Bí A Ti Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Ní Ka BíbélìÀpẹrẹ
Ṣíṣe Àmúlò Àwọn Òtítọ́ Bíbélì fún Ayé Rẹ
Má ṣe àṣìṣe kíka Bíbélì láì tẹ̀lé ẹ̀kọ́ inú rẹ̀. — Francis Chan
Bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, kíka ìwé mímọ́ ṣe kókó fún ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ wa pẹ̀lú Kristi. Àmọ́ kíkọ́ tàbí kíkà láti ní ìmọ̀ yìí láì ṣe àmúlò rẹ̀ kò ní ṣe ìrànwọ́ fún wa lọ títí. Ìdí tí a fi gbọ́dọ̀ ṣe àmúlò ǹkan tí a kà tí a sì kọ́ kí a ba lè máa dàgbà gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́yìn Kristi.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ǹkan ìjà. Tó wà láàyè, tó wà lójú iṣẹ́, tó sì mú ju idà olójú méjì lọ. Nígbà tí a bá fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pamọ́ sínú ọkàn wa, kò ní gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ lásán àmọ́ yóò mú wa dojú ìjà kọ àwọn àgbàra búburú. A ní ọ̀tá kan, kò sì fẹ́ kí a jẹ́rìí Ọlọ́run tàbí Bíbélì. Ọ̀tá wa nípa ti ẹ̀mí ń retí kí a gbá gbogbo ǹkan tí a ti kọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan.
Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tó nípọn jù tí a lè kọ́ látinú Bíbélì ni irú ènìyàn tí a jẹ́ nínú Kristi àti bí a ti lè ṣe àmúlò àwọn òtítọ́ wọ̀nyí nínú ayé wa. Lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ ni wàá ti rí àwọn irọ́ tó wọ́pọ̀ tí gbogbo wá gbàgbọ́ àti ẹ̀rọ̀ tó ma mú wa borí wọn:
Àwọn Irọ́ tí A Gbàgbọ́ —Mi ò pójú òṣùwọ̀n, àti wípé n kò lè dá ǹkan rere ṣe.
Ṣíṣe Àmúlò Òtítọ́ Ọlọ́run — Ó lè má rọrùn, ṣùgbọ́n mo lè ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ Kristi tó ró mi lágbára (Fílípì 4:13).
Àwọn Irọ́ tí A Gbàgbọ́ — Irú Ọlọ́run wo ló máa gba èyí láàyè láti ṣẹlẹ̀ sí mi?
Ṣíṣe Àmúlò Òtítọ́ Ọlọ́run — Mo mọ̀ wípé Ọlọ́run ma mú ohun GBOGBO ṣiṣẹ́ sí rere fún àwọn tó fẹ́ràn Rẹ̀, tí a ti pè gẹ́gẹ́bí ètò Rẹ̀. (Róòmù 8:28)
Àwọn Irọ́ Tí A Gbàgbọ́ — Báyìí ni ayé mi yóò máa rí lọ.
Ṣíṣe Àmúlò Òtítọ́ Ọlọ́run — Mo lò yípadà nítorí mo wà nínú Kristi. Ìgbésí ayé àtijọ́ ti ré kọjá lọ, mo ti di ẹ̀dá titun! (Kọ́ríńtì Kejì 5:17)
Ronú nípa àwọn ìrọ́ tí o gbàgbọ́ sẹ́yìn wá. Wọ́rọ́wọ́ ni, àti wípé lótìítọ́ ó rọrùn láti gba àwọn irúfẹ́ irọ́ yìí láyè nítorí wọ́n ti di bárakú. Ṣùgbọ́n, èyí kìíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa. Lọ́gán tí o bá ti dá àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀, o ti wà ní bèbè ìṣẹ́gun. Ó fún wa ní Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí wa kí a ba lè mọ òtítọ́, nítorí wípé òtítọ́ Rẹ̀ ni yóò tú wa sílẹ̀.
Ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ tọ́ ìṣísẹ̀ wa sí ipa ìṣẹ́gun kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lo agbára tí ń fúnni ní ìyè, ìrètí, àti èyí tí ń gbá èṣù jáde bí a ti pèsè rẹ̀ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Gba èyí rò
- Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ma ńṣe àmúlò ǹkan tí ò ń kà nínú Bíbélì? Àbí o máa ń gba ẹran ara láàyè láti dí o lọ́wọ́ láti ṣe àmúlò rẹ̀?
- Kíni ìpèníjà tí ó burú jù tí ò ń kojú ní àkókò yí? Wá àkókò láti ṣe àwárí àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àmúlò òtítọ́ Ọlọ́run kí o lè máa rìn nínú ìsẹ́gun.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Lòótọ́, a mọ̀ pé kíka Bíbélì dára, ṣùgbọ́n ó le ṣòro láti mọ ibi tí a ti le bẹ̀rẹ̀. Ní ọjọ́ mẹrin tó ń bọ̀, a ó máa kọ nípa ìdí tí Bíbélì fi ṣe pàtàkì, bí a ṣe le bẹ̀rẹ̀ ìwà ìwé-kíka ojoojúmọ́, àti bí a ṣe lè lò ní ayé wa ti òní.
More