Bí A Ti Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Ní Ka BíbélìÀpẹrẹ

How to Start Reading the Bible

Ọjọ́ 2 nínú 4

Bí A Ti Ń Bẹ̀rẹ̀ Kíkà Olójojúmọ́

Máṣe pa ọjọ́ méjì jẹ léraléra. Bí o bá kùnà lẹ́ẹ̀kan, gbìyànjú láti padà sójú àmì ní kíákíá. — James Clear

Kíka Bíbélì lè má rọrùn tí o bá ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Tàbí bóyá o ma ń ṣíi lórè-kóòrè, ṣùgbọ́n lákòótán, kìíṣe ǹkan tí ìwọ ń kà lójojúmọ́. Lónìí, a lè ṣe àtúnṣe sí èyí nípasẹ̀ àwọn ìgbésí mélòó kan. 

Bíbẹ̀rẹ̀ Bíbélì kíkà olójojúmọ́ kò ní láti tẹ̀lé ìlànà kan pàtó. Ọ̀nà tó bá wù kí o gbé gbà, Ọlọ́run yóò fi àwọn ǹkan tó lágbára hàn sí wa nígbà tí a bá ṣe èyí. Bí ọ̀rọ̀ tí a sọ ṣáájú ti fi hàn: Máse kùnà nígbà méjì. Kìíṣe nítorí Ọlọ́run ma bínú sí wa — Kò rí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ọjọ́ tí a pajẹ bá ṣe pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ní pípa Bíbélì tì yóò ti rọrùn. Wo ìsàlẹ̀ fún àwọn ìmọ̀ràn tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ka Bíbélì lójojúmọ́.

Ka Májẹ̀mú Titun.
Ọ̀nà tó dára láti bẹ̀rẹ̀ ni èyí nítorí Májẹ̀mú Titun ṣe àkọsílẹ̀ ìgbésí-ayé àti àwọn ẹ̀kọ́ Jésù. O lè fi Májẹ̀mú Láéláé kun tó bá yá, àmọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àti àwọn tí kò lóye Bíbélì, ibí gaan lo ma ti bẹ̀rẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ látorí Matteu kí o sì ka orí kan lọ́jọ́ kan. Ṣe àkọsílẹ̀ ìmísí tàbí ìbéèrè tí o bá ní bí o ti ń kà á kí o sì fi lọ Olùṣọ́àgùntàn tàbí ọ̀rẹ́ tó bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ jù ẹ́ lọ nínú ìmọ̀ Bíbélì.

Bẹ̀rẹ̀ Ètò Bíbélì Kan. 
Ní YouVersion, a ní àìmọye ẹgbẹ̀rún Ètò Bíbélì—bí eléyìí tí ò ń kà lọ́wọ́—láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ìrìn-àjò rẹ.  Àìmọye èèyàn ló wà tí wọ́n ní ìṣúra ìmọ̀ nípa Bíbélì, ìtàn bí a ti kóojọ, àwọn ibi tó ti ṣẹ̀wá, àwọn ǹkan wọ̀nyí yóò sì fi òye rẹ̀ yé wa. O lè bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésẹ̀ nípasẹ̀ ṣíṣe àwárí Ètò olójojúmọ́ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ka Bíbélì já.

Gbàdúrà fún ìtọ́ni.
Kíka Bíbélì lójojúmọ́ jẹ́ ìṣísẹ̀ àkọ́kọ́. Ìṣísẹ̀ ńlá ló sì jẹ́! Bí o ti ń tẹ̀síwájú nínú kíka àti kíkọ́ síi nípa àwọn oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ inú rẹ̀. Bèrè pé kí Ọlọ́run sọ òtítọ́ Rẹ̀ di ìyè lọ́kàn rẹ kí o ba lè máa dàgbà ní tòótọ́ nínú ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. 

Àwọn ọjọ́ kan ma wà tí kòní ṣe wá bíi wípé kí a ka Bíbélì. Onírúurú ǹkan mìíràn ló ń fa ọkàn wa. Àwọn ọjọ́ mìíràn yóò sì wà tí a máa Kàá àmọ́ tí kókó ǹkan tí a kà kò ní yé wa. Ibi tí a ti ma nílò ìpinnu láti ka Bíbélì nìyí pẹ̀lú gbogbo ìdíwọ́ tó lè fẹ́ yọjú. Ṣàṣà ni ìgbà tí ìmọ̀lára ma darí ìwà wa, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìmọ̀lára ma ń wá lẹ́yìn tí a bá ṣe ǹkan. 

Bí o ti ń tẹ̀síwájú nínú ìṣísẹ̀ kíka Bíbélì lójojúmọ́ yìí, Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní fi àwọn ǹkan tó kọjá ọgbọ́n rẹ hàn sí ọ. Ìwọ ṣáà jẹ́rìí wípé ìfarajìn ọlọ́jọ́ pípẹ́ yìí yóò mú èrè bá ayé rẹ nípa ti ẹ̀mí. 

Gba èyí rò

  • Ṣé ojojúmọ́ nì ìwọ ń ka Bíbélì? Kíni ìdí fún èyí?
  • Gbìyànjú láti ṣe ìpinnu láti ka Bíbélì rẹ láàárín ọgbọ́n ọjọ́ láti ìsinsìnyí. Ìbá tún dára tí o bá lè wá ẹnìkan kúnra láti lè máa jábọ̀ fún ẹnì kejì rẹ. (Kódà o lè bẹ̀rẹ̀ Ètò Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ọ̀rẹ́ nípa fífi ìwé ránṣẹ́ sí wọn láti darapọ̀ mọ́ ọ!)
Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

How to Start Reading the Bible

Lòótọ́, a mọ̀ pé kíka Bíbélì dára, ṣùgbọ́n ó le ṣòro láti mọ ibi tí a ti le bẹ̀rẹ̀. Ní ọjọ́ mẹrin tó ń bọ̀, a ó máa kọ nípa ìdí tí Bíbélì fi ṣe pàtàkì, bí a ṣe le bẹ̀rẹ̀ ìwà ìwé-kíka ojoojúmọ́, àti bí a ṣe lè lò ní ayé wa ti òní.

More

YouVersion ló ṣe ìṣẹ̀dá àti ìpèsè ojúlówó ètò Bíbélì yí.

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ