Bí A Ti Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Ní Ka BíbélìÀpẹrẹ

How to Start Reading the Bible

Ọjọ́ 1 nínú 4

Ǹkan tí Bíbélì Jẹ́ àti Ìdí Tí Ó Fi Ṣe Pàtàkì 

Bíbélì tí a ti kà láìmoye ìgbà jẹ́ àmì ọkàn tí a bọ́ dáradára. — Ẹni Ọlọ́run Mọ̀

Bíbélì Náà, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń pè ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí Ìwé Mímọ́ , ó jẹ́ ìwé tí ń tọ́ ipasẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi ó sì jẹ́ ohun àmúlò pàtàkì láti ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́ńrán pẹ̀lú Jésù. Ó lè má dáhùn gbogbo ìbéèrè wa, àmọ́ ó ńṣe atọ́nà fún wa nípa irú ẹ̀dá tí Ọlọ́run íṣe, bí a ti ń ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn, bí a ti lè gbé ìgbé-ayé tó ní ìtumọ̀, àti bí a ṣe lè jogún ìjọba Ọlọ́run.

Ọ̀kan lára àwọn ǹkan tí ó le fún wa láti gbọ́ ni wípé kí a túbọ̀ máa kàá síi . Àmọ́ a lè kọ́ onírúurú òtítọ́ tó nípọn nípa Bíbélì, èyí yóò wá mú ìwúrí wá láti sọ ọ́ di ojúṣe ojojúmọ́. 

Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa ǹkan tó jẹ́.

A ṣe àkójọ pọ̀ Bíbélì pẹ̀lú...

  • ìwé mẹ́rin-dín-ní-aadorin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀…
  • ...tí a ṣe àkọsílẹ̀ wọn láàárín ọdún ẹgbẹ̀rún-kan-léní-ẹ̀dẹ́ẹ́gbẹẹ̀ta…
  • ...ní èdè mẹ́ta… 
  • ...látọwọ́ ọ̀mọ̀wé ogójì-ólé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀…
  • ...tí ń gbé ní kọntinẹnti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀…
  • … tí wọ́n sì gba ìmísí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Lótìítọ́ la kọ àwọn ìwé wọ̀nyí ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àkòrí kan ni gbogbo wọn dá lórí jálẹ̀ Májẹ̀mú Titun àti Láéláé: ìràpadà gbogbo ènìyàn nípasẹ̀ Olùgbàlà wa, Jésù Kristi.

Àsọtẹ́lẹ̀ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ló ti sọ ṣáájú nípa ìgbésí-ayé àti iṣẹ́ Jésù àti wípé gbogbo rẹ̀ ló wá sí ìmúṣẹ lóríi rẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ìyàtọ̀ tó jẹyọ nípa ọ̀nà àti àkókò tí a gbà kọ Bíbélì, kò sí ọ̀nà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi lè jẹ́ àròkọ àwọn tó kọ wọ́n bẹ́ẹ̀ni kò ṣe sí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fikùn-lukùn nípa rẹ̀.

Àwọn òtítọ́ wọ̀nyí jẹ́ èyí tí ó yani lẹ́nu! Ṣíṣe àṣàrò àti kíkọ́ nípa Bíbélì yóò jẹ́ ìlépa tí yóò gba ayé wa kan, nítorí a jẹ́ ẹ̀dá tó ní ìdiwọ̀n tó ń gbìyànjú láti ní òye nípa Ọlọ́run àìlópin. Àmọ́ ṣá, a lè gbìyànjú láti gbèrú síi nínú òye wa pẹ̀lú ìtẹ̀síwájú láti máa kọ́si jálẹ̀ ayé wa. 

A lè máa rò ó wípé ọ̀nà ni àìka Bíbélì yóò fi kó ìjàmbá bá ayé mi gan ná? A lè rò wípé kò sí ìyàtọ̀ tó tayọ kankan nígbà tí a bá kùnà láti ka Bíbélì ní ọjọ́ kan. A lè má ṣe àkíyèsí ìyàtọ̀ kan gbòógì lẹ́yìn ìkùnà ọjọ́ kan. Bí ìgbà tí a bá ń lo ògùn láti gbọ́ àìsàn kan ni—ó lè má ṣe wá bíi wípé ògùn náà ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n bí a bá dáwọ́ rẹ̀ dúró, a máa ṣe àkíyèsí ìyàtọ̀ tó l'ápẹ̀ẹ́rẹ . Ó lè má jọ wípé Bíbélì ní ipa lórí ayé wa, àmọ́ tí a bá yọọ́ kúrò nínú ìrìn wa ọlọ́lọọjọ́ pẹ̀lú Jésù, ó ma yọ sílẹ̀ nípa ìpòǹgbẹ ọkàn tí yóò bá wa. 

Bí a ti ń tẹ̀síwájú nínú ètò Bíbélì yí, a ó ṣàwárí bí a ti lè máa kọ́ láti ṣe àṣàrò, láti kọ́ bí a ti ń ṣe àmúlò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ayé wa, àti láti jẹ́rìí trust Ọlọ́run síwájú síi. 

Ṣe Àṣàrò

  • Ǹjẹ́ o tilẹ̀ gbàgbọ́ nínú òtítọ́ àti pàtàkì ìwúlò Bíbélì? Kini ìdí fún èsì tí o fi yìí?
  • Tí èyí bá jẹ́ abala tí ó wù ọ́ láti kọ́ si nípa rẹ̀, onírúurú àlùmọ́ọ́nì ló wà lóríi ayélujára látọwọ́ àwọn ènìyàn tó ti fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ nípa òtítọ́ inú Bíbélì.
Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

How to Start Reading the Bible

Lòótọ́, a mọ̀ pé kíka Bíbélì dára, ṣùgbọ́n ó le ṣòro láti mọ ibi tí a ti le bẹ̀rẹ̀. Ní ọjọ́ mẹrin tó ń bọ̀, a ó máa kọ nípa ìdí tí Bíbélì fi ṣe pàtàkì, bí a ṣe le bẹ̀rẹ̀ ìwà ìwé-kíka ojoojúmọ́, àti bí a ṣe lè lò ní ayé wa ti òní.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ