Ìgbé Ayé Tí A Yípadà: Èrèdí Rẹ̀Àpẹrẹ
Ní Ipele Ìdúró
Ọjọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ ètò yí ma ti fún ẹ ní ọ̀pọ̀ ǹkan láti gbà'rò. Kò sì ní yani lẹ́nu tí ǹkan bá fẹ́ rújú bí o ti ń gbìyànjú láti ṣe àwárí àsopọ̀ tó wà láàrin ǹkan tí o fẹ́ràn láti ṣe, ǹkan tí o mọ̀ọ́ ṣe dáradára, àti àwọn ǹkan tí ó ṣòro àmọ́ tí o ti borí rẹ̀. Kàkà kí o máa la ara rẹ̀ ní òógùn nípa àwọn ǹkan wọ̀nyí, ò bá kúkú fún ara rẹ ní ìsinmi ní àkókò ìdúró yìí. Bóyá Ó ní ǹkan kan pàtó tí Ó fẹ́ kọ́ ẹ kí a tó fi ètò ayé rẹ hàn sí ọ kedegbe.
Èmi gẹ́gẹ́bí ẹnìkan, mo ní láti kọ́ bí a ti ń rí ara ẹni nínú dígí òtítọ́ Ọlọ́run kí n tó ní ìṣípayá ètò Rẹ̀ fún ayé mi. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni èrò náà ma ń wá sí mi lọ́kàn wípé n kò ní àǹfààní kankan tí mò ńṣe tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí èrò yí fẹ́ dí mi lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé ka iwájú mi. Nígbà tí mo ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́, ó ń ṣe mí bíi wípé n kò mọ Ìwé Mímọ́ bótiyẹ àti bíi wípé n kò ní àwọn àmúyẹ tí mo nílò láti gbé ǹkan tó jọjú ṣe. Pẹ̀lú gbogbo àìní ìdánilójú, wípé ǹkan ma lọ ní ìrọ́wọ́-rọsẹ̀ yí, mo ṣe ìlérí fún Ọlọ́run wípé mo máa yàǹda ara mi láti ṣe ohunkóhun tó bá gbé ka iwájú mi. Nígbà tí mo kúrò níbi tí mo ti ń jẹ̀gbádùn ayé mi tí mo sì yàǹda ara mi láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi láti mọ̀ wípé ẹ̀bùn mi ní ìwúlò. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé kò sí ìgbà kankan tí ẹnìkan rí mi gẹ́gẹ́bí aláìlẹ́bùn tàbí ẹni tí kò pójúowó. Síbẹ̀, Mo ti ró àwọn irọ́ tó wà ní agbárí mi yìí ní agbára lórí ayé mi ju òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ.
Mósè náà ní ìrírí nípa rírí ara ẹni bíi aláìmọ̀ọ́ṣe. Nínú ìwé Ẹ́kísódù, Ọlọ́run lo Mósè láti tú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò nínú ìmúnisìn ní ilẹ̀ Íjíbítì àti láti fún wọn ní òfin àwọn Júù tí wọ́n padà tẹ̀lé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Mósè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adarí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run pèé láti wá ṣiṣẹ́ ní ipò yí, ó ṣòro fún Mósè láti gbàgbọ́ wípé òhun dáńtọ́ fún ipò náà. Pẹ̀lú gbogbo ìlérí Ọlọ́run láti wà pẹ̀lú rẹ, Mósè kọ̀ jálẹ̀, ó sì rọ Ọlọ́run láti wá ẹlòmíì gbé iṣẹ́ náà fún. T'ẹsẹ̀ dúró kí o sì gba èyí rò. Ọlọ́run ni Mósè ń bá sọ̀rọ̀ báyìí, Ọlọ́run tó ní gbogbo agbára ní ìkápá, tí ìgbà àti àkókò kò ní ipá lóríi Rẹ̀, ẹni tí Ó mọ ohun gbogbo tó wà láti mọ̀. Àwọn àmúyẹ wọ̀nyí tó láti fún Mósè ní ìgboyà. Síbẹ̀, ẹ̀ẹ̀mélòó ni a máa ń bá ara wa ní irú ipò yí?
Ní báyìí, o lè má nìí ìdánilójú nípa èrèdí ìṣẹ̀dá rẹ o sì lè má pójú òṣùwọ̀n láti ṣe ǹkan tí a pè ọ́ fún. Àmọ́ o lè gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́ tí ó sọ wípé o ní àwọn ẹ̀bùn àti àmúyẹ aláìlẹ́gbẹ́. Bóyá ìwọ kò mọ bí o tilè dá àwọn ẹ̀bùn rẹ mọ̀ nítorí wọ́n dàbí èyí tí kò jọjú ní àfiwé sí ti ẹlòmíràn tàbí bóyá o kò mọ rírì rẹ̀ nítorí o kò ṣe wàhálà kí o tó ríi gbà. Òtítọ́ tí o kò mọ̀ ni wípé, àwọn ǹkan tó rọrùn fún ẹ láti ṣe yìí ṣòro fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ẹ̀bùn rẹ ṣe pàtàkì, o sì ní ipa tó jọjú nínú ètò Ọlọ́run. Bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pàtó ǹkan tí ẹ̀bùn náà jẹ́.
Tí o kò bá mọ bí a ti ń gbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tiraka láti mọ̀ ọ́ si. Kà látinú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Bíbélì, lójojúmọ́. Mú ìdàgbàsókè bá ìṣọwọ́ gbàdúrà rẹ nípasẹ̀ bíbàa sọ̀rọ̀ àti nípa fírarabalẹ̀ láti gbọ́ látọ̀dọ̀ Rẹ̀. Fà súnmọ́ àwọn ènìyàn tó ní ìhùwàsí bíi ti Kristi. Tiraka láti ní ìbáṣepọ̀ tó múná dóko pẹ̀lú Ọlọ́run, láìpẹ́, yó sì rọrùn láti dá ohùn Rẹ̀ mọ̀ yàtọ̀ nígbàkúùgbà tí Ó bá kọ sí ẹ.
Nígbàtí o kò bá mọ ohun tí ó kàn lákòókò ìdúró, tẹ́tí sílẹ̀ láti gbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Gbọ́ ǹkan tí ó ń sọ nípaà rẹ. Bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ láti lè dá àwọn irọ́ tó fẹ́ nípa lórí rẹ mọ́. Ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí o lè fi ṣe ìgbọràn lákòókò yí, pàápàá nínú àwọn ǹkan kéékèèké, kí o ba lè wà ní ìmúrasílẹ̀ nígbàtí ó bá fi àwọn ǹkan tó ju èyí lọ hàn sí ọ. Bèrè pé kí Ó fi àwọn ǹkan tí o mọ̀ọ́ ṣe hàn sí ọ, lẹ́yìn èyí kí ìwọ náà wá múra láti jọ̀wọ́ gbogbo rẹ̀ fún-un. Ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyí bí o ti ń dúró dè é nítorí lọ́pọ̀ ìgbà, ètò Rẹ̀ fún ayé wa àti ìpinnu wa láti jọ̀wọ́ àti gbọ́ràn si kìí lọ ní ìkẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.
Ọlọ́run, o ṣeun fún ètò èrèdí kan pàtó tí o ṣe fún ayé mi. Ràn mí lọ́wọ́ láti rí ara mi bí O ti rí mi àti láti lè ṣe ìkọ̀sílẹ̀ gbogbo irọ́ tó lè fẹ́ dè mí mọ́lẹ̀. Ràn mí lọ́wọ́ láti rántí wípé tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi ní àwòrán Rẹ àti wípé kò sí ẹ̀dá mìíràn tó rí bí mo ti rí. Tẹ̀síwájú láti máa túnmiṣe àti láti máa ràn mí lọ́wọ́ fún ètò ńlá Rẹ fún ayé mi. Fi ìṣíṣẹ̀ tó kàn hàn mí láti lè fà súnmọ́ Ọ si àti láti lè ṣíṣẹ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀ fún mi nínú Ìjọ rẹ. Ní orúkọ Jésù, àmín
ìtùnúNípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ti fìgbà kankan wòye nípa ohun tí Olórun dá ẹ láti ṣe àbí o tí béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ ìdí tí o fi la àwọn ìrírí kán kọjá? A ṣèdá rẹ ní ònà tó yàtọ̀ fún iṣẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí ìwo nìkàn lè ṣe. Bí o kò tilẹ̀ mọ ọ̀nà tí o máa gbegbà, tàbí ìṣísẹ̀ rẹ fẹ́ mẹ́hẹ, ètò ọlọ́jọ́ márùn-ùn yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú Ọlọ́run, kí Ó ba lè darí rẹ lọ sí ibi tí Ó ti ṣètò fún ẹ.
More