugbọn gbogbo wa ni ó ní ìfarayíra àti ẹbùn alailẹgbẹ tí àwọn tí ó yiwaka lè jẹ anfaani rẹ. Béèrè lọwọ Ọlọrun láti ṣe afihan bí àwọn nkán wọnyi ṣe lè jẹ ohùn èlò fún ọ nípa ìdí tí ó fí wa laaye.

Ọlọrun, ó seun fún òhun gbogbo tí ó tí fúnmi àti fún gbogbo anfani tí ó fisi ọnà mí. Ṣe afihan bí gbogbo won ṣe ṣiṣẹ papọ lati tọ́mi sónà fún ìgbé ayé mí. Mo fẹ ló awọn nkán wọnyi tí moti là kọja fún iwulo ijoba Rẹ. Rànmí lọ́wọ́ láti fí ògo ati ọlá fún ọ. Ní orúkọ Jésù. Amin.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Living Changed: Purpose

Ǹjẹ́ o ti fìgbà kankan wòye nípa ohun tí Olórun dá ẹ láti ṣe àbí o tí béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ ìdí tí o fi la àwọn ìrírí kán kọjá? A ṣèdá rẹ ní ònà tó yàtọ̀ fún iṣẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí ìwo nìkàn lè ṣe. Bí o kò tilẹ̀ mọ ọ̀nà tí o máa gbegbà, tàbí ìṣísẹ̀ rẹ fẹ́ mẹ́hẹ, ètò ọlọ́jọ́ márùn-ùn yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú Ọlọ́run, kí Ó ba lè darí rẹ lọ sí ibi tí Ó ti ṣètò fún ẹ.

More

A fẹ dúpẹ lọwọ ile-isẹ Changed Women's Ministries fun ipese eto yii. Fun alaye siwaju sii, jọwọ lọsi: https://www.changedokc.com/