Ìgbé Ayé Tí A Yípadà: Èrèdí Rẹ̀Àpẹrẹ
Ìpinnu àti Àfojúsùn Nínú Ìrora
Nígbàmíràn ó ṣòro láti rí bí Ọlọrun ṣe lè lò ìrora tí a tí là kọjá fún rere wa. Sibẹsibẹ, nigbakugba ní á ńri awọn àpẹẹrẹ nínú Bíbélì tí ó rinlẹ tí ó sí nira julọ nínú ìgbé ayé àwọn ènìyàn tí ó sí nlo wọn fún ògo Rẹ.
Jẹ́nẹ́sísì 37-50 sọ ìtàn Jósẹ́fù tí àwọn arákùnrin rẹ kun fún òwú jíjẹ àti ìkórira dé ibí pé wọn tà sí oko ẹrú. Bí ẹnipe ìyẹn kò tíì burú tó, aya ọgá rẹ purọ́ mọ, wọn sì jù sí ẹwọn. Gẹgẹbi ọpọlọpọ nínú wa o ní idojukọ ìmọ̀lára tí ó lé koko bí ìwà ọ̀dàlẹ̀, ikọsilẹ, tí á kò sí naani rárá - ṣugbọn Ọlọrun ńṣiṣẹ́ Rẹ lọ. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, pẹlu ipò àìníreti tí ó wà, Jósẹ́fù dì ìgbákejì ọba Farao tí ó sí ní agbára láti gbà ìdílé rẹ àti gbogbo Íjíbítì là lọwọ ìyàn àti ikú. Jósẹ́fù ronú lórí iṣẹlẹ tí o tí ṣẹlẹ sẹ́hìn, ó sí ní òye pé Ọlọrun kò fí oun silẹ rárá, ṣugbọn Ó fí pẹ̀lẹ́kùtù ńṣisẹ́ láti ìgbà náà.
Gẹgẹbi Jósẹ́fù, gbogbo wa ní ó máà ńní ìrora àti ìpòrúúrùù ọkàn. Diẹ nínú wa a máà ní àjálù tí kò ṣe fí ẹnu sọ tàbí lílo ènìyàn ní ọnà tí kò dára lai bikita. Bí ó tí wú kí ó rí, awọn ìtàn bayi a máà fúnwa ní ìrètí pé, Ọlọrun lè mú wá ṣe àwárí ìdí tí á fí ńla ìrora kọjá.
Nigba gbogbo awọn ìpalára wa á máà fúnwa ní anfààní lati ní ipa rere nínú ayé yí tí ẹlòmíràn kò lè fí ara dà. Mo tí gbọ wípé àwọn tí ó pàdánù òbí wọn nìkan ní ó mọ rírì oun tí ó njẹ àdánù. Ìpápòdà bàbá mí jẹ ìpalára fún mí títí dì òní, ṣugbọn mo rí nisisiyi pé ó rán mí lọwọ láti sọrọ sínú ayé awọn ẹlomiran àti láti tù wọn ninu ní ìpele tí ó jẹ wipe awọn diẹ ní ó lè ṣe bẹẹ. Nínú ìrírí mí, ìrora wa lè ṣe atọ̀nà wa sí ìdí tí á fí wà sí ayé.
Bóyá nítorí ó tí ṣẹlẹ sí ọ ri, ní ó mú ọ wà nípò tí o lè fí fún ẹlòmíràn ní ìrètí lórí ìgbéyàwó wọn, tàbí irú Ìpèníjà idojukọ tí ó ní nígbà èwe rẹ lè ràn ìdílé míràn lọwọ láti mọ irú àwọn àmì ìkìlọ tí ó lè pani lára. Bóyá nínú ìgbìyànjú rẹ ó lè ṣe iranlọwọ fún ẹnìkan nipasẹ ailesabiyamọ̀, ìfẹ́òdì sí ohunkóhun, tàbí ayẹwo àrùn jẹjẹrẹ. Èyíkéyì tí ìtàn rẹ lè dá lé lórí, ẹwà àti agbára asẹ̀dá wà fúnwa láti yan nipa ailagbara wa láti jẹ alábapín ẹrí rẹ pẹlu ẹlòmíràn.
Tí ó bá ngbe ní àkókò tí o le nisisiyi, o lè má lè ronú nípa ohùn tí Ọlọrun lè ṣe fún ọ ní ọjọ iwájú. O dara. Ní àkókò yí iwọ kò ní láti mọ bí Ọlọrun ṣe ní láti lò ìrora rẹ. Sáà mọ pé Òun yíò ṣee.. Jẹki ìyẹn fún ọ ní ìrètí láti mú ọ láá já.
Ọlọrun, Ẹ́ ṣeun fún ìlérí tí Ẹ́ ṣe fúnmi pé Ẹyin kò ní jẹ kí gbogbo òkè ìṣòro tí mo là kọjá jẹ lásán. Ẹ́ ṣeun fún ìlérí Yin fúnmi pé ohun gbogbo yíò ṣiṣẹ pọ fún rere mí. Jésù, mo fí ohun gbogbo tí ó ṣokunkun, ẹgbin àti àwọn ohun tí ó ní abawọn ní ìgbé ayé mí atẹhinwa fún Yin, mo si ní igbẹkẹle sí Yin pé Ẹ́yin yíò yí wọn padà sí ohun tí ó lí ẹwà. Fúnmi ní ìwòsàn kí ó sí fí hàn mí bí èmi yíò ṣe ló ìgbé ayé mí atẹhinwa fún ìdí tí Ẹ́ fí mú mí wá sí ayé. Fi ìrètí ati igbẹkẹle Yin kún mí nínú Rẹ. Ní orúkọ Jésù ní mò gbàdúrà, àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ǹjẹ́ o ti fìgbà kankan wòye nípa ohun tí Olórun dá ẹ láti ṣe àbí o tí béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ ìdí tí o fi la àwọn ìrírí kán kọjá? A ṣèdá rẹ ní ònà tó yàtọ̀ fún iṣẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí ìwo nìkàn lè ṣe. Bí o kò tilẹ̀ mọ ọ̀nà tí o máa gbegbà, tàbí ìṣísẹ̀ rẹ fẹ́ mẹ́hẹ, ètò ọlọ́jọ́ márùn-ùn yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú Ọlọ́run, kí Ó ba lè darí rẹ lọ sí ibi tí Ó ti ṣètò fún ẹ.
More